Surah Al-Baqara Verse 215 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraيَسۡـَٔلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَۖ قُلۡ مَآ أَنفَقۡتُم مِّنۡ خَيۡرٖ فَلِلۡوَٰلِدَيۡنِ وَٱلۡأَقۡرَبِينَ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٞ
Wọ́n ń bí ọ léèrè pé kí ni àwọn yó máa náwó sí. Sọ pé: "Ohun tí ẹ bá ná nínú ohun rere, kí ó máa jẹ́ ti àwọn òbí méjèèjì, àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe nínú ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀