Surah Al-Baqara Verse 125 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذۡ جَعَلۡنَا ٱلۡبَيۡتَ مَثَابَةٗ لِّلنَّاسِ وَأَمۡنٗا وَٱتَّخِذُواْ مِن مَّقَامِ إِبۡرَٰهِـۧمَ مُصَلّٗىۖ وَعَهِدۡنَآ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِـۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ أَن طَهِّرَا بَيۡتِيَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلۡعَٰكِفِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe Ilé (Kaaba) ní àyè tí àwọn ènìyàn yóò máa wá àti àyè ìfàyàbalẹ̀. Kí ẹ sì mú ibùdúró ’Ibrọ̄hīm ní ibùkírun. A sì pa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl láṣẹ pé “Ẹ ṣe Ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, àwọn olùkóraró sínú rẹ̀ àti àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún, àwọn olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun)