Surah Al-Baqara Verse 275 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraٱلَّذِينَ يَأۡكُلُونَ ٱلرِّبَوٰاْ لَا يَقُومُونَ إِلَّا كَمَا يَقُومُ ٱلَّذِي يَتَخَبَّطُهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ مِنَ ٱلۡمَسِّۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡبَيۡعُ مِثۡلُ ٱلرِّبَوٰاْۗ وَأَحَلَّ ٱللَّهُ ٱلۡبَيۡعَ وَحَرَّمَ ٱلرِّبَوٰاْۚ فَمَن جَآءَهُۥ مَوۡعِظَةٞ مِّن رَّبِّهِۦ فَٱنتَهَىٰ فَلَهُۥ مَا سَلَفَ وَأَمۡرُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۖ وَمَنۡ عَادَ فَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Awon t’o n je ele ko nii dide (ninu saree) afi bi eni ti Esu fowo ba ti n ta geegee yo se dide. Iyen ri bee nitori pe won wi pe: “Owo sise da bi owo ele.” Allahu si se owo sise ni eto, O si se owo ele ni eewo. Enikeni ti waasi ba de ba lati odo Oluwa re, ti o si jawo, tire ni eyi t’o siwaju, oro re si di odo Allahu. Enikeni ti o ba si pada (sibi owo ele), awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere si ni won ninu re