Surah Al-Isra Verse 106 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Israوَقُرۡءَانٗا فَرَقۡنَٰهُ لِتَقۡرَأَهُۥ عَلَى ٱلنَّاسِ عَلَىٰ مُكۡثٖ وَنَزَّلۡنَٰهُ تَنزِيلٗا
Àti pé al-Ƙur’ān, A ṣàlàyé rẹ̀ (fún ọ) nítorí kí o lè ké e fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀. oríṣi ìsọ̀kalẹ̀ méjì l’ó wà fún al-Ƙur’ān. Ìsọ̀kalẹ̀ kìíní ni ìsọ̀kalẹ̀ olódidi láti inú Laohul-Mahfuṭḥ sínú sánmọ̀ ilé ayé. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí l’ó ṣẹlẹ̀ nínú òru Laelatul-ƙọdr. Èyí l’ó jẹyọ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:185 sūrah ad-Dukān; 44:3 àti sūrah al-Ƙọdr’ 97:1. Ìsọ̀kalẹ̀ kejì ni ìsọ̀kalẹ̀ onídíẹ̀díẹ̀ láti inú sánmọ̀ ilé ayé sórí ilẹ̀ ayé. Èyí ṣẹlẹ̀ fún òǹkà ọdún mẹ́tàlélógún. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí ni āyah yìí ń sọ nípa rẹ̀