Surah Yunus Verse 18 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Yunusوَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡ وَيَقُولُونَ هَـٰٓؤُلَآءِ شُفَعَـٰٓؤُنَا عِندَ ٱللَّهِۚ قُلۡ أَتُنَبِّـُٔونَ ٱللَّهَ بِمَا لَا يَعۡلَمُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I