Surah Al-Baqara Verse 273 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraلِلۡفُقَرَآءِ ٱلَّذِينَ أُحۡصِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا يَسۡتَطِيعُونَ ضَرۡبٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ يَحۡسَبُهُمُ ٱلۡجَاهِلُ أَغۡنِيَآءَ مِنَ ٱلتَّعَفُّفِ تَعۡرِفُهُم بِسِيمَٰهُمۡ لَا يَسۡـَٔلُونَ ٱلنَّاسَ إِلۡحَافٗاۗ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٌ
(Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì nítorí kí wọ́n lè máa jagun) fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́. Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀