Surah Al-Baqara Verse 284 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraلِّلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَإِن تُبۡدُواْ مَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ أَوۡ تُخۡفُوهُ يُحَاسِبۡكُم بِهِ ٱللَّهُۖ فَيَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun t’ó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fun yín (tí ẹ bá ṣe é níṣẹ́). Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan