Surah An-Noor Verse 33 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Noorوَلۡيَسۡتَعۡفِفِ ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغۡنِيَهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَٱلَّذِينَ يَبۡتَغُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِمَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡ فَكَاتِبُوهُمۡ إِنۡ عَلِمۡتُمۡ فِيهِمۡ خَيۡرٗاۖ وَءَاتُوهُم مِّن مَّالِ ٱللَّهِ ٱلَّذِيٓ ءَاتَىٰكُمۡۚ وَلَا تُكۡرِهُواْ فَتَيَٰتِكُمۡ عَلَى ٱلۡبِغَآءِ إِنۡ أَرَدۡنَ تَحَصُّنٗا لِّتَبۡتَغُواْ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَن يُكۡرِههُّنَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ مِنۢ بَعۡدِ إِكۡرَٰهِهِنَّ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Ki awon ti ko ri (owo lati fe) iyawo mu oju won kuro nibi isekuse titi Allahu yoo fi ro won loro ninu ola Re.1 Awon t’o n wa iwe ominira ninu awon eru yin, e ko iwe ominira fun won ti e ba mo ohun rere nipa won. Ki e si fun won ninu dukia Allahu ti O fun yin. (Nitori dukia aye ti e n wa), e ma se je awon erubinrin yin nipa lati lo se sina, ti won ba fe so abe won nibi isekuse.2 Enikeni ti o ba je won nipa, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun leyin ti e ti je won nipa