Surah Al-Baqara Verse 243 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqara۞أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ خَرَجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَهُمۡ أُلُوفٌ حَذَرَ ٱلۡمَوۡتِ فَقَالَ لَهُمُ ٱللَّهُ مُوتُواْ ثُمَّ أَحۡيَٰهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ
Ṣé o ò rí àwọn t’ó jáde láti inú ilé wọn lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún nítorí ìbẹ̀rù ikú! Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kú.” Lẹ́yìn náà, Ó sọ wọ́n di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Olóore-àjùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò dúpẹ́ (fún Un)