UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Hud - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


الٓرۚ كِتَٰبٌ أُحۡكِمَتۡ ءَايَٰتُهُۥ ثُمَّ فُصِّلَتۡ مِن لَّدُنۡ حَكِيمٍ خَبِيرٍ

’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán
Surah Hud, Verse 1


أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۚ إِنَّنِي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ وَبَشِيرٞ

(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú emi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀
Surah Hud, Verse 2


وَأَنِ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِ يُمَتِّعۡكُم مَّتَٰعًا حَسَنًا إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى وَيُؤۡتِ كُلَّ ذِي فَضۡلٖ فَضۡلَهُۥۖ وَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٖ كَبِيرٍ

(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé kí ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó máa fun yín ní ìgbádùn dáadáa títí di gbèdéke àkókò kan. Ó máa fún oníṣẹ́-àṣegbọrẹ ní ẹ̀san iṣẹ́ àṣegbọrẹ rẹ̀. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá fun yín
Surah Hud, Verse 3


إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ

Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí yín. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Hud, Verse 4


أَلَآ إِنَّهُمۡ يَثۡنُونَ صُدُورَهُمۡ لِيَسۡتَخۡفُواْ مِنۡهُۚ أَلَا حِينَ يَسۡتَغۡشُونَ ثِيَابَهُمۡ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Gbọ́, dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bo ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà wọn láti lè fara pamọ́ fún Allāhu. Kíyè sí i, nígbà tí wọ́n ń yíṣọ wọn bora, Allāhu mọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi pamọ́ àti n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá
Surah Hud, Verse 5


۞وَمَا مِن دَآبَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِ رِزۡقُهَا وَيَعۡلَمُ مُسۡتَقَرَّهَا وَمُسۡتَوۡدَعَهَاۚ كُلّٞ فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ

Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan t’ó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú
Surah Hud, Verse 6


وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ وَكَانَ عَرۡشُهُۥ عَلَى ٱلۡمَآءِ لِيَبۡلُوَكُمۡ أَيُّكُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗاۗ وَلَئِن قُلۡتَ إِنَّكُم مَّبۡعُوثُونَ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡمَوۡتِ لَيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) – nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín l’ó dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
Surah Hud, Verse 7


وَلَئِنۡ أَخَّرۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِلَىٰٓ أُمَّةٖ مَّعۡدُودَةٖ لَّيَقُولُنَّ مَا يَحۡبِسُهُۥٓۗ أَلَا يَوۡمَ يَأۡتِيهِمۡ لَيۡسَ مَصۡرُوفًا عَنۡهُمۡ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ

Dájúdájú tí A bá sún ìyà ṣíwájú fún wọn di ìgbà t’ó ní òǹkà, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Kí l’ó ń dá a dúró ná?” Gbọ́, ní ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, kò níí ṣe é gbé kúrò fún wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po
Surah Hud, Verse 8


وَلَئِنۡ أَذَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِنَّا رَحۡمَةٗ ثُمَّ نَزَعۡنَٰهَا مِنۡهُ إِنَّهُۥ لَيَـُٔوسٞ كَفُورٞ

Àti pé dájúdájú tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò láti ọ̀dọ̀ Wa, lẹ́yìn náà, tí A bá gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, dájúdájú ó máa di olùsọ̀rètínù, aláìmoore
Surah Hud, Verse 9


وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ نَعۡمَآءَ بَعۡدَ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ ٱلسَّيِّـَٔاتُ عَنِّيٓۚ إِنَّهُۥ لَفَرِحٞ فَخُورٌ

Dájúdájú tí A bá sì fún un ní ìdẹ̀ra tọ́wò lẹ́yìn ìnira t’ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Àwọn aburú ti kúrò lọ́dọ̀ mi.” Dájúdájú ó máa di aláyọ̀pọ̀rọ́, onífáàrí
Surah Hud, Verse 10


إِلَّا ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٞ كَبِيرٞ

Àyàfi àwọn t’ó bá ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn, ti wọn ni àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi
Surah Hud, Verse 11


فَلَعَلَّكَ تَارِكُۢ بَعۡضَ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ وَضَآئِقُۢ بِهِۦ صَدۡرُكَ أَن يَقُولُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ كَنزٌ أَوۡ جَآءَ مَعَهُۥ مَلَكٌۚ إِنَّمَآ أَنتَ نَذِيرٞۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٌ

Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?” Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Hud, Verse 12


أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ فَأۡتُواْ بِعَشۡرِ سُوَرٖ مِّثۡلِهِۦ مُفۡتَرَيَٰتٖ وَٱدۡعُواْ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Surah Hud, Verse 13


فَإِلَّمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَكُمۡ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَآ أُنزِلَ بِعِلۡمِ ٱللَّهِ وَأَن لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَهَلۡ أَنتُم مُّسۡلِمُونَ

Nígbà náà tí wọn kò bá da yín lóhùn, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Allāhu. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin yóò di mùsùlùmí
Surah Hud, Verse 14


مَن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيۡهِمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ فِيهَا وَهُمۡ فِيهَا لَا يُبۡخَسُونَ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé
Surah Hud, Verse 15


أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَيۡسَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِلَّا ٱلنَّارُۖ وَحَبِطَ مَا صَنَعُواْ فِيهَا وَبَٰطِلٞ مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Hud, Verse 16


أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّهِۦ وَيَتۡلُوهُ شَاهِدٞ مِّنۡهُ وَمِن قَبۡلِهِۦ كِتَٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامٗا وَرَحۡمَةًۚ أُوْلَـٰٓئِكَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۚ وَمَن يَكۡفُرۡ بِهِۦ مِنَ ٱلۡأَحۡزَابِ فَٱلنَّارُ مَوۡعِدُهُۥۚ فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُۚ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ

Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì s.a.w.), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur’ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasara, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur’ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́
Surah Hud, Verse 17


وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ يُعۡرَضُونَ عَلَىٰ رَبِّهِمۡ وَيَقُولُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ هَـٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ عَلَىٰ رَبِّهِمۡۚ أَلَا لَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلظَّـٰلِمِينَ

Àti pé ta ni ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu? Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n yóò kó wá síwájú Olúwa wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí (ìyẹn, àwọn mọlāika) yó sì máa sọ pé: "Àwọn wọ̀nyí ni àwọn t’ó parọ́ mọ́ Olúwa wọn." Gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí
Surah Hud, Verse 18


ٱلَّذِينَ يَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَيَبۡغُونَهَا عِوَجٗا وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ

àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn
Surah Hud, Verse 19


أُوْلَـٰٓئِكَ لَمۡ يَكُونُواْ مُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كَانَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِنۡ أَوۡلِيَآءَۘ يُضَٰعَفُ لَهُمُ ٱلۡعَذَابُۚ مَا كَانُواْ يَسۡتَطِيعُونَ ٱلسَّمۡعَ وَمَا كَانُواْ يُبۡصِرُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn kò lè mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀ àti pé kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. A ó sì ṣe àdìpèlé ìyà fún wọn. Wọn kò lè gbọ́. Àti pé wọn kì í ríran (rí òdodo)
Surah Hud, Verse 20


أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́
Surah Hud, Verse 21


لَا جَرَمَ أَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡأَخۡسَرُونَ

Ní ti òdodo, dájúdájú àwọn gan-an ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn
Surah Hud, Verse 22


إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَأَخۡبَتُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ

Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sì dúnní mọ́ ìronúpìwàdà sọ́dọ̀ Olúwa wọn, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀
Surah Hud, Verse 23


۞مَثَلُ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ كَٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡأَصَمِّ وَٱلۡبَصِيرِ وَٱلسَّمِيعِۚ هَلۡ يَسۡتَوِيَانِ مَثَلًاۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Àfiwé ìjọ méjèèjì dà bí afọ́jú àti adití pẹ̀lú olùríran àti olùgbọ́rọ̀. Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì dọ́gba ní àfiwé bí? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni
Surah Hud, Verse 24


وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦٓ إِنِّي لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٌ

A sì kúkú ti rán (Ànábì) Nūh sí ìjọ rẹ̀ (láti sọ pé) dájúdájú olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni mo jẹ́ fun yín
Surah Hud, Verse 25


أَن لَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۖ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ أَلِيمٖ

(Mò ń kìlọ̀) pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ẹlẹ́ta-eléro fun yín
Surah Hud, Verse 26


فَقَالَ ٱلۡمَلَأُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَوۡمِهِۦ مَا نَرَىٰكَ إِلَّا بَشَرٗا مِّثۡلَنَا وَمَا نَرَىٰكَ ٱتَّبَعَكَ إِلَّا ٱلَّذِينَ هُمۡ أَرَاذِلُنَا بَادِيَ ٱلرَّأۡيِ وَمَا نَرَىٰ لَكُمۡ عَلَيۡنَا مِن فَضۡلِۭ بَلۡ نَظُنُّكُمۡ كَٰذِبِينَ

Àwọn aṣíwájú t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ sì wí pé: "Àwa kò mọ̀ ọ́ sí ẹnì kan tayọ abara bí irú wa. Àwa kò sì mọ àwọn t’ó tẹ̀lé ọ sí ẹnì kan kan tayọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ nínú wa, ọlọ́pọlọ bín-íntín. Àti pé àwa kò ri yín sí ẹni t’ó fi ọ̀nà kan kan ní àjùlọ lórí wa, ṣùgbọ́n a kà yín kún òpùrọ́
Surah Hud, Verse 27


قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَءَاتَىٰنِي رَحۡمَةٗ مِّنۡ عِندِهِۦ فَعُمِّيَتۡ عَلَيۡكُمۡ أَنُلۡزِمُكُمُوهَا وَأَنتُمۡ لَهَا كَٰرِهُونَ

(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí mo bá wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí Ó sì fún mi ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọn kò sí jẹ́ kí ẹ ríran rí (òdodo náà), ǹjẹ́ a óò fi dandan mu yín bí, nígbà tí ẹ̀mí yín kọ̀ ọ́
Surah Hud, Verse 28


وَيَٰقَوۡمِ لَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مَالًاۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۚ وَمَآ أَنَا۠ بِطَارِدِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْۚ إِنَّهُم مُّلَٰقُواْ رَبِّهِمۡ وَلَٰكِنِّيٓ أَرَىٰكُمۡ قَوۡمٗا تَجۡهَلُونَ

Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì níí le àwọn t’ó gbàgbọ́ dànù. Dájúdájú wọn yóò pàdé Olúwa wọn, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ń ri yín sí ìjọ aláìmọ̀kan
Surah Hud, Verse 29


وَيَٰقَوۡمِ مَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِن طَرَدتُّهُمۡۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ

Ẹ̀yin ìjọ mi, ta ni ó máa ràn mí lọ́wọ́ níbi (ìyà) Allāhu tí mo bá lé wọn dànù? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni
Surah Hud, Verse 30


وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ إِنِّي مَلَكٞ وَلَآ أَقُولُ لِلَّذِينَ تَزۡدَرِيٓ أَعۡيُنُكُمۡ لَن يُؤۡتِيَهُمُ ٱللَّهُ خَيۡرًاۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا فِيٓ أَنفُسِهِمۡ إِنِّيٓ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Èmi kò sì sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí
Surah Hud, Verse 31


قَالُواْ يَٰنُوحُ قَدۡ جَٰدَلۡتَنَا فَأَكۡثَرۡتَ جِدَٰلَنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ

Wọ́n wí pé: "Ìwọ Nūh, O mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo
Surah Hud, Verse 32


قَالَ إِنَّمَا يَأۡتِيكُم بِهِ ٱللَّهُ إِن شَآءَ وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ

(Ànábì Nūh) sọ pé: "Allāhu l’Ó máa mú un wá ba yín tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́
Surah Hud, Verse 33


وَلَا يَنفَعُكُمۡ نُصۡحِيٓ إِنۡ أَرَدتُّ أَنۡ أَنصَحَ لَكُمۡ إِن كَانَ ٱللَّهُ يُرِيدُ أَن يُغۡوِيَكُمۡۚ هُوَ رَبُّكُمۡ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ

Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Hud, Verse 34


أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ إِنِ ٱفۡتَرَيۡتُهُۥ فَعَلَيَّ إِجۡرَامِي وَأَنَا۠ بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُجۡرِمُونَ

Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni." Sọ pé: "Tí mó bá hun ún, èmi ni mo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń dá lẹ́ṣẹ̀
Surah Hud, Verse 35


وَأُوحِيَ إِلَىٰ نُوحٍ أَنَّهُۥ لَن يُؤۡمِنَ مِن قَوۡمِكَ إِلَّا مَن قَدۡ ءَامَنَ فَلَا تَبۡتَئِسۡ بِمَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni t’ó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Hud, Verse 36


وَٱصۡنَعِ ٱلۡفُلۡكَ بِأَعۡيُنِنَا وَوَحۡيِنَا وَلَا تُخَٰطِبۡنِي فِي ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ إِنَّهُم مُّغۡرَقُونَ

Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí. Dájúdájú A máa tẹ̀ wọ́n rì ni
Surah Hud, Verse 37


وَيَصۡنَعُ ٱلۡفُلۡكَ وَكُلَّمَا مَرَّ عَلَيۡهِ مَلَأٞ مِّن قَوۡمِهِۦ سَخِرُواْ مِنۡهُۚ قَالَ إِن تَسۡخَرُواْ مِنَّا فَإِنَّا نَسۡخَرُ مِنكُمۡ كَمَا تَسۡخَرُونَ

Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: "Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́
Surah Hud, Verse 38


فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ مَن يَأۡتِيهِ عَذَابٞ يُخۡزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيۡهِ عَذَابٞ مُّقِيمٌ

Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí
Surah Hud, Verse 39


حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَمۡرُنَا وَفَارَ ٱلتَّنُّورُ قُلۡنَا ٱحۡمِلۡ فِيهَا مِن كُلّٖ زَوۡجَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِ وَأَهۡلَكَ إِلَّا مَن سَبَقَ عَلَيۡهِ ٱلۡقَوۡلُ وَمَنۡ ءَامَنَۚ وَمَآ ءَامَنَ مَعَهُۥٓ إِلَّا قَلِيلٞ

(Báyìí ni ọ̀rọ̀ wà) títí di ìgbà tí àṣẹ Wa dé, omi sì ṣẹ́yọ gbùú láti ojú-àrò (tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì). A sọ pé: "Kó gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ sínú ọkọ̀ ojú-omi - àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí (fún ìparun) - àti ẹnikẹ́ni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì sí ẹni t’ó ní ìgbàgbọ́ òdodo pẹ̀lú rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀
Surah Hud, Verse 40


۞وَقَالَ ٱرۡكَبُواْ فِيهَا بِسۡمِ ٱللَّهِ مَجۡرٜىٰهَا وَمُرۡسَىٰهَآۚ إِنَّ رَبِّي لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ

(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ wọ inú ọkọ̀ ojú-omi náà. Ó máa rìn, ó sì máa gúnlẹ̀ ní orúkọ Allāhu. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Hud, Verse 41


وَهِيَ تَجۡرِي بِهِمۡ فِي مَوۡجٖ كَٱلۡجِبَالِ وَنَادَىٰ نُوحٌ ٱبۡنَهُۥ وَكَانَ فِي مَعۡزِلٖ يَٰبُنَيَّ ٱرۡكَب مَّعَنَا وَلَا تَكُن مَّعَ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Ó sì ń gbé wọn lọ nínú ìgbì omi t’ó dà bí àpáta. (Ànábì Nūh) sì ké sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó ti yara rẹ̀ sọ́tọ̀: "Ọmọkùnrin mi, gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú wa. Má sì ṣe wà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Hud, Verse 42


قَالَ سَـَٔاوِيٓ إِلَىٰ جَبَلٖ يَعۡصِمُنِي مِنَ ٱلۡمَآءِۚ قَالَ لَا عَاصِمَ ٱلۡيَوۡمَ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِ إِلَّا مَن رَّحِمَۚ وَحَالَ بَيۡنَهُمَا ٱلۡمَوۡجُ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُغۡرَقِينَ

Ó wí pé: “Èmi yóò forí pamọ́ síbi àpáta kan tí ó máa là mí níbi omi.” (Ànábì Nūh) sọ pé: "Kò sí aláàbò kan ní òní níbi àṣẹ Allāhu àfi ẹni tí Allāhu bá ṣàánú." Ìgbì omi sì la àwọn méjèèjì láààrin. Ó sì di ara àwọn olùtẹ̀rì sínú omi
Surah Hud, Verse 43


وَقِيلَ يَـٰٓأَرۡضُ ٱبۡلَعِي مَآءَكِ وَيَٰسَمَآءُ أَقۡلِعِي وَغِيضَ ٱلۡمَآءُ وَقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ وَٱسۡتَوَتۡ عَلَى ٱلۡجُودِيِّۖ وَقِيلَ بُعۡدٗا لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ

A sọ pé: "Ilẹ̀, fa omi rẹ mu. Sánmọ̀, dáwọ́ (òjò) dúró." Wọ́n sì dín omi kù. Ọ̀rọ̀ ìparun wọn sì wá sí ìmúṣẹ. (Ọkọ̀ ojú-omi) sì gúnlẹ̀ sórí àpáta Jūdī. A sì sọ pé: “Ìjìnnà réré sí ìkẹ́ Allāhu ni ti ìjọ alábòsí.”
Surah Hud, Verse 44


وَنَادَىٰ نُوحٞ رَّبَّهُۥ فَقَالَ رَبِّ إِنَّ ٱبۡنِي مِنۡ أَهۡلِي وَإِنَّ وَعۡدَكَ ٱلۡحَقُّ وَأَنتَ أَحۡكَمُ ٱلۡحَٰكِمِينَ

(Ànábì) Nūh pe Olúwa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú ọmọ mi wà nínú ará ilé mi. Àti pé dájúdájú àdéhùn Rẹ, òdodo ni. Ìwọ l’O sì mọ ẹjọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́
Surah Hud, Verse 45


قَالَ يَٰنُوحُ إِنَّهُۥ لَيۡسَ مِنۡ أَهۡلِكَۖ إِنَّهُۥ عَمَلٌ غَيۡرُ صَٰلِحٖۖ فَلَا تَسۡـَٔلۡنِ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۖ إِنِّيٓ أَعِظُكَ أَن تَكُونَ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ

Allāhu sọ pé: “Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan.”
Surah Hud, Verse 46


قَالَ رَبِّ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِكَ أَنۡ أَسۡـَٔلَكَ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمٞۖ وَإِلَّا تَغۡفِرۡ لِي وَتَرۡحَمۡنِيٓ أَكُن مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń sá di Ọ́ níbi kí n̄g bi Ọ́ léèrè n̄ǹkan tí èmi kò ní ìmọ̀ rẹ̀. Tí O ò bá foríjìn mí, kí O sì ṣàánú mi, èmi yóò wà lára àwọn ẹni òfò
Surah Hud, Verse 47


قِيلَ يَٰنُوحُ ٱهۡبِطۡ بِسَلَٰمٖ مِّنَّا وَبَرَكَٰتٍ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ أُمَمٖ مِّمَّن مَّعَكَۚ وَأُمَمٞ سَنُمَتِّعُهُمۡ ثُمَّ يَمَسُّهُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٞ

A sọ pé: "Nūh, sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Wa. Àti pé kí ìbùkún wà pẹ̀lú rẹ àti àwọn ìjọ nínú àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Àwọn ìjọ kan (tún ń bọ̀), tí A óò fún wọn ní ìgbádùn (oore ayé). Lẹ́yìn náà, ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ bà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Wa
Surah Hud, Verse 48


تِلۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهَآ إِلَيۡكَۖ مَا كُنتَ تَعۡلَمُهَآ أَنتَ وَلَا قَوۡمُكَ مِن قَبۡلِ هَٰذَاۖ فَٱصۡبِرۡۖ إِنَّ ٱلۡعَٰقِبَةَ لِلۡمُتَّقِينَ

Ìwọ̀nyí wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi (ìmísí rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ àti ìjọ rẹ kò nímọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ). Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú ìkángun rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
Surah Hud, Verse 49


وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمۡ هُودٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۖ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا مُفۡتَرُونَ

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran ‘Ād ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe aládàápa irọ́
Surah Hud, Verse 50


يَٰقَوۡمِ لَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًاۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱلَّذِي فَطَرَنِيٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ

Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá mi. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni
Surah Hud, Verse 51


وَيَٰقَوۡمِ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِ يُرۡسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيۡكُم مِّدۡرَارٗا وَيَزِدۡكُمۡ قُوَّةً إِلَىٰ قُوَّتِكُمۡ وَلَا تَتَوَلَّوۡاْ مُجۡرِمِينَ

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olùwa Ẹlẹ́dàá yín, lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè rọ̀jò fun yín ní púpọ̀ láti sánmọ̀ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún agbára kún agbára yín. Ẹ má ṣe pẹ̀yìn dà láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ (sínú àìgbàgbọ́)
Surah Hud, Verse 52


قَالُواْ يَٰهُودُ مَا جِئۡتَنَا بِبَيِّنَةٖ وَمَا نَحۡنُ بِتَارِكِيٓ ءَالِهَتِنَا عَن قَوۡلِكَ وَمَا نَحۡنُ لَكَ بِمُؤۡمِنِينَ

Wọ́n wí pé: "Hūd, o ò mú ẹ̀rí kan t’ó yanjú wá fún wa. Àwa kò sì níí gbé àwọn òrìṣà wa jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ. Àti pé àwa kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ
Surah Hud, Verse 53


إِن نَّقُولُ إِلَّا ٱعۡتَرَىٰكَ بَعۡضُ ءَالِهَتِنَا بِسُوٓءٖۗ قَالَ إِنِّيٓ أُشۡهِدُ ٱللَّهَ وَٱشۡهَدُوٓاْ أَنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ

ǹkan tí à ń sọ fún ọ ni pé àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (l’ó fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn)." Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ
Surah Hud, Verse 54


مِن دُونِهِۦۖ فَكِيدُونِي جَمِيعٗا ثُمَّ لَا تُنظِرُونِ

dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára
Surah Hud, Verse 55


إِنِّي تَوَكَّلۡتُ عَلَى ٱللَّهِ رَبِّي وَرَبِّكُمۚ مَّا مِن دَآبَّةٍ إِلَّا هُوَ ءَاخِذُۢ بِنَاصِيَتِهَآۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà
Surah Hud, Verse 56


فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقَدۡ أَبۡلَغۡتُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦٓ إِلَيۡكُمۡۚ وَيَسۡتَخۡلِفُ رَبِّي قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ وَلَا تَضُرُّونَهُۥ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَفِيظٞ

Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fun yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan t’ó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ ò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Hud, Verse 57


وَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا هُودٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَنَجَّيۡنَٰهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà t’ó nípọn
Surah Hud, Verse 58


وَتِلۡكَ عَادٞۖ جَحَدُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَعَصَوۡاْ رُسُلَهُۥ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَمۡرَ كُلِّ جَبَّارٍ عَنِيدٖ

Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo
Surah Hud, Verse 59


وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ عَادٗا كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّعَادٖ قَوۡمِ هُودٖ

A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd
Surah Hud, Verse 60


۞وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ هُوَ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَٱسۡتَعۡمَرَكُمۡ فِيهَا فَٱسۡتَغۡفِرُوهُ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِۚ إِنَّ رَبِّي قَرِيبٞ مُّجِيبٞ

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l’Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fun yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá).”
Surah Hud, Verse 61


قَالُواْ يَٰصَٰلِحُ قَدۡ كُنتَ فِينَا مَرۡجُوّٗا قَبۡلَ هَٰذَآۖ أَتَنۡهَىٰنَآ أَن نَّعۡبُدَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ

Wọ́n wí pé: “Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí.”
Surah Hud, Verse 62


قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَءَاتَىٰنِي مِنۡهُ رَحۡمَةٗ فَمَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِنۡ عَصَيۡتُهُۥۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيۡرَ تَخۡسِيرٖ

Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun
Surah Hud, Verse 63


وَيَٰقَوۡمِ هَٰذِهِۦ نَاقَةُ ٱللَّهِ لَكُمۡ ءَايَةٗۖ فَذَرُوهَا تَأۡكُلۡ فِيٓ أَرۡضِ ٱللَّهِۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابٞ قَرِيبٞ

Ẹ̀yin ìjọ mi, èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. Ó jẹ́ àmì fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ́ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ìnira kàn án nítorí kí ìyà t’ó súnmọ́ má báa jẹ yín
Surah Hud, Verse 64


فَعَقَرُوهَا فَقَالَ تَمَتَّعُواْ فِي دَارِكُمۡ ثَلَٰثَةَ أَيَّامٖۖ ذَٰلِكَ وَعۡدٌ غَيۡرُ مَكۡذُوبٖ

Wọ́n sì gún un pa. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ̀gbádùn nínú ilé yín fún ọjọ́ mẹ́ta (kí ìyà yín tó dé). Ìyẹn ni àdéhùn tí kì í ṣe irọ́.”
Surah Hud, Verse 65


فَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا صَٰلِحٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَمِنۡ خِزۡيِ يَوۡمِئِذٍۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡعَزِيزُ

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Sọ̄lih àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. (A tún gbà wọ́n là) nínú àbùkù ọjọ́ yẹn. Dájúdájú Olúwa Rẹ, Òun ni Alágbára, Olùborí (ẹ̀dá)
Surah Hud, Verse 66


وَأَخَذَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلصَّيۡحَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دِيَٰرِهِمۡ جَٰثِمِينَ

Ohùn igbe líle gbá àwọn t’ó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn
Surah Hud, Verse 67


كَأَن لَّمۡ يَغۡنَوۡاْ فِيهَآۗ أَلَآ إِنَّ ثَمُودَاْ كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّثَمُودَ

Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí. Gbọ́, dájúdájú ìran Thamūd ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìjọ Thamūd
Surah Hud, Verse 68


وَلَقَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُنَآ إِبۡرَٰهِيمَ بِٱلۡبُشۡرَىٰ قَالُواْ سَلَٰمٗاۖ قَالَ سَلَٰمٞۖ فَمَا لَبِثَ أَن جَآءَ بِعِجۡلٍ حَنِيذٖ

Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ti mú ìró ìdùnnú wá bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Wọ́n sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Ó sọ pé: “Àlàáfíà (fun yín).” Kò sì pẹ́ rárá t’ó fi gbé ọmọ màálù àyangbẹ wá
Surah Hud, Verse 69


فَلَمَّا رَءَآ أَيۡدِيَهُمۡ لَا تَصِلُ إِلَيۡهِ نَكِرَهُمۡ وَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةٗۚ قَالُواْ لَا تَخَفۡ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمِ لُوطٖ

Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ, ó f’ojú òdì wo (àìjẹun) wọn. Ìbẹ̀rù wọn sí wà nínú ọkàn rẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí.”
Surah Hud, Verse 70


وَٱمۡرَأَتُهُۥ قَآئِمَةٞ فَضَحِكَتۡ فَبَشَّرۡنَٰهَا بِإِسۡحَٰقَ وَمِن وَرَآءِ إِسۡحَٰقَ يَعۡقُوبَ

Ìyàwó rẹ̀ wà ní ìdúró, ó rẹ́rìn-ín. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (pé ó máa bí) ’Ishāƙ. Àti pé lẹ́yìn ’Ishāƙ ni Ya‘ƙūb (ìyẹn, ọmọọmọ)
Surah Hud, Verse 71


قَالَتۡ يَٰوَيۡلَتَىٰٓ ءَأَلِدُ وَأَنَا۠ عَجُوزٞ وَهَٰذَا بَعۡلِي شَيۡخًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عَجِيبٞ

Ó sọ pé: “Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ? Arúgbóbìnrin ni mi, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu.”
Surah Hud, Verse 72


قَالُوٓاْ أَتَعۡجَبِينَ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِۖ رَحۡمَتُ ٱللَّهِ وَبَرَكَٰتُهُۥ عَلَيۡكُمۡ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِۚ إِنَّهُۥ حَمِيدٞ مَّجِيدٞ

Wọ́n sọ pé: “Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fun yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́, Ẹlẹ́yìn.”
Surah Hud, Verse 73


فَلَمَّا ذَهَبَ عَنۡ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلرَّوۡعُ وَجَآءَتۡهُ ٱلۡبُشۡرَىٰ يُجَٰدِلُنَا فِي قَوۡمِ لُوطٍ

Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a, ó sì ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt
Surah Hud, Verse 74


إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ لَحَلِيمٌ أَوَّـٰهٞ مُّنِيبٞ

Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà
Surah Hud, Verse 75


يَـٰٓإِبۡرَٰهِيمُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَآۖ إِنَّهُۥ قَدۡ جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَإِنَّهُمۡ ءَاتِيهِمۡ عَذَابٌ غَيۡرُ مَرۡدُودٖ

(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá
Surah Hud, Verse 76


وَلَمَّا جَآءَتۡ رُسُلُنَا لُوطٗا سِيٓءَ بِهِمۡ وَضَاقَ بِهِمۡ ذَرۡعٗا وَقَالَ هَٰذَا يَوۡمٌ عَصِيبٞ

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ t’ó le púpọ̀.”
Surah Hud, Verse 77


وَجَآءَهُۥ قَوۡمُهُۥ يُهۡرَعُونَ إِلَيۡهِ وَمِن قَبۡلُ كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ هَـٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِي هُنَّ أَطۡهَرُ لَكُمۡۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ فِي ضَيۡفِيٓۖ أَلَيۡسَ مِنكُمۡ رَجُلٞ رَّشِيدٞ

Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bíi ìbálòpọ̀ láààrin ọkùnrin àti ọkùnrin). Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyẹn ni ọmọbìnrin mi, wọ́n mọ́ jùlọ fun yín (láti fi ṣaya). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin olùmọ̀nà kan nínú yín ni
Surah Hud, Verse 78


قَالُواْ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَا لَنَا فِي بَنَاتِكَ مِنۡ حَقّٖ وَإِنَّكَ لَتَعۡلَمُ مَا نُرِيدُ

Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò lẹ́tọ̀ọ́ kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́.”
Surah Hud, Verse 79


قَالَ لَوۡ أَنَّ لِي بِكُمۡ قُوَّةً أَوۡ ءَاوِيٓ إِلَىٰ رُكۡنٖ شَدِيدٖ

Ó sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan t’ó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín)
Surah Hud, Verse 80


قَالُواْ يَٰلُوطُ إِنَّا رُسُلُ رَبِّكَ لَن يَصِلُوٓاْ إِلَيۡكَۖ فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٌ إِلَّا ٱمۡرَأَتَكَۖ إِنَّهُۥ مُصِيبُهَا مَآ أَصَابَهُمۡۚ إِنَّ مَوۡعِدَهُمُ ٱلصُّبۡحُۚ أَلَيۡسَ ٱلصُّبۡحُ بِقَرِيبٖ

(Àwọn mọlāika) sọ pé: “(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru. Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú àdánwò rẹ̀ ni ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni
Surah Hud, Verse 81


فَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا جَعَلۡنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهَا حِجَارَةٗ مِّن سِجِّيلٖ مَّنضُودٖ

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé
Surah Hud, Verse 82


مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَۖ وَمَا هِيَ مِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ بِبَعِيدٖ

(Àwọn òkúta náà) ti ní àmì (orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lára) láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Wọn kò sì jìnnà sí àwọn alábòsí
Surah Hud, Verse 83


۞وَإِلَىٰ مَدۡيَنَ أَخَاهُمۡ شُعَيۡبٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ وَلَا تَنقُصُواْ ٱلۡمِكۡيَالَ وَٱلۡمِيزَانَۖ إِنِّيٓ أَرَىٰكُم بِخَيۡرٖ وَإِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٖ مُّحِيطٖ

(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Mọdyan ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣua‘eb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe dín kóńgò àti òṣùwọ̀n kù. Mo rí yín pẹ̀lú dáadáa (tí Allāhu ṣe fun yín). Dájúdájú èmi sì ń páyà ìyà ọjọ́ kan tí ó máa yi yín po
Surah Hud, Verse 84


وَيَٰقَوۡمِ أَوۡفُواْ ٱلۡمِكۡيَالَ وَٱلۡمِيزَانَ بِٱلۡقِسۡطِۖ وَلَا تَبۡخَسُواْ ٱلنَّاسَ أَشۡيَآءَهُمۡ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gbadọ́gba. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe balẹ̀ jẹ́ ní ti òbìlẹ̀jẹ́
Surah Hud, Verse 85


بَقِيَّتُ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَۚ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِحَفِيظٖ

Ohun tí Allāhu bá ṣẹ́kù fun yín (nínú halāl) lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Èmi kì í sì ṣe olùṣọ́ lórí yín
Surah Hud, Verse 86


قَالُواْ يَٰشُعَيۡبُ أَصَلَوٰتُكَ تَأۡمُرُكَ أَن نَّتۡرُكَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَآ أَوۡ أَن نَّفۡعَلَ فِيٓ أَمۡوَٰلِنَا مَا نَشَـٰٓؤُاْۖ إِنَّكَ لَأَنتَ ٱلۡحَلِيمُ ٱلرَّشِيدُ

Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, ṣé ìrun rẹ l’ó ń pa ọ́ láṣẹ pé kí á gbé ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún jù sílẹ̀, tàbí (ìrun rẹ ló ń kọ̀ fún wa) láti ṣe ohun tí a bá fẹ́ nínú dúkìá wa? Dájúdájú ìwọ mà ni aláfaradà, olùmọ̀nà (lójú ara rẹ nìyẹn)
Surah Hud, Verse 87


قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَرَزَقَنِي مِنۡهُ رِزۡقًا حَسَنٗاۚ وَمَآ أُرِيدُ أَنۡ أُخَالِفَكُمۡ إِلَىٰ مَآ أَنۡهَىٰكُمۡ عَنۡهُۚ إِنۡ أُرِيدُ إِلَّا ٱلۡإِصۡلَٰحَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُۚ وَمَا تَوۡفِيقِيٓ إِلَّا بِٱللَّهِۚ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ

Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé mo wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí (Olúwa mi) sì fún mi ní arísìkí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní arísìkí t’ó dára (ṣé kí n̄g máa jẹ harāmu pẹ̀lú rẹ̀ ni?). Èmi kò sì fẹ́ yapa yín nípa n̄ǹkan tí mò ń kọ̀ fun yín (ìyẹn ni pé, èmi náà ń lo ohun tí mò ń sọ fun yín). Kò sí ohun tí mo fẹ́ bí kò ṣe àtúnṣe pẹ̀lú bí mo ṣe lágbára mọ. Kò sí kòǹgẹ́ ìmọ̀nà kan fún mi bí kò ṣe pẹ̀lú (ìyọ̀ǹda) Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí sí (fún ìronúpìwàdà)
Surah Hud, Verse 88


وَيَٰقَوۡمِ لَا يَجۡرِمَنَّكُمۡ شِقَاقِيٓ أَن يُصِيبَكُم مِّثۡلُ مَآ أَصَابَ قَوۡمَ نُوحٍ أَوۡ قَوۡمَ هُودٍ أَوۡ قَوۡمَ صَٰلِحٖۚ وَمَا قَوۡمُ لُوطٖ مِّنكُم بِبَعِيدٖ

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí (bí) ẹ ṣe ń yapa mi mu yín lùgbàdì irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ (Ànábì) Nūh tàbí ìjọ (Ànábì) Hūd tàbí ìjọ (Ànábì) Sọ̄lih. Ìjọ (Ànábì) Lūt kò sì jìnnà si yín
Surah Hud, Verse 89


وَٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِۚ إِنَّ رَبِّي رَحِيمٞ وَدُودٞ

Kí ẹ sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá).”
Surah Hud, Verse 90


قَالُواْ يَٰشُعَيۡبُ مَا نَفۡقَهُ كَثِيرٗا مِّمَّا تَقُولُ وَإِنَّا لَنَرَىٰكَ فِينَا ضَعِيفٗاۖ وَلَوۡلَا رَهۡطُكَ لَرَجَمۡنَٰكَۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡنَا بِعَزِيزٖ

Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, a ò gbọ́ àgbọ́yé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ò ń sọ. Dájúdájú àwa sì ń rí ọ ní ọ̀lẹ láààrin wa. Tí kò bá jẹ́ pé nítorí ti ẹbí rẹ ni, a ìbá ti kù ọ́ lókò pa; ìwọ kò sì níí lágbára kan lórí wa
Surah Hud, Verse 91


قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَهۡطِيٓ أَعَزُّ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱللَّهِ وَٱتَّخَذۡتُمُوهُ وَرَآءَكُمۡ ظِهۡرِيًّاۖ إِنَّ رَبِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ مُحِيطٞ

Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé ẹbí mi ló lágbára lójú yin ju Allāhu? Ẹ sì sọ Allāhu di Ẹni tí ẹ kọ̀yìn kọ̀pàkọ́ sí! Dájúdájú Olúwa mi ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Hud, Verse 92


وَيَٰقَوۡمِ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنِّي عَٰمِلٞۖ سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ مَن يَأۡتِيهِ عَذَابٞ يُخۡزِيهِ وَمَنۡ هُوَ كَٰذِبٞۖ وَٱرۡتَقِبُوٓاْ إِنِّي مَعَكُمۡ رَقِيبٞ

Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín, dájúdájú èmi yóò máa bá ẹ̀sìn mi lọ. Láìpẹ́ ẹ̀yin yóò mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, (ẹ̀yin yó sì mọ) ta ni òpùrọ́. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín tí mò ń retí (ìkángun ọ̀rọ̀ yín).”
Surah Hud, Verse 93


وَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا شُعَيۡبٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَأَخَذَتِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلصَّيۡحَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دِيَٰرِهِمۡ جَٰثِمِينَ

Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn
Surah Hud, Verse 94


كَأَن لَّمۡ يَغۡنَوۡاْ فِيهَآۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّمَدۡيَنَ كَمَا بَعِدَتۡ ثَمُودُ

Àfi bí ẹni pé wọn kò gbé inú ìlú náà rí. Gbọ́, ìjìnnà sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran Mọdyan gẹ́gẹ́ bí ìran Thamūd ṣe jìnnà sí ìkẹ́
Surah Hud, Verse 95


وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ

Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā
Surah Hud, Verse 96


إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَٱتَّبَعُوٓاْ أَمۡرَ فِرۡعَوۡنَۖ وَمَآ أَمۡرُ فِرۡعَوۡنَ بِرَشِيدٖ

sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà
Surah Hud, Verse 97


يَقۡدُمُ قَوۡمَهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَأَوۡرَدَهُمُ ٱلنَّارَۖ وَبِئۡسَ ٱلۡوِرۡدُ ٱلۡمَوۡرُودُ

Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú
Surah Hud, Verse 98


وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِۦ لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ بِئۡسَ ٱلرِّفۡدُ ٱلۡمَرۡفُودُ

A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn ègún tí A fún wọn sì burú
Surah Hud, Verse 99


ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡقُرَىٰ نَقُصُّهُۥ عَلَيۡكَۖ مِنۡهَا قَآئِمٞ وَحَصِيدٞ

Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí ó ti parẹ́
Surah Hud, Verse 100


وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡۖ فَمَآ أَغۡنَتۡ عَنۡهُمۡ ءَالِهَتُهُمُ ٱلَّتِي يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖ لَّمَّا جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَمَا زَادُوهُمۡ غَيۡرَ تَتۡبِيبٖ

A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun
Surah Hud, Verse 101


وَكَذَٰلِكَ أَخۡذُ رَبِّكَ إِذَآ أَخَذَ ٱلۡقُرَىٰ وَهِيَ ظَٰلِمَةٌۚ إِنَّ أَخۡذَهُۥٓ أَلِيمٞ شَدِيدٌ

Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le
Surah Hud, Verse 102


إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّمَنۡ خَافَ عَذَابَ ٱلۡأٓخِرَةِۚ ذَٰلِكَ يَوۡمٞ مَّجۡمُوعٞ لَّهُ ٱلنَّاسُ وَذَٰلِكَ يَوۡمٞ مَّشۡهُودٞ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni t’ó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí
Surah Hud, Verse 103


وَمَا نُؤَخِّرُهُۥٓ إِلَّا لِأَجَلٖ مَّعۡدُودٖ

A ò sì fi falẹ̀ bí kò ṣe di àkókò t’ó lọ́jọ́
Surah Hud, Verse 104


يَوۡمَ يَأۡتِ لَا تَكَلَّمُ نَفۡسٌ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ فَمِنۡهُمۡ شَقِيّٞ وَسَعِيدٞ

Ní ọjọ́ t’ó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà)
Surah Hud, Verse 105


فَأَمَّا ٱلَّذِينَ شَقُواْ فَفِي ٱلنَّارِ لَهُمۡ فِيهَا زَفِيرٞ وَشَهِيقٌ

Ní ti àwọn t’ó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò
Surah Hud, Verse 106


خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۚ إِنَّ رَبَّكَ فَعَّالٞ لِّمَا يُرِيدُ

Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́ . Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú
Surah Hud, Verse 107


۞وَأَمَّا ٱلَّذِينَ سُعِدُواْ فَفِي ٱلۡجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۖ عَطَآءً غَيۡرَ مَجۡذُوذٖ

Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ,1 àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.2 (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin
Surah Hud, Verse 108


فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّمَّا يَعۡبُدُ هَـٰٓؤُلَآءِۚ مَا يَعۡبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُهُم مِّن قَبۡلُۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمۡ نَصِيبَهُمۡ غَيۡرَ مَنقُوصٖ

Nítorí náà, má ṣe wà nínú ròyíròyí nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí kù síbì kan
Surah Hud, Verse 109


وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ

A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kì í bá ṣe ọ̀rọ̀ kan tí ó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān
Surah Hud, Verse 110


وَإِنَّ كُلّٗا لَّمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمۡ رَبُّكَ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ إِنَّهُۥ بِمَا يَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ

Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Hud, Verse 111


فَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَ وَمَن تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطۡغَوۡاْۚ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ

Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Hud, Verse 112


وَلَا تَرۡكَنُوٓاْ إِلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ فَتَمَسَّكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِنۡ أَوۡلِيَآءَ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ

Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fun yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́
Surah Hud, Verse 113


وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ طَرَفَيِ ٱلنَّهَارِ وَزُلَفٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِۚ إِنَّ ٱلۡحَسَنَٰتِ يُذۡهِبۡنَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ ذَٰلِكَ ذِكۡرَىٰ لِلذَّـٰكِرِينَ

Kírun ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀sán (ìyẹn, ìrun Subh, Ṭḥuhr àti ‘Asr) àti ní ìbẹ̀rẹ̀ òru (ìyẹn, ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’). Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu)
Surah Hud, Verse 114


وَٱصۡبِرۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre
Surah Hud, Verse 115


فَلَوۡلَا كَانَ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مِن قَبۡلِكُمۡ أُوْلُواْ بَقِيَّةٖ يَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡفَسَادِ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّنۡ أَنجَيۡنَا مِنۡهُمۡۗ وَٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَآ أُتۡرِفُواْ فِيهِ وَكَانُواْ مُجۡرِمِينَ

Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ – àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn t’ó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀
Surah Hud, Verse 116


وَمَا كَانَ رَبُّكَ لِيُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ بِظُلۡمٖ وَأَهۡلُهَا مُصۡلِحُونَ

Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe
Surah Hud, Verse 117


وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَجَعَلَ ٱلنَّاسَ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗۖ وَلَا يَزَالُونَ مُخۡتَلِفِينَ

Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, ìbá ṣe àwọn ènìyàn ní ìjọ ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo. (Àmọ́) wọn kò níí yé yapa ẹnu (sí ’Islām)
Surah Hud, Verse 118


إِلَّا مَن رَّحِمَ رَبُّكَۚ وَلِذَٰلِكَ خَلَقَهُمۡۗ وَتَمَّتۡ كَلِمَةُ رَبِّكَ لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ

àfi ẹni tí Olúwa rẹ bá kẹ́. Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn. Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ sì ti ṣẹ (báyìí pé): “Dájúdájú Èmi yóò mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kúnnú iná Jahanamọ.”
Surah Hud, Verse 119


وَكُلّٗا نَّقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلرُّسُلِ مَا نُثَبِّتُ بِهِۦ فُؤَادَكَۚ وَجَآءَكَ فِي هَٰذِهِ ٱلۡحَقُّ وَمَوۡعِظَةٞ وَذِكۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ

Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Hud, Verse 120


وَقُل لِّلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنَّا عَٰمِلُونَ

Kí o sì sọ fún àwọn tí kò gbàgbọ́ pé: "Ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín. Dájúdájú àwa náà yóò máa bá ẹ̀sìn wa lọ
Surah Hud, Verse 121


وَٱنتَظِرُوٓاْ إِنَّا مُنتَظِرُونَ

Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí
Surah Hud, Verse 122


وَلِلَّهِ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَإِلَيۡهِ يُرۡجَعُ ٱلۡأَمۡرُ كُلُّهُۥ فَٱعۡبُدۡهُ وَتَوَكَّلۡ عَلَيۡهِۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ

Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Hud, Verse 123


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 10
>> Surah 12

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai