Surah Yunus Verse 61 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Yunusوَمَا تَكُونُ فِي شَأۡنٖ وَمَا تَتۡلُواْ مِنۡهُ مِن قُرۡءَانٖ وَلَا تَعۡمَلُونَ مِنۡ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيۡكُمۡ شُهُودًا إِذۡ تُفِيضُونَ فِيهِۚ وَمَا يَعۡزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثۡقَالِ ذَرَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَآ أَصۡغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرَ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٍ
Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; tí ó mọ ní òdiwọ̀n iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, kí ó tún kéré jú ìyẹn lọ tàbí kí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú