Surah An-Noor Verse 35 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Noor۞ٱللَّهُ نُورُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ مَثَلُ نُورِهِۦ كَمِشۡكَوٰةٖ فِيهَا مِصۡبَاحٌۖ ٱلۡمِصۡبَاحُ فِي زُجَاجَةٍۖ ٱلزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوۡكَبٞ دُرِّيّٞ يُوقَدُ مِن شَجَرَةٖ مُّبَٰرَكَةٖ زَيۡتُونَةٖ لَّا شَرۡقِيَّةٖ وَلَا غَرۡبِيَّةٖ يَكَادُ زَيۡتُهَا يُضِيٓءُ وَلَوۡ لَمۡ تَمۡسَسۡهُ نَارٞۚ نُّورٌ عَلَىٰ نُورٖۚ يَهۡدِي ٱللَّهُ لِنُورِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَ لِلنَّاسِۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Allahu ni Olutan-imole sinu awon sanmo ati ile. Apejuwe imole Re da bi opo atupa kan ti atupa wa ninu re. Atupa naa si wa ninu dingi. Dingi naa da bi irawo kan t’o n tan yanranyanran. Won n tan (imole naa) lati ara igi ibukun kan, igi zaetun. Ki i gba imole nigba ti oorun ba n yo jade tabi nigba ti oorun ba n wo. Epo (imole) re fee da mu imole wa, ina ibaa ma de ibe. Imole lori imole ni. Allahu n to enikeni ti O ba fe si (ona) imole Re. Allahu n fi awon akawe lele fun awon eniyan. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan