Surah Al-Baqara Verse 61 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نَّصۡبِرَ عَلَىٰ طَعَامٖ وَٰحِدٖ فَٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُخۡرِجۡ لَنَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۢ بَقۡلِهَا وَقِثَّآئِهَا وَفُومِهَا وَعَدَسِهَا وَبَصَلِهَاۖ قَالَ أَتَسۡتَبۡدِلُونَ ٱلَّذِي هُوَ أَدۡنَىٰ بِٱلَّذِي هُوَ خَيۡرٌۚ ٱهۡبِطُواْ مِصۡرٗا فَإِنَّ لَكُم مَّا سَأَلۡتُمۡۗ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ وَٱلۡمَسۡكَنَةُ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ
(E ranti) nigba ti e wi pe: “Musa, a o nii se ifarada lori ounje eyo kan. Nitori naa, pe Oluwa re fun wa. Ki O mu jade fun wa ninu ohun ti ile n hu jade bi ewebe re, kukumba re, oka baba re, ewa re ati alubosa re.” (Anabi Musa) so pe: “Se eyin yoo fi eyi to yepere paaro eyi ti o dara julo ni? E sokale sinu ilu (miiran). Dajudaju ohun ti e n beere fun n be (nibe) fun yin.” A si mu iyepere ati osi ba won. Won si pada wale pelu ibinu lati odo Allahu. Iyen nitori pe dajudaju won n sai gbagbo ninu awon ayah Allahu, won si n pa awon Anabi lai letoo. Iyen nitori pe won yapa (ase Allahu), won si n tayo enu-ala