Surah Al-Fatiha - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Fatiha, Verse 1
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
Surah Al-Fatiha, Verse 2
ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Fatiha, Verse 3
مَٰلِكِ يَوۡمِ ٱلدِّينِ
Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san
Surah Al-Fatiha, Verse 4
إِيَّاكَ نَعۡبُدُ وَإِيَّاكَ نَسۡتَعِينُ
Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí
Surah Al-Fatiha, Verse 5
ٱهۡدِنَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
Jíjọ́sìn fún Allāhu níkan ṣoṣo àti dídúró ṣinṣin nínú ìjọ́sìn Rẹ̀ ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Āli ‘Imrọ̄n “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ sínú ’Islām ọ̀nà tààrà.” Nítorí náà
Surah Al-Fatiha, Verse 6
صِرَٰطَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِمۡ غَيۡرِ ٱلۡمَغۡضُوبِ عَلَيۡهِمۡ وَلَا ٱلضَّآلِّينَ
ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasara)
Surah Al-Fatiha, Verse 7