Surah An-Nas - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ
Sọ pé: "Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn
Surah An-Nas, Verse 1
مَلِكِ ٱلنَّاسِ
Ọba àwọn ènìyàn
Surah An-Nas, Verse 2
إِلَٰهِ ٱلنَّاسِ
Ọlọ́hun àwọn ènìyàn
Surah An-Nas, Verse 3
مِن شَرِّ ٱلۡوَسۡوَاسِ ٱلۡخَنَّاسِ
níbi aburú (Èṣù) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni t’ó bá dárúkọ Allāh)
Surah An-Nas, Verse 4
ٱلَّذِي يُوَسۡوِسُ فِي صُدُورِ ٱلنَّاسِ
(Èṣù ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn
Surah An-Nas, Verse 5
مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ
(Èṣù náà) wà nínú àlùjànnú àti ènìyàn
Surah An-Nas, Verse 6