Surah Al-Baqara Verse 255 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُۚ لَا تَأۡخُذُهُۥ سِنَةٞ وَلَا نَوۡمٞۚ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ مَن ذَا ٱلَّذِي يَشۡفَعُ عِندَهُۥٓ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيۡءٖ مِّنۡ عِلۡمِهِۦٓ إِلَّا بِمَا شَآءَۚ وَسِعَ كُرۡسِيُّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۖ وَلَا يَـُٔودُهُۥ حِفۡظُهُمَاۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi