Surah Al-Baqara Verse 233 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqara۞وَٱلۡوَٰلِدَٰتُ يُرۡضِعۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ حَوۡلَيۡنِ كَامِلَيۡنِۖ لِمَنۡ أَرَادَ أَن يُتِمَّ ٱلرَّضَاعَةَۚ وَعَلَى ٱلۡمَوۡلُودِ لَهُۥ رِزۡقُهُنَّ وَكِسۡوَتُهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ لَا تُكَلَّفُ نَفۡسٌ إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَا تُضَآرَّ وَٰلِدَةُۢ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوۡلُودٞ لَّهُۥ بِوَلَدِهِۦۚ وَعَلَى ٱلۡوَارِثِ مِثۡلُ ذَٰلِكَۗ فَإِنۡ أَرَادَا فِصَالًا عَن تَرَاضٖ مِّنۡهُمَا وَتَشَاوُرٖ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَاۗ وَإِنۡ أَرَدتُّمۡ أَن تَسۡتَرۡضِعُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِذَا سَلَّمۡتُم مَّآ ءَاتَيۡتُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ
Awon abiyamo yoo maa fun awon omo won ni oyan mu fun odun meji gbako, fun eni ti o ba fe pari (asiko) ifomoloyan. Ojuse ni fun eni ti won bimo fun lati maa se (eto) ije-imu won ati aso won ni ona t’o dara. Won ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. Won ko nii ko inira ba abiyamo nitori omo re. Won ko si nii ko inira ba eni ti won bimo fun nitori omo re. Iru (ojuse) yen tun n be fun olujogun. Ti awon mejeeji ba si fe gba oyan l’enu omo pelu ipanupo ati asaro awon mejeeji, ko si ese fun awon mejeeji. Ti e ba si fe gba eni ti o maa fun awon omo yin loyan mu, ko si ese fun yin, ti e ba ti fun won ni ohun ti e fe fun won (ni owo-oya) ni ona t’o dara. E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise