Surah Al-Baqara Verse 87 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَقَفَّيۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ بِٱلرُّسُلِۖ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ أَفَكُلَّمَا جَآءَكُمۡ رَسُولُۢ بِمَا لَا تَهۡوَىٰٓ أَنفُسُكُمُ ٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡ فَفَرِيقٗا كَذَّبۡتُمۡ وَفَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ
Dajudaju A ti fun (Anabi) Musa ni Tira. A si mu awon Ojise wa ni telentele leyin re. A tun fun (Anabi) ‘Isa omo Moryam ni awon eri t’o yanju. A tun fun ni agbara nipase Emi Mimo (iyen, Molaika Jibril). Se gbogbo igba ti Ojise kan ba wa ba yin pelu ohun ti okan yin ko fe ni e o maa segberaga? E si pe apa kan (awon Anabi) ni opuro, e si n pa apa kan