Surah Yusuf - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ
’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira t’o yanju oro eda
Surah Yusuf, Verse 1
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
Dajudaju Awa so o kale ni nnkan kike ni ede Larubawa nitori ki e le se laakaye
Surah Yusuf, Verse 2
نَحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ أَحۡسَنَ ٱلۡقَصَصِ بِمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ وَإِن كُنتَ مِن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ
Awa n so itan t’o dara julo fun o pelu ohun ti A fi ranse si o (ninu imisi) al-Ƙur’an yii, bi o tile je pe siwaju imisi naa iwo wa lara awon ti ko nimo (nipa re)
Surah Yusuf, Verse 3
إِذۡ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَـٰٓأَبَتِ إِنِّي رَأَيۡتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوۡكَبٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ رَأَيۡتُهُمۡ لِي سَٰجِدِينَ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Yusuf so fun baba re pe: “Baba mi, dajudaju emi (lalaa) ri awon irawo mokanla, oorun ati osupa. Mo ri won ti won fori kanle fun mi.”
Surah Yusuf, Verse 4
قَالَ يَٰبُنَيَّ لَا تَقۡصُصۡ رُءۡيَاكَ عَلَىٰٓ إِخۡوَتِكَ فَيَكِيدُواْ لَكَ كَيۡدًاۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
O so pe: "Omo mi, ma se ro ala re fun awon obakan re nitori ki won ma baa dete si o. Dajudaju Esu ni ota ponnbele fun eniyan
Surah Yusuf, Verse 5
وَكَذَٰلِكَ يَجۡتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِ وَيُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ ءَالِ يَعۡقُوبَ كَمَآ أَتَمَّهَا عَلَىٰٓ أَبَوَيۡكَ مِن قَبۡلُ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Bayen ni Oluwa re yoo se sa o lesa. O maa fi itumo ala mo o. O si maa pe idera Re fun iwo ati awon ebi Ya‘ƙub, gege bi O se pe e siwaju fun awon baba re mejeeji, (Anabi) ’Ibrohim ati ’Ishaƙ. Dajudaju Oluwa re ni Onimo, Ologbon
Surah Yusuf, Verse 6
۞لَّقَدۡ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخۡوَتِهِۦٓ ءَايَٰتٞ لِّلسَّآئِلِينَ
Dajudaju awon ami (ariwoye) n be fun awon onibeeere nipa (itan Anabi) Yusuf ati awon obakan re
Surah Yusuf, Verse 7
إِذۡ قَالُواْ لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰٓ أَبِينَا مِنَّا وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
(Ranti) nigba ti won so pe: "Dajudaju Yusuf ati omo-iya re ni baba wa nifee si ju awa. Opo eniyan si ni awa. Dajudaju baba wa ma ti wa ninu asise ponnbele
Surah Yusuf, Verse 8
ٱقۡتُلُواْ يُوسُفَ أَوِ ٱطۡرَحُوهُ أَرۡضٗا يَخۡلُ لَكُمۡ وَجۡهُ أَبِيكُمۡ وَتَكُونُواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ قَوۡمٗا صَٰلِحِينَ
E pa Yusuf tabi ki e lo gbe e junu si ile (miiran) nitori ki baba yin le roju gbo tiyin. E si maa di eniyan rere leyin re
Surah Yusuf, Verse 9
قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ لَا تَقۡتُلُواْ يُوسُفَ وَأَلۡقُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّ يَلۡتَقِطۡهُ بَعۡضُ ٱلسَّيَّارَةِ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ
Onsoro kan ninu won so pe: "E ma se pa Yusuf. Ti o ba je pe e sa fe wa nnkan se (si oro re), e gbe e ju sinu isaleesale kannga nitori ki apa kan ninu awon onirin-ajo le baa he e lo
Surah Yusuf, Verse 10
قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا مَا لَكَ لَا تَأۡمَ۬نَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُۥ لَنَٰصِحُونَ
Won so pe: “Baba wa, ki ni ko mu o fi okan tan wa lori Yusuf. Dajudaju awa si maa je olutoju re
Surah Yusuf, Verse 11
أَرۡسِلۡهُ مَعَنَا غَدٗا يَرۡتَعۡ وَيَلۡعَبۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Je ki o ba wa lo ni ola nitori ki o le dara ya, ki o si le sere. Ati pe dajudaju awa ni oluso fun un.”
Surah Yusuf, Verse 12
قَالَ إِنِّي لَيَحۡزُنُنِيٓ أَن تَذۡهَبُواْ بِهِۦ وَأَخَافُ أَن يَأۡكُلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَأَنتُمۡ عَنۡهُ غَٰفِلُونَ
O so pe: “Dajudaju o maa ba mi ninu je pe ki e mu u lo. Mo si n paya ki ikoko ma lo pa a je nigba ti eyin ba gbagbe re (sibi kan).”
Surah Yusuf, Verse 13
قَالُواْ لَئِنۡ أَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّآ إِذٗا لَّخَٰسِرُونَ
Won so pe: “Ti ikoko ba fi pa a je, opo eniyan si ni wa, dajudaju awa nigba naa ni eni ofo.”
Surah Yusuf, Verse 14
فَلَمَّا ذَهَبُواْ بِهِۦ وَأَجۡمَعُوٓاْ أَن يَجۡعَلُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمۡرِهِمۡ هَٰذَا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Nigba ti won mu un lo tan, won panupo pe ki awon ju u si isaleesale kannga. A si fi imisi ranse si Yusuf pe: “Dajudaju iwo yoo fun won ni iro nipa oro won yii nigba ti won ko nii fura.”
Surah Yusuf, Verse 15
وَجَآءُوٓ أَبَاهُمۡ عِشَآءٗ يَبۡكُونَ
Won de ba baba won ni asale, ti won n sunkun
Surah Yusuf, Verse 16
قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَآ إِنَّا ذَهَبۡنَا نَسۡتَبِقُ وَتَرَكۡنَا يُوسُفَ عِندَ مَتَٰعِنَا فَأَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُؤۡمِنٖ لَّنَا وَلَوۡ كُنَّا صَٰدِقِينَ
Won so pe: “Baba wa, awa lo dije ere sisa. A si fi Yusuf sile sibi awon eru wa. Nigba naa ni ikoko pa a je. Iwo ko si nii gba wa gbo, awa ibaa je olododo.”
Surah Yusuf, Verse 17
وَجَآءُو عَلَىٰ قَمِيصِهِۦ بِدَمٖ كَذِبٖۚ قَالَ بَلۡ سَوَّلَتۡ لَكُمۡ أَنفُسُكُمۡ أَمۡرٗاۖ فَصَبۡرٞ جَمِيلٞۖ وَٱللَّهُ ٱلۡمُسۡتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ
Won de pelu eje iro lara ewu re. (Anabi Ya‘ƙub) so pe: "Rara o, emi yin l’o se oran kan losoo fun yin. Nitori naa, suuru abiyi (loro mi kan). Allahu ni Oluranlowo lori ohun ti e n royin
Surah Yusuf, Verse 18
وَجَآءَتۡ سَيَّارَةٞ فَأَرۡسَلُواْ وَارِدَهُمۡ فَأَدۡلَىٰ دَلۡوَهُۥۖ قَالَ يَٰبُشۡرَىٰ هَٰذَا غُلَٰمٞۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَٰعَةٗۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ
Awon onirin-ajo kan si de. Won ran aponmi won (ni omi). O si ju doro re sinu kannga. (Yusuf si diro mo okun doro bo sita. Aponmi si) so pe: "Ire idunnu re e! Eyi ni omodekunrin." Won si fi pamo fun tita (bi oja). Allahu si ni Onimo nipa ohun ti won n se nise
Surah Yusuf, Verse 19
وَشَرَوۡهُ بِثَمَنِۭ بَخۡسٖ دَرَٰهِمَ مَعۡدُودَةٖ وَكَانُواْ فِيهِ مِنَ ٱلزَّـٰهِدِينَ
Won ta a ni edinwo pelu owo diriham t’o niye. Won si je eni t’o mu un bin-intin
Surah Yusuf, Verse 20
وَقَالَ ٱلَّذِي ٱشۡتَرَىٰهُ مِن مِّصۡرَ لِٱمۡرَأَتِهِۦٓ أَكۡرِمِي مَثۡوَىٰهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗاۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلِنُعَلِّمَهُۥ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ وَٱللَّهُ غَالِبٌ عَلَىٰٓ أَمۡرِهِۦ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Eni ti o ra a ni (ilu) Misro so fun aya re pe: “Se ibugbe re daadaa. O sunmo ki o wulo fun wa tabi ki a fi somo.” Bayen ni A se fi aye gba Yusuf lori ile. Ati pe ki A tun le fi itumo ala mo on. Allahu ni Olubori lori ase Re, sugbon opolopo eniyan ni ko mo
Surah Yusuf, Verse 21
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥٓ ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Nigba ti o di gende tan, A fun un ni ogbon ijinle ati imo. Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan rere
Surah Yusuf, Verse 22
وَرَٰوَدَتۡهُ ٱلَّتِي هُوَ فِي بَيۡتِهَا عَن نَّفۡسِهِۦ وَغَلَّقَتِ ٱلۡأَبۡوَٰبَ وَقَالَتۡ هَيۡتَ لَكَۚ قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ رَبِّيٓ أَحۡسَنَ مَثۡوَايَۖ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
Obinrin ti Yusuf wa ninu ile re si jireebe fun ere ife lodo re. O si ti gbogbo ilekun pa. O so pe: “Sunmo mi.” (Yusuf) so pe: “Mo sadi Allahu. Dajudaju oko re ni oga mi. O si se ibugbe mi daadaa. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”
Surah Yusuf, Verse 23
وَلَقَدۡ هَمَّتۡ بِهِۦۖ وَهَمَّ بِهَا لَوۡلَآ أَن رَّءَا بُرۡهَٰنَ رَبِّهِۦۚ كَذَٰلِكَ لِنَصۡرِفَ عَنۡهُ ٱلسُّوٓءَ وَٱلۡفَحۡشَآءَۚ إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُخۡلَصِينَ
(Obinrin naa) kuku gbero ere ife si i. Oun naa gbero re, Ti ki i ba se pe o ri eri Oluwa re (pe haramu ni sina, iba sunmo on). Bayen ni (oro naa ri) nitori ki A le seri aburu ati sina sise kuro lodo re. Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon eni esa
Surah Yusuf, Verse 24
وَٱسۡتَبَقَا ٱلۡبَابَ وَقَدَّتۡ قَمِيصَهُۥ مِن دُبُرٖ وَأَلۡفَيَا سَيِّدَهَا لَدَا ٱلۡبَابِۚ قَالَتۡ مَا جَزَآءُ مَنۡ أَرَادَ بِأَهۡلِكَ سُوٓءًا إِلَّآ أَن يُسۡجَنَ أَوۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Awon mejeeji sare lo sibi ilekun. (Obinrin yii) si fa ewu (Yusuf) ya leyin. Awon mejeeji si ba oga re lenu ona. (Obinrin yii) si so pe: “Ki ni esan fun eni ti o gbero aburu si ara ile re bi ko se pe ki a so o sinu ogba ewon tabi iya eleta-elero.”
Surah Yusuf, Verse 25
قَالَ هِيَ رَٰوَدَتۡنِي عَن نَّفۡسِيۚ وَشَهِدَ شَاهِدٞ مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن قُبُلٖ فَصَدَقَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ
(Yusuf) so pe: “Oun l’o jireebe fun ere ife lodo mi.” Elerii kan ninu ara ile (obinrin naa) si jerii pe: "Ti o ba je pe won fa ewu re ya niwaju, (obinrin yii) l’o so ododo, (Yusuf) si wa ninu awon opuro
Surah Yusuf, Verse 26
وَإِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ فَكَذَبَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
Ti o ba si je pe won fa ewu re ya leyin, (obinrin yii) l’o paro, (Yusuf) si wa ninu awon olododo
Surah Yusuf, Verse 27
فَلَمَّا رَءَا قَمِيصَهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ قَالَ إِنَّهُۥ مِن كَيۡدِكُنَّۖ إِنَّ كَيۡدَكُنَّ عَظِيمٞ
Nigba ti (oko) ri ewu re ti won ti fa a ya leyin, o so pe: "Dajudaju ninu ete eyin obinrin ni (eyi). Dajudaju ete yin tobi
Surah Yusuf, Verse 28
يُوسُفُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَاۚ وَٱسۡتَغۡفِرِي لِذَنۢبِكِۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ ٱلۡخَاطِـِٔينَ
Yusuf, seri kuro nibi eyi. Ki iwo (obinrin yii) si toro aforijin fun ese re. Dajudaju iwo wa lara awon alasise
Surah Yusuf, Verse 29
۞وَقَالَ نِسۡوَةٞ فِي ٱلۡمَدِينَةِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ تُرَٰوِدُ فَتَىٰهَا عَن نَّفۡسِهِۦۖ قَدۡ شَغَفَهَا حُبًّاۖ إِنَّا لَنَرَىٰهَا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Awon obinrin kan ninu ilu so pe: “Ayaba n jireebe fun ere ife lodo omo odo re; ife kuku ti ko si i lokan. Dajudaju awa n ri oun pe o wa ninu asise ponnbele.”
Surah Yusuf, Verse 30
فَلَمَّا سَمِعَتۡ بِمَكۡرِهِنَّ أَرۡسَلَتۡ إِلَيۡهِنَّ وَأَعۡتَدَتۡ لَهُنَّ مُتَّكَـٔٗا وَءَاتَتۡ كُلَّ وَٰحِدَةٖ مِّنۡهُنَّ سِكِّينٗا وَقَالَتِ ٱخۡرُجۡ عَلَيۡهِنَّۖ فَلَمَّا رَأَيۡنَهُۥٓ أَكۡبَرۡنَهُۥ وَقَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّ وَقُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا هَٰذَا بَشَرًا إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا مَلَكٞ كَرِيمٞ
Nigba ti (ayaba) gbo ete (oro) won (ti won n so nipa re), o ranse si won. O si pese ohun jije ajokooje sile fun won. O fun ikookan won ni obe (ti o maa fi jeun). O si so pe: “Jade si won, (Yusuf).” Nigba ti won ri i, won gbe e tobi (fun ewa ara re). Won si rera won lowo (fun iyanu ewa ara re). Won si wi pe: “Mimo ni fun Allahu! Eyi ki i se abara. Ki ni eyi bi ko se molaika alapon-onle.”
Surah Yusuf, Verse 31
قَالَتۡ فَذَٰلِكُنَّ ٱلَّذِي لُمۡتُنَّنِي فِيهِۖ وَلَقَدۡ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ فَٱسۡتَعۡصَمَۖ وَلَئِن لَّمۡ يَفۡعَلۡ مَآ ءَامُرُهُۥ لَيُسۡجَنَنَّ وَلَيَكُونٗا مِّنَ ٱلصَّـٰغِرِينَ
(Ayaba) so pe: “Iyen ni eni ti e bu mi fun. Dajudaju mo jireebe fun ere ife lodo re, o si wa isora. Dajudaju ti ko ba se ohun ti mo n pa lase fun un, won kuku maa fi sinu ogba ewon ni. Dajudaju o si maa wa ninu awon eni yepere.”
Surah Yusuf, Verse 32
قَالَ رَبِّ ٱلسِّجۡنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِۖ وَإِلَّا تَصۡرِفۡ عَنِّي كَيۡدَهُنَّ أَصۡبُ إِلَيۡهِنَّ وَأَكُن مِّنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ
(Yusuf) so pe: “Oluwa (Eledaa) mi, ogba ewon ni mo nifee si ju ohun ti won n pe mi si. Ti O o ba si seri ete won kuro lodo mi, emi yoo ko sinu ete won, emi yo si wa lara awon alaimokan.”
Surah Yusuf, Verse 33
فَٱسۡتَجَابَ لَهُۥ رَبُّهُۥ فَصَرَفَ عَنۡهُ كَيۡدَهُنَّۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Nitori naa, Oluwa re jepe re. O si seri ete won kuro lodo re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo
Surah Yusuf, Verse 34
ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا رَأَوُاْ ٱلۡأٓيَٰتِ لَيَسۡجُنُنَّهُۥ حَتَّىٰ حِينٖ
Leyin igba ti won ti ri awon ami (pe Yusuf ko jebi esun), leyin naa, o han si won pe awon gbodo so o sinu ogba ewon titi di asiko kan na
Surah Yusuf, Verse 35
وَدَخَلَ مَعَهُ ٱلسِّجۡنَ فَتَيَانِۖ قَالَ أَحَدُهُمَآ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَعۡصِرُ خَمۡرٗاۖ وَقَالَ ٱلۡأٓخَرُ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَحۡمِلُ فَوۡقَ رَأۡسِي خُبۡزٗا تَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِنۡهُۖ نَبِّئۡنَا بِتَأۡوِيلِهِۦٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Awon odokunrin meji kan wo inu ogba ewon pelu re. Okan ninu awon mejeeji so pe: “Emi lalaa ri ara mi pe mo n fun oti.” Eni keji so pe: “Dajudaju emi lalaa ri ara mi pe mo gbe buredi ru sori mi, eye si n je ninu re.” So itumo re fun wa. Dajudaju awa n ri o pe o wa ninu awon eni rere
Surah Yusuf, Verse 36
قَالَ لَا يَأۡتِيكُمَا طَعَامٞ تُرۡزَقَانِهِۦٓ إِلَّا نَبَّأۡتُكُمَا بِتَأۡوِيلِهِۦ قَبۡلَ أَن يَأۡتِيَكُمَاۚ ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِي رَبِّيٓۚ إِنِّي تَرَكۡتُ مِلَّةَ قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ
O so pe: "Ounje ti won n pese fun yin ko ni ti i de ba yin, afi ki emi ti so itumo re fun eyin mejeeji siwaju ki o to de ba yin. Iyen wa ninu nnkan ti Oluwa mi fi mo mi. Dajudaju emi fi esin awon eniyan ti ko gbagbo ninu Allahu sile. Awon si ni alaigbagbo ninu Ojo Ikeyin
Surah Yusuf, Verse 37
وَٱتَّبَعۡتُ مِلَّةَ ءَابَآءِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۚ مَا كَانَ لَنَآ أَن نُّشۡرِكَ بِٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۚ ذَٰلِكَ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ عَلَيۡنَا وَعَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ
Mo si tele esin awon baba mi, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub. Ko to si wa pe ki a so nnkan kan di akegbe fun Allahu. Iyen wa ninu oore ajulo Allahu lori awa ati lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Allahu)
Surah Yusuf, Verse 38
يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ ءَأَرۡبَابٞ مُّتَفَرِّقُونَ خَيۡرٌ أَمِ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ
Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, se awon oluwa otooto l’o loore julo (lati josin fun) tabi Allahu, Okan soso, Olubori
Surah Yusuf, Verse 39
مَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ أَسۡمَآءٗ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِ أَمَرَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Ko si ohun kan ti e n josin fun leyin Re bi ko se awon oruko kan ti e so won - eyin ati awon baba yin - Allahu ko so eri kan kale fun un. Idajo (ta ni ijosin to si) ko si fun eni kan afi Allahu. O si ti pase pe e ma josin fun kini kan afi Oun nikan. Iyen ni esin t’o fese rinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
Surah Yusuf, Verse 40
يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ أَمَّآ أَحَدُكُمَا فَيَسۡقِي رَبَّهُۥ خَمۡرٗاۖ وَأَمَّا ٱلۡأٓخَرُ فَيُصۡلَبُ فَتَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِن رَّأۡسِهِۦۚ قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ ٱلَّذِي فِيهِ تَسۡتَفۡتِيَانِ
Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, ni ti eni kan ninu yin, o maa fun oga re ni oti mu. Ni ti eni keji, won yoo kan an mo igi, eye yo si maa je ninu ori re. Won ti pari oro ti eyin mejeeji n se ibeere nipa re
Surah Yusuf, Verse 41
وَقَالَ لِلَّذِي ظَنَّ أَنَّهُۥ نَاجٖ مِّنۡهُمَا ٱذۡكُرۡنِي عِندَ رَبِّكَ فَأَنسَىٰهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ ذِكۡرَ رَبِّهِۦ فَلَبِثَ فِي ٱلسِّجۡنِ بِضۡعَ سِنِينَ
O si so fun eni ti o ro pe o maa la ninu awon mejeeji pe: “Ranti mi lodo oga re.” Esu si mu (Yusuf) gbagbe iranti Oluwa re (nipa wiwa iranlowo sodo oga re). Nitori naa, o wa ninu ogba ewon fun awon odun die
Surah Yusuf, Verse 42
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ إِنِّيٓ أَرَىٰ سَبۡعَ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعَ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖۖ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ أَفۡتُونِي فِي رُءۡيَٰيَ إِن كُنتُمۡ لِلرُّءۡيَا تَعۡبُرُونَ
Oba so pe: “Dajudaju emi lalaa ri maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. (Mo tun lalaa ri) siri meje tutu ati omiran gbigbe. Eyin ijoye, e fun mi ni alaye itumo ala mi ti e ba je eni t’o maa n tumo ala.”
Surah Yusuf, Verse 43
قَالُوٓاْ أَضۡغَٰثُ أَحۡلَٰمٖۖ وَمَا نَحۡنُ بِتَأۡوِيلِ ٱلۡأَحۡلَٰمِ بِعَٰلِمِينَ
Won so pe: “Awon ala t’o lopo mora won (niyi). Ati pe awa ki i se onimo nipa itumo awon ala.”
Surah Yusuf, Verse 44
وَقَالَ ٱلَّذِي نَجَا مِنۡهُمَا وَٱدَّكَرَ بَعۡدَ أُمَّةٍ أَنَا۠ أُنَبِّئُكُم بِتَأۡوِيلِهِۦ فَأَرۡسِلُونِ
Eni ti o la ninu awon (elewon) mejeeji so pe, - o ranti (Yusuf) leyin igba pipe -: “Emi yoo fun yin ni iro nipa itumo re. Nitori naa, e fi ise ran mi na (ki ng lo se iwadii re).”
Surah Yusuf, Verse 45
يُوسُفُ أَيُّهَا ٱلصِّدِّيقُ أَفۡتِنَا فِي سَبۡعِ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعِ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖ لَّعَلِّيٓ أَرۡجِعُ إِلَى ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَعۡلَمُونَ
Yusuf, iwo olododo, fun wa ni alaye itumo ala (yii): maalu meje t’o sanra. Awon maalu meje t’o ru si n je won. Ati siri meje tutu ati omiran gbigbe. (Ki ni itumo re) nitori ki ng le fi abo sodo awon eniyan ati nitori ki won le mo (itumo re)
Surah Yusuf, Verse 46
قَالَ تَزۡرَعُونَ سَبۡعَ سِنِينَ دَأَبٗا فَمَا حَصَدتُّمۡ فَذَرُوهُ فِي سُنۢبُلِهِۦٓ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تَأۡكُلُونَ
O so pe: “Eyin yoo gbin nnkan ogbin fun odun meje gbako (gege bi) ise (yin). Ohunkohun ti e ba ko lere oko, ki e fi sile sinu siri re afi die ti e maa je ninu re
Surah Yusuf, Verse 47
ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ سَبۡعٞ شِدَادٞ يَأۡكُلۡنَ مَا قَدَّمۡتُمۡ لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تُحۡصِنُونَ
Leyin naa, odun meje t’o le (fun oda ojo) yoo de leyin iyen, (awon ara ilu) yo si le je ohun ti e ti (ko lere oko) siwaju afi die ti e maa fi pamo (fun gbigbin)
Surah Yusuf, Verse 48
ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ عَامٞ فِيهِ يُغَاثُ ٱلنَّاسُ وَفِيهِ يَعۡصِرُونَ
Leyin naa, odun kan ti Won yoo rojo fun awon eniyan yoo de leyin iyen. Awon eniyan yo si maa fun eso ati wara mu ninu odun naa
Surah Yusuf, Verse 49
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦۖ فَلَمَّا جَآءَهُ ٱلرَّسُولُ قَالَ ٱرۡجِعۡ إِلَىٰ رَبِّكَ فَسۡـَٔلۡهُ مَا بَالُ ٱلنِّسۡوَةِ ٱلَّـٰتِي قَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّۚ إِنَّ رَبِّي بِكَيۡدِهِنَّ عَلِيمٞ
Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi.” Nigba ti iranse naa de odo re. (Yusuf) so pe: “Pada sodo oga re, ki o bi i leere pe, ki ni o sele si awon obinrin ti won re owo ara won. Dajudaju Oluwa mi ni Onimo nipa ete won.”
Surah Yusuf, Verse 50
قَالَ مَا خَطۡبُكُنَّ إِذۡ رَٰوَدتُّنَّ يُوسُفَ عَن نَّفۡسِهِۦۚ قُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا عَلِمۡنَا عَلَيۡهِ مِن سُوٓءٖۚ قَالَتِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡـَٰٔنَ حَصۡحَصَ ٱلۡحَقُّ أَنَا۠ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّـٰدِقِينَ
(Oba) so pe: "Ki ni oro tiyin ti je ti e fi jireebe fun ere ife lodo Yusuf?" Won so pe: “Mimo ni fun Allahu. awa ko mo aburu kan mo Yusuf.” Ayaba so pe: “Nisinsin yii ni ododo foju han. Emi ni mo jireebe fun ere ife lodo re. Dajudaju o wa ninu awon olododo.”
Surah Yusuf, Verse 51
ذَٰلِكَ لِيَعۡلَمَ أَنِّي لَمۡ أَخُنۡهُ بِٱلۡغَيۡبِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي كَيۡدَ ٱلۡخَآئِنِينَ
(Yusuf so pe): "Iyen nitori ki oba le mo pe dajudaju emi ko janba re ni ikoko. Ati pe dajudaju Allahu ko nii fi imona sibi ete awon onijanba
Surah Yusuf, Verse 52
۞وَمَآ أُبَرِّئُ نَفۡسِيٓۚ إِنَّ ٱلنَّفۡسَ لَأَمَّارَةُۢ بِٱلسُّوٓءِ إِلَّا مَا رَحِمَ رَبِّيٓۚ إِنَّ رَبِّي غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Emi ko si fora mi mo (nibi erokero); dajudaju emi kuku n pase erokero (fun eda) ni afi eni ti Oluwa mi ba ke. Dajudaju Oluwa mi ni Alaforijin, Asake-orun
Surah Yusuf, Verse 53
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦٓ أَسۡتَخۡلِصۡهُ لِنَفۡسِيۖ فَلَمَّا كَلَّمَهُۥ قَالَ إِنَّكَ ٱلۡيَوۡمَ لَدَيۡنَا مَكِينٌ أَمِينٞ
Oba so pe: “E mu (Yusuf) wa fun mi. Emi yoo se e ni eni esa lodo mi.” Nigba ti oba ba a soro tan, o so pe: “Lodo wa ni oni dajudaju iwo ni eni pataki, olufokantan.”
Surah Yusuf, Verse 54
قَالَ ٱجۡعَلۡنِي عَلَىٰ خَزَآئِنِ ٱلۡأَرۡضِۖ إِنِّي حَفِيظٌ عَلِيمٞ
(Yusuf) so pe: “Fi mi se alase awon oro ilu, dajudaju alamojuuto onimo ni mi.”
Surah Yusuf, Verse 55
وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَتَبَوَّأُ مِنۡهَا حَيۡثُ يَشَآءُۚ نُصِيبُ بِرَحۡمَتِنَا مَن نَّشَآءُۖ وَلَا نُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Bayen ni A se fun Yusuf ni ipo ati ibugbe lori ile. O si n gbe ni ibi ti o ba fe. Awa n mu ike Wa ba enikeni ti A ba fe. A o si nii fi esan awon oluse-rere rare
Surah Yusuf, Verse 56
وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ
Dajudaju esan ti orun loore julo fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si n beru (Allahu)
Surah Yusuf, Verse 57
وَجَآءَ إِخۡوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَعَرَفَهُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ مُنكِرُونَ
Awon obakan (Anabi) Yusuf de, won si wole to o. O da won mo. Awon ko si mo on mo
Surah Yusuf, Verse 58
وَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ قَالَ ٱئۡتُونِي بِأَخٖ لَّكُم مِّنۡ أَبِيكُمۡۚ أَلَا تَرَوۡنَ أَنِّيٓ أُوفِي ٱلۡكَيۡلَ وَأَنَا۠ خَيۡرُ ٱلۡمُنزِلِينَ
Nigba ti o si ba won di eru ounje won tan, o so pe: "E lo mu obakan yin wa lati odo baba yin. Se e ko ri i pe dajudaju mo n won kongo ni ekun rere ni? Emi si dara julo ninu awon olugbalejo
Surah Yusuf, Verse 59
فَإِن لَّمۡ تَأۡتُونِي بِهِۦ فَلَا كَيۡلَ لَكُمۡ عِندِي وَلَا تَقۡرَبُونِ
Ti e o ba si mu un wa, ko si (eru ounje) wiwon fun yin lodo mi. Ki e si ma se sunmo mi
Surah Yusuf, Verse 60
قَالُواْ سَنُرَٰوِدُ عَنۡهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَٰعِلُونَ
Won so pe: “A maa jireebe fun un lodo baba re. Dajudaju awa maa se bee.”
Surah Yusuf, Verse 61
وَقَالَ لِفِتۡيَٰنِهِ ٱجۡعَلُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ فِي رِحَالِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَعۡرِفُونَهَآ إِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
O si so fun awon omo odo re pe: “E fi owo-oja won sinu eru (ounje) won nitori ki won le mo nigba ti won ba pada de odo ara ile won (pe a ti da a pada fun won), won yo si le pada wa.”
Surah Yusuf, Verse 62
فَلَمَّا رَجَعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَبِيهِمۡ قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا مُنِعَ مِنَّا ٱلۡكَيۡلُ فَأَرۡسِلۡ مَعَنَآ أَخَانَا نَكۡتَلۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Nigba ti won pada de odo baba won, won so pe: “Baba wa, won ko lati won ounje fun wa. Nitori naa, je ki obakan wa ba wa lo nitori ki a le ri ounje won (wale). Dajudaju awa ni oluso fun un.”
Surah Yusuf, Verse 63
قَالَ هَلۡ ءَامَنُكُمۡ عَلَيۡهِ إِلَّا كَمَآ أَمِنتُكُمۡ عَلَىٰٓ أَخِيهِ مِن قَبۡلُ فَٱللَّهُ خَيۡرٌ حَٰفِظٗاۖ وَهُوَ أَرۡحَمُ ٱلرَّـٰحِمِينَ
O so pe: “Se ki ng gba yin gbo lori re bi ko se bi mo se gba yin gbo ni isaaju lori omo-iya re? Nitori naa, Allahu loore julo ni Oluso. Oun si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu.”
Surah Yusuf, Verse 64
وَلَمَّا فَتَحُواْ مَتَٰعَهُمۡ وَجَدُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ رُدَّتۡ إِلَيۡهِمۡۖ قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا مَا نَبۡغِيۖ هَٰذِهِۦ بِضَٰعَتُنَا رُدَّتۡ إِلَيۡنَاۖ وَنَمِيرُ أَهۡلَنَا وَنَحۡفَظُ أَخَانَا وَنَزۡدَادُ كَيۡلَ بَعِيرٖۖ ذَٰلِكَ كَيۡلٞ يَسِيرٞ
Nigba ti won tu eru ounje won, won ri owo-oja won ti won da pada fun won (ninu re). Won so pe: “Baba wa, ki ni a tun n fe? Owo-oja wa niyi ti won ti da pada fun wa. A o si tun fi wa ounje ra fun awon ebi wa. A o si daabo bo obakan wa. A si maa ri alekun eru ounje (ti) rakunmi kan le ru si i. Iwon ounje kekere si niyen (lodo oba).”
Surah Yusuf, Verse 65
قَالَ لَنۡ أُرۡسِلَهُۥ مَعَكُمۡ حَتَّىٰ تُؤۡتُونِ مَوۡثِقٗا مِّنَ ٱللَّهِ لَتَأۡتُنَّنِي بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يُحَاطَ بِكُمۡۖ فَلَمَّآ ءَاتَوۡهُ مَوۡثِقَهُمۡ قَالَ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٞ
O so pe: “Emi ko nii je ki o ba yin lo titi e maa fi se adehun fun mi ni (oruko) Allahu pe dajudaju e maa mu un pada wa ba mi afi ti (awon ota) ba ka yin mo.” Nigba ti won fun un ni adehun won tan, o so pe: “Allahu ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”
Surah Yusuf, Verse 66
وَقَالَ يَٰبَنِيَّ لَا تَدۡخُلُواْ مِنۢ بَابٖ وَٰحِدٖ وَٱدۡخُلُواْ مِنۡ أَبۡوَٰبٖ مُّتَفَرِّقَةٖۖ وَمَآ أُغۡنِي عَنكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٍۖ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِۖ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُۖ وَعَلَيۡهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُتَوَكِّلُونَ
O tun so pe: “Eyin omo mi, e ma se gba enu ona eyo kan wole. E gba enu ona otooto wole. Emi ko le fi nnkan kan ro yin loro lodo Allahu. Ko si idajo (fun eni kan) afi fun Allahu. Oun ni mo gbarale. Oun si ni ki awon olugbarale gbarale.”
Surah Yusuf, Verse 67
وَلَمَّا دَخَلُواْ مِنۡ حَيۡثُ أَمَرَهُمۡ أَبُوهُم مَّا كَانَ يُغۡنِي عَنۡهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٍ إِلَّا حَاجَةٗ فِي نَفۡسِ يَعۡقُوبَ قَضَىٰهَاۚ وَإِنَّهُۥ لَذُو عِلۡمٖ لِّمَا عَلَّمۡنَٰهُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Nigba ti won wo (inu ilu) ni awon aye ti baba won pa lase fun won, ko si ro won loro kan kan lodo Allahu bi ko se bukata kan ninu emi (Anabi) Ya‘ƙub ti o muse. Dajudaju onimo ni nipa ohun ti A fi mo on, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
Surah Yusuf, Verse 68
وَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيۡهِ أَخَاهُۖ قَالَ إِنِّيٓ أَنَا۠ أَخُوكَ فَلَا تَبۡتَئِسۡ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Nigba ti won wole ti (Anabi) Yusuf, o mu omo-iya re mora sodo re. O so pe: “Dajudaju emi ni omo-iya re. Nitori naa, ma se banuje nipa ohun ti won n se nise.”
Surah Yusuf, Verse 69
فَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ جَعَلَ ٱلسِّقَايَةَ فِي رَحۡلِ أَخِيهِ ثُمَّ أَذَّنَ مُؤَذِّنٌ أَيَّتُهَا ٱلۡعِيرُ إِنَّكُمۡ لَسَٰرِقُونَ
Nigba ti o si ba won di eru won tan, o fi ife-imumi sinu eru omo-iya re. Leyin naa, olupepe kan kede pe: “Eyin ero-rakunmi, dajudaju eyin ni ole.”
Surah Yusuf, Verse 70
قَالُواْ وَأَقۡبَلُواْ عَلَيۡهِم مَّاذَا تَفۡقِدُونَ
Won doju ko won, won so pe: “Ki l’e safeku?”
Surah Yusuf, Verse 71
قَالُواْ نَفۡقِدُ صُوَاعَ ٱلۡمَلِكِ وَلِمَن جَآءَ بِهِۦ حِمۡلُ بَعِيرٖ وَأَنَا۠ بِهِۦ زَعِيمٞ
Won so pe: “A o ri ife oba ni. Eni ti o ba si mu un wa yoo ri eru ounje rakunmi kan gba. Emi si ni oniduroo fun ebun naa.”
Surah Yusuf, Verse 72
قَالُواْ تَٱللَّهِ لَقَدۡ عَلِمۡتُم مَّا جِئۡنَا لِنُفۡسِدَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كُنَّا سَٰرِقِينَ
Won so pe: “A fi Allahu bura, dajudaju e mo pe a ko wa lati sebaje lori ile. Ati pe awa ki i se ole.”
Surah Yusuf, Verse 73
قَالُواْ فَمَا جَزَـٰٓؤُهُۥٓ إِن كُنتُمۡ كَٰذِبِينَ
Won so pe: “Ki ni esan (fun eni ti) o ji i, ti (o ba han pe) eyin je opuro?”
Surah Yusuf, Verse 74
قَالُواْ جَزَـٰٓؤُهُۥ مَن وُجِدَ فِي رَحۡلِهِۦ فَهُوَ جَزَـٰٓؤُهُۥۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلظَّـٰلِمِينَ
Won so pe: “Esan re; eni ti won ba ba a ninu eru re, oun naa ni esan re. Bayen ni awa naa se n san awon alabosi ni esan.”
Surah Yusuf, Verse 75
فَبَدَأَ بِأَوۡعِيَتِهِمۡ قَبۡلَ وِعَآءِ أَخِيهِ ثُمَّ ٱسۡتَخۡرَجَهَا مِن وِعَآءِ أَخِيهِۚ كَذَٰلِكَ كِدۡنَا لِيُوسُفَۖ مَا كَانَ لِيَأۡخُذَ أَخَاهُ فِي دِينِ ٱلۡمَلِكِ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ نَرۡفَعُ دَرَجَٰتٖ مَّن نَّشَآءُۗ وَفَوۡقَ كُلِّ ذِي عِلۡمٍ عَلِيمٞ
O si bere (ayewo) apo won siwaju apo omo-iya re. Leyin naa, o mu un jade lati inu apo omo-iya re. Bayen ni A se fun (Anabi) Yusuf ni ete da. Ko le fi ofin oba mu omo-iya re afi ti Allahu ba fe. A n sagbega fun enikeni ti A ba fe. Onimo wa loke gbogbo onimo
Surah Yusuf, Verse 76
۞قَالُوٓاْ إِن يَسۡرِقۡ فَقَدۡ سَرَقَ أَخٞ لَّهُۥ مِن قَبۡلُۚ فَأَسَرَّهَا يُوسُفُ فِي نَفۡسِهِۦ وَلَمۡ يُبۡدِهَا لَهُمۡۚ قَالَ أَنتُمۡ شَرّٞ مَّكَانٗاۖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا تَصِفُونَ
Won so pe: “Ti o ba jale, dajudaju omo-iya re kan ti jale siwaju.” (Anabi) Yusuf si fi oro naa pamo sinu emi re, ko si fi han si won pe (ko ri bee). O (si) so pe: “Ipo tiyin l’o buru julo. Allahu l’O si nimo julo nipa ohun ti e n so.”
Surah Yusuf, Verse 77
قَالُواْ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡعَزِيزُ إِنَّ لَهُۥٓ أَبٗا شَيۡخٗا كَبِيرٗا فَخُذۡ أَحَدَنَا مَكَانَهُۥٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Won so pe: "Iwo oba, dajudaju o ni baba arugbo agbalagba kan. Nitori naa, mu eni kan ninu wa dipo re. Dajudaju awa n ri iwo pe o wa ninu awon eni-rere
Surah Yusuf, Verse 78
قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِ أَن نَّأۡخُذَ إِلَّا مَن وَجَدۡنَا مَتَٰعَنَا عِندَهُۥٓ إِنَّآ إِذٗا لَّظَٰلِمُونَ
O so pe: “Mo sadi Allahu pe ki a mu eni kan afi eni ti a ba eru wa lodo re. (Ti a ba mu elomiiran) dajudaju nigba naa alabosi ni wa.”
Surah Yusuf, Verse 79
فَلَمَّا ٱسۡتَيۡـَٔسُواْ مِنۡهُ خَلَصُواْ نَجِيّٗاۖ قَالَ كَبِيرُهُمۡ أَلَمۡ تَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ أَبَاكُمۡ قَدۡ أَخَذَ عَلَيۡكُم مَّوۡثِقٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَمِن قَبۡلُ مَا فَرَّطتُمۡ فِي يُوسُفَۖ فَلَنۡ أَبۡرَحَ ٱلۡأَرۡضَ حَتَّىٰ يَأۡذَنَ لِيٓ أَبِيٓ أَوۡ يَحۡكُمَ ٱللَّهُ لِيۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡحَٰكِمِينَ
Nigba ti won soreti nu nipa re, won te soro. Agba (ninu) won so pe: “Se e ko mo pe dajudaju baba yin ti gba adehun yin ti (e se ni oruko) Allahu. Ati pe siwaju (eyi, e ti se) aseeto nipa oro (Anabi) Yusuf. Nitori naa, emi ko nii fi ile (Misro) sile titi baba mi yoo fi yonda fun mi tabi (titi) Allahu yoo fi se idajo fun mi. O si loore julo ninu awon oludajo
Surah Yusuf, Verse 80
ٱرۡجِعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَبِيكُمۡ فَقُولُواْ يَـٰٓأَبَانَآ إِنَّ ٱبۡنَكَ سَرَقَ وَمَا شَهِدۡنَآ إِلَّا بِمَا عَلِمۡنَا وَمَا كُنَّا لِلۡغَيۡبِ حَٰفِظِينَ
E pada sodo baba yin, ki e si so pe: “Baba wa, dajudaju omo re jale. A ko si le jerii (si kini kan) afi ohun ti a ba nimo (nipa) re. Awa ko si je oluso fun ohun ti o pamo (fun wa)
Surah Yusuf, Verse 81
وَسۡـَٔلِ ٱلۡقَرۡيَةَ ٱلَّتِي كُنَّا فِيهَا وَٱلۡعِيرَ ٱلَّتِيٓ أَقۡبَلۡنَا فِيهَاۖ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ
Ki o si bi awon ara ilu ti a wa ninu re ati ero-rakunmi ti a jo dari de leere wo. Dajudaju olododo ma ni wa.”
Surah Yusuf, Verse 82
قَالَ بَلۡ سَوَّلَتۡ لَكُمۡ أَنفُسُكُمۡ أَمۡرٗاۖ فَصَبۡرٞ جَمِيلٌۖ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَأۡتِيَنِي بِهِمۡ جَمِيعًاۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
(Anabi Ya‘ƙub) so pe: “Rara o, emi yin lo se oran kan losoo fun yin. Nitori naa, suuru t’o rewa (loro mi kan bayii). O see se ki Allahu ba mi mu gbogbo won wa. Dajudaju Allahu, Oun ni Onimo, Ologbon.”
Surah Yusuf, Verse 83
وَتَوَلَّىٰ عَنۡهُمۡ وَقَالَ يَـٰٓأَسَفَىٰ عَلَىٰ يُوسُفَ وَٱبۡيَضَّتۡ عَيۡنَاهُ مِنَ ٱلۡحُزۡنِ فَهُوَ كَظِيمٞ
O pa won ti, o si so pe: “Ibanuje n be fun mi lori Yusuf!” Oju re mejeeji si funfun wa (ko si riran mo); o si pa ibanuje mora
Surah Yusuf, Verse 84
قَالُواْ تَٱللَّهِ تَفۡتَؤُاْ تَذۡكُرُ يُوسُفَ حَتَّىٰ تَكُونَ حَرَضًا أَوۡ تَكُونَ مِنَ ٱلۡهَٰلِكِينَ
Won so pe: “A fi Allahu bura, iwo ko ye ranti Yusuf titi o maa fi di yannayanna tabi (titi) o maa fi di ara awon oku.”
Surah Yusuf, Verse 85
قَالَ إِنَّمَآ أَشۡكُواْ بَثِّي وَحُزۡنِيٓ إِلَى ٱللَّهِ وَأَعۡلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
O so pe: “Allahu ma ni emi n ro edun okan mi ati ibanuje mi fun. Mo si mo ohun ti e ko mo nipa Allahu
Surah Yusuf, Verse 86
يَٰبَنِيَّ ٱذۡهَبُواْ فَتَحَسَّسُواْ مِن يُوسُفَ وَأَخِيهِ وَلَا تَاْيۡـَٔسُواْ مِن رَّوۡحِ ٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ لَا يَاْيۡـَٔسُ مِن رَّوۡحِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Eyin omo mi, e lo wadii nipa Yusuf ati omo-iya re. E si ma se soreti nu ninu ike Allahu. Dajudaju ko si eni kan ti o maa soreti nu ninu ike Allahu afi ijo alaigbagbo.”
Surah Yusuf, Verse 87
فَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَيۡهِ قَالُواْ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡعَزِيزُ مَسَّنَا وَأَهۡلَنَا ٱلضُّرُّ وَجِئۡنَا بِبِضَٰعَةٖ مُّزۡجَىٰةٖ فَأَوۡفِ لَنَا ٱلۡكَيۡلَ وَتَصَدَّقۡ عَلَيۡنَآۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَجۡزِي ٱلۡمُتَصَدِّقِينَ
Nigba ti won wole to Yusuf, won so pe: “Iwo oba, inira ti mu awa ati ara ile wa. A si mu owo kan ti ko yanju wa. Nitori naa, won kongo (ounje) naa kun fun wa, ki o si ta wa lore. Dajudaju Allahu yoo san awon olutore ni esan rere.”
Surah Yusuf, Verse 88
قَالَ هَلۡ عَلِمۡتُم مَّا فَعَلۡتُم بِيُوسُفَ وَأَخِيهِ إِذۡ أَنتُمۡ جَٰهِلُونَ
O so pe: “Nje e mo ohun ti e se fun Yusuf ati omo-iya re nigba ti eyin je alaimokan.”
Surah Yusuf, Verse 89
قَالُوٓاْ أَءِنَّكَ لَأَنتَ يُوسُفُۖ قَالَ أَنَا۠ يُوسُفُ وَهَٰذَآ أَخِيۖ قَدۡ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡنَآۖ إِنَّهُۥ مَن يَتَّقِ وَيَصۡبِرۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Won so pe: “Se dajudaju iwo ni Yusuf?” O so pe: “Emi ni Yusuf. Omo-iya mi si niyi. Dajudaju Allahu ti se idera fun wa. Dajudaju enikeni ti o ba beru (Allahu), ti o si se suuru, dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare.”
Surah Yusuf, Verse 90
قَالُواْ تَٱللَّهِ لَقَدۡ ءَاثَرَكَ ٱللَّهُ عَلَيۡنَا وَإِن كُنَّا لَخَٰطِـِٔينَ
Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju Allahu ti gbola fun o ju wa lo. Ati pe dajudaju awa ni alasise.”
Surah Yusuf, Verse 91
قَالَ لَا تَثۡرِيبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡيَوۡمَۖ يَغۡفِرُ ٱللَّهُ لَكُمۡۖ وَهُوَ أَرۡحَمُ ٱلرَّـٰحِمِينَ
O so pe: "Ko si ibawi fun yin ni oni. Allahu yoo forijin yin. Oun si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu
Surah Yusuf, Verse 92
ٱذۡهَبُواْ بِقَمِيصِي هَٰذَا فَأَلۡقُوهُ عَلَىٰ وَجۡهِ أَبِي يَأۡتِ بَصِيرٗا وَأۡتُونِي بِأَهۡلِكُمۡ أَجۡمَعِينَ
E mu ewu mi yii lo, ki e fi le iwaju baba mi, o maa pada di oluriran. Ki e si ko gbogbo ebi yin wa ba mi
Surah Yusuf, Verse 93
وَلَمَّا فَصَلَتِ ٱلۡعِيرُ قَالَ أَبُوهُمۡ إِنِّي لَأَجِدُ رِيحَ يُوسُفَۖ لَوۡلَآ أَن تُفَنِّدُونِ
Nigba ti ero-rakunmi naa si pinya (kuro lodo Anabi Yusuf), baba won so pe: “Dajudaju emi n gbo oorun Yusuf ti e o ba nii so pe mo n jaran.”
Surah Yusuf, Verse 94
قَالُواْ تَٱللَّهِ إِنَّكَ لَفِي ضَلَٰلِكَ ٱلۡقَدِيمِ
Won so pe: “A fi Allahu bura! Dajudaju iwo si wa ninu asise re ti atijo (nipa ife Yusuf).”
Surah Yusuf, Verse 95
فَلَمَّآ أَن جَآءَ ٱلۡبَشِيرُ أَلۡقَىٰهُ عَلَىٰ وَجۡهِهِۦ فَٱرۡتَدَّ بَصِيرٗاۖ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
Nigba ti oniroo-idunnu de, o ju (ewu naa) le e niwaju, o si riran pada. O so pe: “Nje ng ko so fun yin pe dajudaju emi mo ohun ti e ko mo nipa Allahu.”
Surah Yusuf, Verse 96
قَالُواْ يَـٰٓأَبَانَا ٱسۡتَغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَآ إِنَّا كُنَّا خَٰطِـِٔينَ
Won so pe: “Baba wa, toro aforijin ese wa fun wa, dajudaju awa je alasise.”
Surah Yusuf, Verse 97
قَالَ سَوۡفَ أَسۡتَغۡفِرُ لَكُمۡ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
O so pe: “Laipe mo maa toro aforijin fun yin lodo Oluwa mi. Dajudaju Allahu, Oun ni Alaforijin, Asake-orun.”
Surah Yusuf, Verse 98
فَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيۡهِ أَبَوَيۡهِ وَقَالَ ٱدۡخُلُواْ مِصۡرَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ
Nigba ti won wole to (Anabi) Yusuf, o ko awon obi re mejeeji mora sodo re, o si so pe: “E wo ilu Misro ni olufayabale – ti Allahu ba fe.-”
Surah Yusuf, Verse 99
وَرَفَعَ أَبَوَيۡهِ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ وَخَرُّواْ لَهُۥ سُجَّدٗاۖ وَقَالَ يَـٰٓأَبَتِ هَٰذَا تَأۡوِيلُ رُءۡيَٰيَ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَعَلَهَا رَبِّي حَقّٗاۖ وَقَدۡ أَحۡسَنَ بِيٓ إِذۡ أَخۡرَجَنِي مِنَ ٱلسِّجۡنِ وَجَآءَ بِكُم مِّنَ ٱلۡبَدۡوِ مِنۢ بَعۡدِ أَن نَّزَغَ ٱلشَّيۡطَٰنُ بَيۡنِي وَبَيۡنَ إِخۡوَتِيٓۚ إِنَّ رَبِّي لَطِيفٞ لِّمَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
O gbe awon obi re mejeeji sori ite. Won si doju bole fun un ni oluforikanle-kini. O so pe: “Baba mi, eyi ni itumo ala mi (ti mo la) siwaju. Dajudaju Oluwa mi ti so o di ododo. O si se daadaa fun mi nigba ti O mu mi jade kuro ninu ogba ewon. O tun mu yin wa (ba mi) lati inu oko leyin ti Esu ti ba aarin emi ati awon oba-kan mi je. Dajudaju Oluwa mi ni Alaaanu fun ohun ti O ba fe. Dajudaju Allahu, Oun ni Onimo, Ologbon
Surah Yusuf, Verse 100
۞رَبِّ قَدۡ ءَاتَيۡتَنِي مِنَ ٱلۡمُلۡكِ وَعَلَّمۡتَنِي مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَنتَ وَلِيِّۦ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ تَوَفَّنِي مُسۡلِمٗا وَأَلۡحِقۡنِي بِٱلصَّـٰلِحِينَ
Oluwa mi, dajudaju O ti fun mi ni ijoba. O tun fun mi ni imo itumo ala. Olupileda awon sanmo ati ile, Iwo ni Oluranlowo mi ni aye ati ni orun, pa mi sipo musulumi. Ki O si fi mi pelu awon eni rere.”
Surah Yusuf, Verse 101
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۖ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ أَجۡمَعُوٓاْ أَمۡرَهُمۡ وَهُمۡ يَمۡكُرُونَ
Iyen wa ninu iro ikoko ti A fi imisi (re) ranse si o. Ati pe iwo ko si lodo won nigba ti won panu po lori oro won, ti won n dete
Surah Yusuf, Verse 102
وَمَآ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ وَلَوۡ حَرَصۡتَ بِمُؤۡمِنِينَ
Iwo ibaa soju kokoro (igbala won), opolopo eniyan ni ko nii gbagbo
Surah Yusuf, Verse 103
وَمَا تَسۡـَٔلُهُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ
Iwo ko si bi won leere owo-oya kan lori re. Ko si je kini kan bi ko se iranti fun gbogbo eda
Surah Yusuf, Verse 104
وَكَأَيِّن مِّنۡ ءَايَةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ يَمُرُّونَ عَلَيۡهَا وَهُمۡ عَنۡهَا مُعۡرِضُونَ
Ati pe meloo meloo ninu awon ami ti n be ni sanmo ati ni ori ile ti won n re koja lori re, ti won si n gbunri kuro nibe
Surah Yusuf, Verse 105
وَمَا يُؤۡمِنُ أَكۡثَرُهُم بِٱللَّهِ إِلَّا وَهُم مُّشۡرِكُونَ
Opolopo won si ni ko nii gba Allahu gbo ni ododo afi ki won tun maa sebo
Surah Yusuf, Verse 106
أَفَأَمِنُوٓاْ أَن تَأۡتِيَهُمۡ غَٰشِيَةٞ مِّنۡ عَذَابِ ٱللَّهِ أَوۡ تَأۡتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Se won faya bale pe ohun ti n bo eda mole ninu iya Allahu ko le de ba awon ni tabi pe Akoko naa ko le ko le awon lori ni ojiji, ti won ko si nii fura
Surah Yusuf, Verse 107
قُلۡ هَٰذِهِۦ سَبِيلِيٓ أَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۚ عَلَىٰ بَصِيرَةٍ أَنَا۠ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِيۖ وَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
So pe: “Eyi ni oju ona (esin) mi, emi ati awon t’o tele mi si n pepe si (esin) Allahu pelu imo amodaju. Mimo ni fun Allahu. Emi ko si si lara awon osebo.”
Surah Yusuf, Verse 108
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡقُرَىٰٓۗ أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۗ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si ninu awon ara ilu. Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Dajudaju Ile ikeyin loore julo fun awon t’o beru (Allahu). Se e o se laakaye ni
Surah Yusuf, Verse 109
حَتَّىٰٓ إِذَا ٱسۡتَيۡـَٔسَ ٱلرُّسُلُ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ قَدۡ كُذِبُواْ جَآءَهُمۡ نَصۡرُنَا فَنُجِّيَ مَن نَّشَآءُۖ وَلَا يُرَدُّ بَأۡسُنَا عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ
(A ki i je awon eniyan niya) titi di igba ti awon Ojise ba t’o soreti nu (nipa igbagbo won), ti won si mo pe won ti pe awon ni opuro. Aranse Wa yo si de ba won. A si maa gba eni ti A ba fe la. Won ko le da iya Wa pada lori ijo elese
Surah Yusuf, Verse 110
لَقَدۡ كَانَ فِي قَصَصِهِمۡ عِبۡرَةٞ لِّأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِۗ مَا كَانَ حَدِيثٗا يُفۡتَرَىٰ وَلَٰكِن تَصۡدِيقَ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَتَفۡصِيلَ كُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Dajudaju ariwoye wa ninu itan won fun awon onilaakaye. (Al-Ƙur’an) ki i se oro kan ti won n hun, sugbon o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re, o n salaye gbogbo nnkan; o je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo
Surah Yusuf, Verse 111