Surah Al-Baqara Verse 29 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ لَكُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَسَوَّىٰهُنَّ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖۚ وَهُوَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Òun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ fun yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó wà l’ókè sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan