Surah Al-Baqara Verse 143 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَٰكُمۡ أُمَّةٗ وَسَطٗا لِّتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِ وَيَكُونَ ٱلرَّسُولُ عَلَيۡكُمۡ شَهِيدٗاۗ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلۡقِبۡلَةَ ٱلَّتِي كُنتَ عَلَيۡهَآ إِلَّا لِنَعۡلَمَ مَن يَتَّبِعُ ٱلرَّسُولَ مِمَّن يَنقَلِبُ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِۚ وَإِن كَانَتۡ لَكَبِيرَةً إِلَّا عَلَى ٱلَّذِينَ هَدَى ٱللَّهُۗ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِيعَ إِيمَٰنَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ
Báyẹn ni A ti ṣe yín ní ẹ̀ṣà ìjọ t’ó lóore jùlọ, nítorí kí ẹ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn, àti nítorí kí Òjíṣẹ́ náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín. A kò sì ṣe Ƙiblah tí o wà lórí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ibùkọjú-kírun bí kò ṣe pé nítorí kí Á lè ṣe àfihàn ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tí ó máa yísẹ̀ padà. Dájúdájú ó lágbára àyàfi fún àwọn tí Allāhu tọ́ sọ́nà. Allāhu kò sì níí fi ìgbàgbọ́ yín ráre. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn