Surah Yunus Verse 71 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Yunus۞وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ نُوحٍ إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِن كَانَ كَبُرَ عَلَيۡكُم مَّقَامِي وَتَذۡكِيرِي بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَعَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡتُ فَأَجۡمِعُوٓاْ أَمۡرَكُمۡ وَشُرَكَآءَكُمۡ ثُمَّ لَا يَكُنۡ أَمۡرُكُمۡ عَلَيۡكُمۡ غُمَّةٗ ثُمَّ ٱقۡضُوٓاْ إِلَيَّ وَلَا تُنظِرُونِ
Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fun yín bá lágbara lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́