Surah Al-Baqara Verse 249 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraفَلَمَّا فَصَلَ طَالُوتُ بِٱلۡجُنُودِ قَالَ إِنَّ ٱللَّهَ مُبۡتَلِيكُم بِنَهَرٖ فَمَن شَرِبَ مِنۡهُ فَلَيۡسَ مِنِّي وَمَن لَّمۡ يَطۡعَمۡهُ فَإِنَّهُۥ مِنِّيٓ إِلَّا مَنِ ٱغۡتَرَفَ غُرۡفَةَۢ بِيَدِهِۦۚ فَشَرِبُواْ مِنۡهُ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۚ فَلَمَّا جَاوَزَهُۥ هُوَ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ قَالُواْ لَا طَاقَةَ لَنَا ٱلۡيَوۡمَ بِجَالُوتَ وَجُنُودِهِۦۚ قَالَ ٱلَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَٰقُواْ ٱللَّهِ كَم مِّن فِئَةٖ قَلِيلَةٍ غَلَبَتۡ فِئَةٗ كَثِيرَةَۢ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ مَعَ ٱلصَّـٰبِرِينَ
Nigba ti Tolut jade pelu awon omo ogun, o so pe: “Dajudaju Allahu maa fi odo kan dan yin wo. Nitori naa, enikeni ti o ba mu ninu re, ki i se eni mi. Eni ti ko ba to o wo dajudaju oun ni eni mi, ayafi eni ti o ba bu iwon ekunwo re kan mu.” (Sugbon) won mu ninu re afi die ninu won. Nigba ti oun ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re soda odo naa, won so pe: “Ko si agbara kan fun wa lonii ti a le fi k’oju Jalut ati awon omo ogun re.” Awon t’o mo pe dajudaju awon maa pade Allahu, won so pe: "Meloo meloo ninu awon ijo (ogun) kekere t’o ti segun ijo (ogun) pupo pelu iyonda Allahu. Allahu n be pelu awon onisuuru