Surah Maryam - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
كٓهيعٓصٓ
Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. ìyá ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) Òun l’Ó ṣà á lẹ́ṣà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà ìbá tí sọ àwọn òdodo wọ̀nyẹn nípa Mọryam ìyá Jésù. Ṣebí wọ́n kúkú fi ẹnu àbùkù kan Mọryam ẹ̀dá ni àwọn mìíràn tí Allāhu fi sọrí àwọn sūrah ọ̀rọ̀ Rẹ̀. A kúkú rí sūrah Muhammad gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí sūrah Mọryam. Àmọ́ ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó máa sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di olúwa àti olùgbàlà? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun ọmọ? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam ní ẹ̀ṣà ènìyàn àmọ́ tí Allāhu kò ṣe ìyá àti bàbá Ànábì wa bẹ́ẹ̀ tí Allāhu fi sọrí ẹbí Mọryam a kúkú rí sūrah Ƙuraeṣ
Surah Maryam, Verse 1
ذِكۡرُ رَحۡمَتِ رَبِّكَ عَبۡدَهُۥ زَكَرِيَّآ
(Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀, (Ànábì) Zakariyyā
Surah Maryam, Verse 2
إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥ نِدَآءً خَفِيّٗا
(Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀
Surah Maryam, Verse 3
قَالَ رَبِّ إِنِّي وَهَنَ ٱلۡعَظۡمُ مِنِّي وَٱشۡتَعَلَ ٱلرَّأۡسُ شَيۡبٗا وَلَمۡ أَكُنۢ بِدُعَآئِكَ رَبِّ شَقِيّٗا
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi
Surah Maryam, Verse 4
وَإِنِّي خِفۡتُ ٱلۡمَوَٰلِيَ مِن وَرَآءِي وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا فَهَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا
Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan
Surah Maryam, Verse 5
يَرِثُنِي وَيَرِثُ مِنۡ ءَالِ يَعۡقُوبَۖ وَٱجۡعَلۡهُ رَبِّ رَضِيّٗا
(tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi
Surah Maryam, Verse 6
يَٰزَكَرِيَّآ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَٰمٍ ٱسۡمُهُۥ يَحۡيَىٰ لَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ مِن قَبۡلُ سَمِيّٗا
Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A ò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀)
Surah Maryam, Verse 7
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَكَانَتِ ٱمۡرَأَتِي عَاقِرٗا وَقَدۡ بَلَغۡتُ مِنَ ٱلۡكِبَرِ عِتِيّٗا
Ó sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an
Surah Maryam, Verse 8
قَالَ كَذَٰلِكَ قَالَ رَبُّكَ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞ وَقَدۡ خَلَقۡتُكَ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ تَكُ شَيۡـٔٗا
(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”
Surah Maryam, Verse 9
قَالَ رَبِّ ٱجۡعَل لِّيٓ ءَايَةٗۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَٰثَ لَيَالٖ سَوِيّٗا
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi
Surah Maryam, Verse 10
فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ مِنَ ٱلۡمِحۡرَابِ فَأَوۡحَىٰٓ إِلَيۡهِمۡ أَن سَبِّحُواْ بُكۡرَةٗ وَعَشِيّٗا
Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́
Surah Maryam, Verse 11
يَٰيَحۡيَىٰ خُذِ ٱلۡكِتَٰبَ بِقُوَّةٖۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡحُكۡمَ صَبِيّٗا
Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré
Surah Maryam, Verse 12
وَحَنَانٗا مِّن لَّدُنَّا وَزَكَوٰةٗۖ وَكَانَ تَقِيّٗا
(Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu)
Surah Maryam, Verse 13
وَبَرَّۢا بِوَٰلِدَيۡهِ وَلَمۡ يَكُن جَبَّارًا عَصِيّٗا
(Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa
Surah Maryam, Verse 14
وَسَلَٰمٌ عَلَيۡهِ يَوۡمَ وُلِدَ وَيَوۡمَ يَمُوتُ وَيَوۡمَ يُبۡعَثُ حَيّٗا
Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)
Surah Maryam, Verse 15
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَرۡيَمَ إِذِ ٱنتَبَذَتۡ مِنۡ أَهۡلِهَا مَكَانٗا شَرۡقِيّٗا
Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn
Surah Maryam, Verse 16
فَٱتَّخَذَتۡ مِن دُونِهِمۡ حِجَابٗا فَأَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهَا رُوحَنَا فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرٗا سَوِيّٗا
Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé
Surah Maryam, Verse 17
قَالَتۡ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ مِنكَ إِن كُنتَ تَقِيّٗا
(Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”
Surah Maryam, Verse 18
قَالَ إِنَّمَآ أَنَا۠ رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَٰمٗا زَكِيّٗا
(Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”
Surah Maryam, Verse 19
قَالَتۡ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞ وَلَمۡ أَكُ بَغِيّٗا
Ó sọ pé: "Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè
Surah Maryam, Verse 20
قَالَ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞۖ وَلِنَجۡعَلَهُۥٓ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِ وَرَحۡمَةٗ مِّنَّاۚ وَكَانَ أَمۡرٗا مَّقۡضِيّٗا
(Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn l’ó máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí.”
Surah Maryam, Verse 21
۞فَحَمَلَتۡهُ فَٱنتَبَذَتۡ بِهِۦ مَكَانٗا قَصِيّٗا
Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan t’ó jìnnà
Surah Maryam, Verse 22
فَأَجَآءَهَا ٱلۡمَخَاضُ إِلَىٰ جِذۡعِ ٱلنَّخۡلَةِ قَالَتۡ يَٰلَيۡتَنِي مِتُّ قَبۡلَ هَٰذَا وَكُنتُ نَسۡيٗا مَّنسِيّٗا
Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”
Surah Maryam, Verse 23
فَنَادَىٰهَا مِن تَحۡتِهَآ أَلَّا تَحۡزَنِي قَدۡ جَعَلَ رَبُّكِ تَحۡتَكِ سَرِيّٗا
Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ
Surah Maryam, Verse 24
وَهُزِّيٓ إِلَيۡكِ بِجِذۡعِ ٱلنَّخۡلَةِ تُسَٰقِطۡ عَلَيۡكِ رُطَبٗا جَنِيّٗا
Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ
Surah Maryam, Verse 25
فَكُلِي وَٱشۡرَبِي وَقَرِّي عَيۡنٗاۖ فَإِمَّا تَرَيِنَّ مِنَ ٱلۡبَشَرِ أَحَدٗا فَقُولِيٓ إِنِّي نَذَرۡتُ لِلرَّحۡمَٰنِ صَوۡمٗا فَلَنۡ أُكَلِّمَ ٱلۡيَوۡمَ إِنسِيّٗا
Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: "Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, mi ò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní
Surah Maryam, Verse 26
فَأَتَتۡ بِهِۦ قَوۡمَهَا تَحۡمِلُهُۥۖ قَالُواْ يَٰمَرۡيَمُ لَقَدۡ جِئۡتِ شَيۡـٔٗا فَرِيّٗا
Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: "Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá
Surah Maryam, Verse 27
يَـٰٓأُخۡتَ هَٰرُونَ مَا كَانَ أَبُوكِ ٱمۡرَأَ سَوۡءٖ وَمَا كَانَتۡ أُمُّكِ بَغِيّٗا
Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè
Surah Maryam, Verse 28
فَأَشَارَتۡ إِلَيۡهِۖ قَالُواْ كَيۡفَ نُكَلِّمُ مَن كَانَ فِي ٱلۡمَهۡدِ صَبِيّٗا
Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni t’ó wà lórí ìtẹ́, t’ó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”
Surah Maryam, Verse 29
قَالَ إِنِّي عَبۡدُ ٱللَّهِ ءَاتَىٰنِيَ ٱلۡكِتَٰبَ وَجَعَلَنِي نَبِيّٗا
(Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: "Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ni Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn t’ó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà pẹ̀lú ẹ̀mí mi pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn
Surah Maryam, Verse 30
وَجَعَلَنِي مُبَارَكًا أَيۡنَ مَا كُنتُ وَأَوۡصَٰنِي بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱلزَّكَوٰةِ مَا دُمۡتُ حَيّٗا
Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé)
Surah Maryam, Verse 31
وَبَرَّۢا بِوَٰلِدَتِي وَلَمۡ يَجۡعَلۡنِي جَبَّارٗا شَقِيّٗا
(Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú
Surah Maryam, Verse 32
وَٱلسَّلَٰمُ عَلَيَّ يَوۡمَ وُلِدتُّ وَيَوۡمَ أَمُوتُ وَيَوۡمَ أُبۡعَثُ حَيّٗا
Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)
Surah Maryam, Verse 33
ذَٰلِكَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَۖ قَوۡلَ ٱلۡحَقِّ ٱلَّذِي فِيهِ يَمۡتَرُونَ
Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasara) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀
Surah Maryam, Verse 34
مَا كَانَ لِلَّهِ أَن يَتَّخِذَ مِن وَلَدٖۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓۚ إِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀
Surah Maryam, Verse 35
وَإِنَّ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà
Surah Maryam, Verse 36
فَٱخۡتَلَفَ ٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَيۡنِهِمۡۖ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن مَّشۡهَدِ يَوۡمٍ عَظِيمٍ
Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasara) sì yapa ẹnu (sí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba lọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde)
Surah Maryam, Verse 37
أَسۡمِعۡ بِهِمۡ وَأَبۡصِرۡ يَوۡمَ يَأۡتُونَنَا لَٰكِنِ ٱلظَّـٰلِمُونَ ٱلۡيَوۡمَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa! Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
Surah Maryam, Verse 38
وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡحَسۡرَةِ إِذۡ قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ وَهُمۡ فِي غَفۡلَةٖ وَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́
Surah Maryam, Verse 39
إِنَّا نَحۡنُ نَرِثُ ٱلۡأَرۡضَ وَمَنۡ عَلَيۡهَا وَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ
Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Maryam, Verse 40
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِبۡرَٰهِيمَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صِدِّيقٗا نَّبِيًّا
Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì
Surah Maryam, Verse 41
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ يَـٰٓأَبَتِ لِمَ تَعۡبُدُ مَا لَا يَسۡمَعُ وَلَا يُبۡصِرُ وَلَا يُغۡنِي عَنكَ شَيۡـٔٗا
Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan
Surah Maryam, Verse 42
يَـٰٓأَبَتِ إِنِّي قَدۡ جَآءَنِي مِنَ ٱلۡعِلۡمِ مَا لَمۡ يَأۡتِكَ فَٱتَّبِعۡنِيٓ أَهۡدِكَ صِرَٰطٗا سَوِيّٗا
Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́
Surah Maryam, Verse 43
يَـٰٓأَبَتِ لَا تَعۡبُدِ ٱلشَّيۡطَٰنَۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ عَصِيّٗا
Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé
Surah Maryam, Verse 44
يَـٰٓأَبَتِ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يَمَسَّكَ عَذَابٞ مِّنَ ٱلرَّحۡمَٰنِ فَتَكُونَ لِلشَّيۡطَٰنِ وَلِيّٗا
Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná)
Surah Maryam, Verse 45
قَالَ أَرَاغِبٌ أَنتَ عَنۡ ءَالِهَتِي يَـٰٓإِبۡرَٰهِيمُۖ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ لَأَرۡجُمَنَّكَۖ وَٱهۡجُرۡنِي مَلِيّٗا
(Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná.”
Surah Maryam, Verse 46
قَالَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكَۖ سَأَسۡتَغۡفِرُ لَكَ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ بِي حَفِيّٗا
(’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi
Surah Maryam, Verse 47
وَأَعۡتَزِلُكُمۡ وَمَا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَأَدۡعُواْ رَبِّي عَسَىٰٓ أَلَّآ أَكُونَ بِدُعَآءِ رَبِّي شَقِيّٗا
Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi
Surah Maryam, Verse 48
فَلَمَّا ٱعۡتَزَلَهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۖ وَكُلّٗا جَعَلۡنَا نَبِيّٗا
Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì
Surah Maryam, Verse 49
وَوَهَبۡنَا لَهُم مِّن رَّحۡمَتِنَا وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ لِسَانَ صِدۡقٍ عَلِيّٗا
Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì ní kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa
Surah Maryam, Verse 50
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مُوسَىٰٓۚ إِنَّهُۥ كَانَ مُخۡلَصٗا وَكَانَ رَسُولٗا نَّبِيّٗا
Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì
Surah Maryam, Verse 51
وَنَٰدَيۡنَٰهُ مِن جَانِبِ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنِ وَقَرَّبۡنَٰهُ نَجِيّٗا
A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀
Surah Maryam, Verse 52
وَوَهَبۡنَا لَهُۥ مِن رَّحۡمَتِنَآ أَخَاهُ هَٰرُونَ نَبِيّٗا
Láti inú ìkẹ́ Wa A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ
Surah Maryam, Verse 53
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِسۡمَٰعِيلَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صَادِقَ ٱلۡوَعۡدِ وَكَانَ رَسُولٗا نَّبِيّٗا
Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì
Surah Maryam, Verse 54
وَكَانَ يَأۡمُرُ أَهۡلَهُۥ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱلزَّكَوٰةِ وَكَانَ عِندَ رَبِّهِۦ مَرۡضِيّٗا
Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀
Surah Maryam, Verse 55
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ إِدۡرِيسَۚ إِنَّهُۥ كَانَ صِدِّيقٗا نَّبِيّٗا
Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì
Surah Maryam, Verse 56
وَرَفَعۡنَٰهُ مَكَانًا عَلِيًّا
A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀)
Surah Maryam, Verse 57
أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِن ذُرِّيَّةِ ءَادَمَ وَمِمَّنۡ حَمَلۡنَا مَعَ نُوحٖ وَمِن ذُرِّيَّةِ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡرَـٰٓءِيلَ وَمِمَّنۡ هَدَيۡنَا وَٱجۡتَبَيۡنَآۚ إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُ ٱلرَّحۡمَٰنِ خَرُّواْۤ سُجَّدٗاۤ وَبُكِيّٗا۩
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún
Surah Maryam, Verse 58
۞فَخَلَفَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ خَلۡفٌ أَضَاعُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَٱتَّبَعُواْ ٱلشَّهَوَٰتِۖ فَسَوۡفَ يَلۡقَوۡنَ غَيًّا
Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn yòdòyìndìn ẹ̀mí. Láìpẹ́ wọn máa pàdé ìparun (nínú Iná)
Surah Maryam, Verse 59
إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَأُوْلَـٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ وَلَا يُظۡلَمُونَ شَيۡـٔٗا
Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn
Surah Maryam, Verse 60
جَنَّـٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ عِبَادَهُۥ بِٱلۡغَيۡبِۚ إِنَّهُۥ كَانَ وَعۡدُهُۥ مَأۡتِيّٗا
(Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn sí ìpamọ́ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ
Surah Maryam, Verse 61
لَّا يَسۡمَعُونَ فِيهَا لَغۡوًا إِلَّا سَلَٰمٗاۖ وَلَهُمۡ رِزۡقُهُمۡ فِيهَا بُكۡرَةٗ وَعَشِيّٗا
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́
Surah Maryam, Verse 62
تِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِي نُورِثُ مِنۡ عِبَادِنَا مَن كَانَ تَقِيّٗا
Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa
Surah Maryam, Verse 63
وَمَا نَتَنَزَّلُ إِلَّا بِأَمۡرِ رَبِّكَۖ لَهُۥ مَا بَيۡنَ أَيۡدِينَا وَمَا خَلۡفَنَا وَمَا بَيۡنَ ذَٰلِكَۚ وَمَا كَانَ رَبُّكَ نَسِيّٗا
Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yìí. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbé
Surah Maryam, Verse 64
رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا فَٱعۡبُدۡهُ وَٱصۡطَبِرۡ لِعِبَٰدَتِهِۦۚ هَلۡ تَعۡلَمُ لَهُۥ سَمِيّٗا
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀
Surah Maryam, Verse 65
وَيَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَءِذَا مَا مِتُّ لَسَوۡفَ أُخۡرَجُ حَيًّا
Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, Wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”
Surah Maryam, Verse 66
أَوَلَا يَذۡكُرُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ يَكُ شَيۡـٔٗا
Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan
Surah Maryam, Verse 67
فَوَرَبِّكَ لَنَحۡشُرَنَّهُمۡ وَٱلشَّيَٰطِينَ ثُمَّ لَنُحۡضِرَنَّهُمۡ حَوۡلَ جَهَنَّمَ جِثِيّٗا
Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀
Surah Maryam, Verse 68
ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمۡ أَشَدُّ عَلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ عِتِيّٗا
Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan èyíkéyìí nínú wọn tí ó le jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé
Surah Maryam, Verse 69
ثُمَّ لَنَحۡنُ أَعۡلَمُ بِٱلَّذِينَ هُمۡ أَوۡلَىٰ بِهَا صِلِيّٗا
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó lẹ́tọ̀ọ́ sí wíwọ inú Iná
Surah Maryam, Verse 70
وَإِن مِّنكُمۡ إِلَّا وَارِدُهَاۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتۡمٗا مَّقۡضِيّٗا
Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀. Ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ dandan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ. 74:30-31. Bákan náà, kalmọh “wārid” t’ó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ méjì péré l’ó wà fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’
Surah Maryam, Verse 71
ثُمَّ نُنَجِّي ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّنَذَرُ ٱلظَّـٰلِمِينَ فِيهَا جِثِيّٗا
igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé àwọn mọlāika kan l’ó máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé
Surah Maryam, Verse 72
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ خَيۡرٞ مَّقَامٗا وَأَحۡسَنُ نَدِيّٗا
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) l’ó lóore jùlọ ní ibùgbé, l’ó sì dára jùlọ ní ìjókòó?”
Surah Maryam, Verse 73
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هُمۡ أَحۡسَنُ أَثَٰثٗا وَرِءۡيٗا
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí
Surah Maryam, Verse 74
قُلۡ مَن كَانَ فِي ٱلضَّلَٰلَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَدًّاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوۡاْ مَا يُوعَدُونَ إِمَّا ٱلۡعَذَابَ وَإِمَّا ٱلسَّاعَةَ فَسَيَعۡلَمُونَ مَنۡ هُوَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضۡعَفُ جُندٗا
Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun
Surah Maryam, Verse 75
وَيَزِيدُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱهۡتَدَوۡاْ هُدٗىۗ وَٱلۡبَٰقِيَٰتُ ٱلصَّـٰلِحَٰتُ خَيۡرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابٗا وَخَيۡرٞ مَّرَدًّا
Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn t’ó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ
Surah Maryam, Verse 76
أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي كَفَرَ بِـَٔايَٰتِنَا وَقَالَ لَأُوتَيَنَّ مَالٗا وَوَلَدًا
Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”
Surah Maryam, Verse 77
أَطَّلَعَ ٱلۡغَيۡبَ أَمِ ٱتَّخَذَ عِندَ ٱلرَّحۡمَٰنِ عَهۡدٗا
Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé
Surah Maryam, Verse 78
كَلَّاۚ سَنَكۡتُبُ مَا يَقُولُ وَنَمُدُّ لَهُۥ مِنَ ٱلۡعَذَابِ مَدّٗا
Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun t’ó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà
Surah Maryam, Verse 79
وَنَرِثُهُۥ مَا يَقُولُ وَيَأۡتِينَا فَرۡدٗا
A ó sì jogún ohun t’ó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan
Surah Maryam, Verse 80
وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةٗ لِّيَكُونُواْ لَهُمۡ عِزّٗا
Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára
Surah Maryam, Verse 81
كَلَّاۚ سَيَكۡفُرُونَ بِعِبَادَتِهِمۡ وَيَكُونُونَ عَلَيۡهِمۡ ضِدًّا
Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn
Surah Maryam, Verse 82
أَلَمۡ تَرَ أَنَّآ أَرۡسَلۡنَا ٱلشَّيَٰطِينَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ تَؤُزُّهُمۡ أَزّٗا
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Àwa ń rán àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń tì wọ́n ní ìtìkutì (síbi ẹ̀ṣẹ̀)
Surah Maryam, Verse 83
فَلَا تَعۡجَلۡ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّمَا نَعُدُّ لَهُمۡ عَدّٗا
Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà
Surah Maryam, Verse 84
يَوۡمَ نَحۡشُرُ ٱلۡمُتَّقِينَ إِلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ وَفۡدٗا
(Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn
Surah Maryam, Verse 85
وَنَسُوقُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ إِلَىٰ جَهَنَّمَ وِرۡدٗا
A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì
Surah Maryam, Verse 86
لَّا يَمۡلِكُونَ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَنِ ٱتَّخَذَ عِندَ ٱلرَّحۡمَٰنِ عَهۡدٗا
Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé
Surah Maryam, Verse 87
وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَلَدٗا
Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ
Surah Maryam, Verse 88
لَّقَدۡ جِئۡتُمۡ شَيۡـًٔا إِدّٗا
Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá
Surah Maryam, Verse 89
تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِنۡهُ وَتَنشَقُّ ٱلۡأَرۡضُ وَتَخِرُّ ٱلۡجِبَالُ هَدًّا
Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dà wó lulẹ̀ gbì
Surah Maryam, Verse 90
أَن دَعَوۡاْ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٗا
fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé
Surah Maryam, Verse 91
وَمَا يَنۢبَغِي لِلرَّحۡمَٰنِ أَن يَتَّخِذَ وَلَدًا
Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ
Surah Maryam, Verse 92
إِن كُلُّ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ إِلَّآ ءَاتِي ٱلرَّحۡمَٰنِ عَبۡدٗا
Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn
Surah Maryam, Verse 93
لَّقَدۡ أَحۡصَىٰهُمۡ وَعَدَّهُمۡ عَدّٗا
Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà
Surah Maryam, Verse 94
وَكُلُّهُمۡ ءَاتِيهِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَرۡدًا
Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan
Surah Maryam, Verse 95
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ سَيَجۡعَلُ لَهُمُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وُدّٗا
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn
Surah Maryam, Verse 96
فَإِنَّمَا يَسَّرۡنَٰهُ بِلِسَانِكَ لِتُبَشِّرَ بِهِ ٱلۡمُتَّقِينَ وَتُنذِرَ بِهِۦ قَوۡمٗا لُّدّٗا
Nítorí náà, A kúkú ṣe kíké al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn (fún ọ) pẹ̀lú èdè abínibí rẹ nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ oníyàn-jíjà
Surah Maryam, Verse 97
وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هَلۡ تُحِسُّ مِنۡهُم مِّنۡ أَحَدٍ أَوۡ تَسۡمَعُ لَهُمۡ رِكۡزَۢا
Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí
Surah Maryam, Verse 98