Surah Al-Baqara Verse 93 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Baqaraوَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ وَرَفَعۡنَا فَوۡقَكُمُ ٱلطُّورَ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱسۡمَعُواْۖ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَعَصَيۡنَا وَأُشۡرِبُواْ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡعِجۡلَ بِكُفۡرِهِمۡۚ قُلۡ بِئۡسَمَا يَأۡمُرُكُم بِهِۦٓ إِيمَٰنُكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s’ókè orí yín, (A sọ pé:) "Ẹ gbá ohun tí A fun yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀." Wọ́n wí pé: "A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (àṣẹ)." Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: "Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo