Surah Al-Baqara Verse 259 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraأَوۡ كَٱلَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرۡيَةٖ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحۡيِۦ هَٰذِهِ ٱللَّهُ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۖ فَأَمَاتَهُ ٱللَّهُ مِاْئَةَ عَامٖ ثُمَّ بَعَثَهُۥۖ قَالَ كَمۡ لَبِثۡتَۖ قَالَ لَبِثۡتُ يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۖ قَالَ بَل لَّبِثۡتَ مِاْئَةَ عَامٖ فَٱنظُرۡ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمۡ يَتَسَنَّهۡۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجۡعَلَكَ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِۖ وَٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡعِظَامِ كَيۡفَ نُنشِزُهَا ثُمَّ نَكۡسُوهَا لَحۡمٗاۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥ قَالَ أَعۡلَمُ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Tabi bi eni ti o koja ninu ilu kan nigba ti o ti tu torule-torule re. O so pe: “Bawo ni Allahu yo se so eyi di alaaye leyin iku re!” Allahu si so o di oku fun ogorun-un odun. Leyin naa, O gbe e dide. O so pe: “Igba wo ni o ti wa nibi?” O so pe: “Mo wa nibi fun ojo kan tabi ilaji ojo.” O so pe: “Bee ko, o wa nibi fun ogorun-un odun. Wo ounje re ati omi re, ko yi pada. Tun wo ketekete re, ki A le fi o se ami kan fun awon eniyan. Si tun wo eegun naa bi A o se to won papo mora won. Leyin naa, (wo) bi A o se da eran bo o lara. Nigba ti o foju han si i kedere (bee), o so pe: “Mo mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.”