Surah Al-Baqara Verse 236 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraلَّا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِن طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ مَا لَمۡ تَمَسُّوهُنَّ أَوۡ تَفۡرِضُواْ لَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَمَتِّعُوهُنَّ عَلَى ٱلۡمُوسِعِ قَدَرُهُۥ وَعَلَى ٱلۡمُقۡتِرِ قَدَرُهُۥ مَتَٰعَۢا بِٱلۡمَعۡرُوفِۖ حَقًّا عَلَى ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín, tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, láì tí ì súnmọ́ wọn tàbí láì tí ì sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn ní pàtó. Kí ẹ sì fún wọn ní ẹ̀bùn (ìkọ̀sílẹ̀); kí olùgbòòrò (nínú arísìkí) fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀, kí tálíkà sì fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀nà t’ó dára. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùṣe-rere