Surah Al-Baqara Verse 229 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraٱلطَّلَٰقُ مَرَّتَانِۖ فَإِمۡسَاكُۢ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ تَسۡرِيحُۢ بِإِحۡسَٰنٖۗ وَلَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَأۡخُذُواْ مِمَّآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ شَيۡـًٔا إِلَّآ أَن يَخَافَآ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَا فِيمَا ٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَعۡتَدُوهَاۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ
Ee meji ni ikosile. Nitori naa, e mu won mora pelu daadaa tabi ki e fi won sile pelu daadaa. Ko si letoo fun yin lati gba kini kan ninu ohun ti e ti fun won ayafi ti awon mejeeji ba n paya pe awon ko nii le so awon enu-ala (ofin) Allahu (laaarin ara won). Nitori naa, ti e ba n paya pe awon mejeeji ko nii le so awon enu-ala (ofin) Allahu, ko si ese fun won nigba naa nipa ohun ti obinrin ba fi serapada (emi ara re) Iwonyi ni awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale. Nitori naa, e ma se tayo re. Enikeni ti o ba tayo awon enu-ala (ofin) ti Allahu gbe kale, awon wonyen ni alabosi