Surah Al-Zalzala - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
إِذَا زُلۡزِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ زِلۡزَالَهَا
Nigba ti won ba mi ile titi ni imititi re
Surah Al-Zalzala, Verse 1
وَأَخۡرَجَتِ ٱلۡأَرۡضُ أَثۡقَالَهَا
ati (nigba) ti ile ba tu awon eru t’o wuwo ninu re jade
Surah Al-Zalzala, Verse 2
وَقَالَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا لَهَا
eniyan yo si wi pe: "Ki l’o mu un
Surah Al-Zalzala, Verse 3
يَوۡمَئِذٖ تُحَدِّثُ أَخۡبَارَهَا
Ni ojo yen ni (ile) yoo soro nipa awon iro re (ti eda gbe ori ile se)
Surah Al-Zalzala, Verse 4
بِأَنَّ رَبَّكَ أَوۡحَىٰ لَهَا
Nitori pe dajudaju Oluwa re l’O fun un ni ase (lati soro)
Surah Al-Zalzala, Verse 5
يَوۡمَئِذٖ يَصۡدُرُ ٱلنَّاسُ أَشۡتَاتٗا لِّيُرَوۡاْ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Ni ojo yen, awon eniyan yoo maa gba ona otooto lo nitori ki won le fi awon ise won han won
Surah Al-Zalzala, Verse 6
فَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٍ خَيۡرٗا يَرَهُۥ
Nitori naa, eni ti o ba se ise rere ni odiwon omo ina-igun, o maa ri i
Surah Al-Zalzala, Verse 7
وَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖ شَرّٗا يَرَهُۥ
Eni ti o ba si se ise aburu ni odiwon omo ina-igun, o maa ri i
Surah Al-Zalzala, Verse 8