Surah Ar-Rad Verse 11 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Ar-Radلَهُۥ مُعَقِّبَٰتٞ مِّنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَمِنۡ خَلۡفِهِۦ يَحۡفَظُونَهُۥ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُغَيِّرُ مَا بِقَوۡمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُواْ مَا بِأَنفُسِهِمۡۗ وَإِذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِقَوۡمٖ سُوٓءٗا فَلَا مَرَدَّ لَهُۥۚ وَمَا لَهُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَالٍ
O n be fun eniyan (kookan) awon molaika ti n gbase funra won; won wa niwaju (eniyan) ati leyin re; won n so (ise owo) re pelu ase Allahu. Dajudaju Allahu ko nii se iyipada nnkan t’o n be lodo ijo kan titi won yoo fi yi nnkan t’o n be ninu emi won pada. Nigba ti Allahu ba gbero aburu kan ro ijo kan, ko si eni t’o le da a pada. Ko si si alaabo kan fun won leyin Re