Surah Al-Baqara Verse 102 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَٱتَّبَعُواْ مَا تَتۡلُواْ ٱلشَّيَٰطِينُ عَلَىٰ مُلۡكِ سُلَيۡمَٰنَۖ وَمَا كَفَرَ سُلَيۡمَٰنُ وَلَٰكِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ كَفَرُواْ يُعَلِّمُونَ ٱلنَّاسَ ٱلسِّحۡرَ وَمَآ أُنزِلَ عَلَى ٱلۡمَلَكَيۡنِ بِبَابِلَ هَٰرُوتَ وَمَٰرُوتَۚ وَمَا يُعَلِّمَانِ مِنۡ أَحَدٍ حَتَّىٰ يَقُولَآ إِنَّمَا نَحۡنُ فِتۡنَةٞ فَلَا تَكۡفُرۡۖ فَيَتَعَلَّمُونَ مِنۡهُمَا مَا يُفَرِّقُونَ بِهِۦ بَيۡنَ ٱلۡمَرۡءِ وَزَوۡجِهِۦۚ وَمَا هُم بِضَآرِّينَ بِهِۦ مِنۡ أَحَدٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَتَعَلَّمُونَ مَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡۚ وَلَقَدۡ عَلِمُواْ لَمَنِ ٱشۡتَرَىٰهُ مَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنۡ خَلَٰقٖۚ وَلَبِئۡسَ مَا شَرَوۡاْ بِهِۦٓ أَنفُسَهُمۡۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Won si tele ohun ti awon esu alujannu n ka (fun won ninu idan) lasiko ijoba (Anabi) Sulaemon. (Anabi) Sulaemon ko si sai gbagbo, sugbon awon esu alujannu ni won sai gbagbo, ti won n ko awon eniyan ni idan. Awa ko si so (idan) kale fun awon molaika meji naa. (Amo awon esu alujannu wonyi) Harut ati Morut ni (ilu) Babil (ni won n ko awon eniyan nidan). Won ko si nii ko enikeni ayafi ki won wi pe: "Adanwo ni wa. Nitori naa, ma di keferi." Won si n kekoo ohun ti won yoo fi sopinya laaarin omoniyan ati eni keji re lodo awon alujannu mejeeji. - Won ko si le ko inira ba enikeni ayafi pelu iyonda Allahu. - Won n kekoo ohun ti o maa ko inira ba won, ti ko si nii se won ni anfaani. Won kuku ti mo pe enikeni ti o ba ra idan, ko nii si ipin rere kan fun un ni Ojo Ikeyin. Aburu si ni ohun ti won ra fun emi ara won ti o ba je pe won mo. ti awon onimo mu wa lori re. Ma se siju wo itumo miiran … bi itan ti won ti fi esun oti mimu ati esun ipaniyan kan awon molaika… Ipile adisokan ti a ni si awon molaika yo fori sanpon nipa pipe Harut ati Morut ni molaika. Awon molaika ni eni ti Allahu ni afokantan si lori imisi Re ti O fi ran won. Awon si ni asoju Allahu fun awon Ojise Re. E wo surah at-Tahrim; 66:6 ati surah al-’Anbiya’; 21:26-27…” al-Ƙurtubiy. bi Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) se n ko awon eniyan re ni igbagbo ododo ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) fi ran an nise si won bee naa ni awon esu alujannu kan n lo ba awon eniyan lati maa ko won ni eko idan lati maa fi tako igbagbo ododo ti won n gbo lodo Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam). Nikete ti iro aburu yii deti igbo Anabi Sulaemon ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) l’o pase lati gba gbogbo akosile idan naa lowo won. O si bo gbogbo re mo inu ile. Amo leyin iku re