Surah Al-Baqara Verse 217 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ قِتَالٖ فِيهِۖ قُلۡ قِتَالٞ فِيهِ كَبِيرٞۚ وَصَدٌّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَكُفۡرُۢ بِهِۦ وَٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَإِخۡرَاجُ أَهۡلِهِۦ مِنۡهُ أَكۡبَرُ عِندَ ٱللَّهِۚ وَٱلۡفِتۡنَةُ أَكۡبَرُ مِنَ ٱلۡقَتۡلِۗ وَلَا يَزَالُونَ يُقَٰتِلُونَكُمۡ حَتَّىٰ يَرُدُّوكُمۡ عَن دِينِكُمۡ إِنِ ٱسۡتَطَٰعُواْۚ وَمَن يَرۡتَدِدۡ مِنكُمۡ عَن دِينِهِۦ فَيَمُتۡ وَهُوَ كَافِرٞ فَأُوْلَـٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Won n bi o leere nipa ogun jija ninu osu owo. So pe: "Ese nla ni ogun jija ninu re. Ati pe siseri awon eniyan kuro l’oju ona (esin) Allahu, sise aigbagbo ninu Allahu, didi awon musulumi lowo lati wo inu Mosalasi Haram ati lile awon musulumi jade kuro ninu re, (iwonyi) tun tobi julo ni ese ni odo Allahu." Ifooro si buru ju ipaniyan lo. Won ko ni yee gbogun ti yin titi won yo fi se yin lori kuro ninu esin yin, ti won ba lagbara (ona lati se bee). Enikeni ninu yin ti o ba seri kuroninu esin re, ti o si ku si ipo keferi, nitori naa awon wonyen ni awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re