Surah Yunus Verse 15 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Yunusوَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَاتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا ٱئۡتِ بِقُرۡءَانٍ غَيۡرِ هَٰذَآ أَوۡ بَدِّلۡهُۚ قُلۡ مَا يَكُونُ لِيٓ أَنۡ أُبَدِّلَهُۥ مِن تِلۡقَآيِٕ نَفۡسِيٓۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّۖ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa, t’o yanju fun won, awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) yoo maa wi pe: “Mu Ƙur’an kan wa yato si eyi tabi ki o yi i pada.” So pe: “Ko letoo fun mi lati yi i pada lati odo ara mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Dajudaju emi n paya iya Ojo nla ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.”