Surah Al-Baqara Verse 49 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذۡ نَجَّيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ
(Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín