Surah Al-Baqara Verse 174 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraإِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡتُمُونَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَيَشۡتَرُونَ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلًا أُوْلَـٰٓئِكَ مَا يَأۡكُلُونَ فِي بُطُونِهِمۡ إِلَّا ٱلنَّارَ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ ٱللَّهُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Dájúdájú àwọn t’ó ń daṣọ bo ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú Tírà, tí wọ́n sì ń tà á ní owó pọ́ọ́kú, àwọn wọ̀nyẹn kò jẹ kiní kan sínú wọn bí kò ṣe Iná. Allāhu kò sì níí bá wọn sọ̀rọ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn