Surah Al-Baqara Verse 253 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqara۞تِلۡكَ ٱلرُّسُلُ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۘ مِّنۡهُم مَّن كَلَّمَ ٱللَّهُۖ وَرَفَعَ بَعۡضَهُمۡ دَرَجَٰتٖۚ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلَ ٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ وَلَٰكِنِ ٱخۡتَلَفُواْ فَمِنۡهُم مَّنۡ ءَامَنَ وَمِنۡهُم مَّن كَفَرَۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلُواْ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ
Awon Ojise wonyen, A soore ajulo fun apa kan won lori apa kan. O n be ninu won, eni ti Allahu ba soro (taara). O si se agbega awon ipo fun apa kan won. A fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fi Emi Mimo (iyen, molaika Jibril) ran an lowo. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, awon t’o wa leyin won iba ti bara won ja leyin ti awon eri to yanju ti de ba won. Sugbon won yapa enu (si esin ’Islam). O n be ninu won eni t’o gbagbo ni ododo (ti o je musulumi). O si n be ninu won eni t’o sai gbagbo (ti o di nasara). Ati pe ti Allahu ba fe, won iba ti ba’ra won ja, sugbon Allahu n se ohun ti O ba fe