UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Al-Qasas - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


طسٓمٓ

Tọ̄ sīn mīm
Surah Al-Qasas, Verse 1


تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá
Surah Al-Qasas, Verse 2


نَتۡلُواْ عَلَيۡكَ مِن نَّبَإِ مُوسَىٰ وَفِرۡعَوۡنَ بِٱلۡحَقِّ لِقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ

À ń ké nínú ìró (Ànábì) Mūsā àti Fir‘aon fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí ìjọ t’ó gbàgbọ́ lódodo
Surah Al-Qasas, Verse 3


إِنَّ فِرۡعَوۡنَ عَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَجَعَلَ أَهۡلَهَا شِيَعٗا يَسۡتَضۡعِفُ طَآئِفَةٗ مِّنۡهُمۡ يُذَبِّحُ أَبۡنَآءَهُمۡ وَيَسۡتَحۡيِۦ نِسَآءَهُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ

Dájúdájú Fir‘aon ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Ó ṣe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìjọ-ìjọ. Ó ń dá igun kan nínú wọn lágara; ó ń pa àwọn ọmọkùnrin wọn, ó sì ń dá àwọn obìnrin wọn sí. Dájúdájú ó wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́
Surah Al-Qasas, Verse 4


وَنُرِيدُ أَن نَّمُنَّ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنَجۡعَلَهُمۡ أَئِمَّةٗ وَنَجۡعَلَهُمُ ٱلۡوَٰرِثِينَ

A sì fẹ́ ṣèdẹ̀ra fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín lórí ilẹ̀, A (fẹ́) ṣe wọ́n ní aṣíwájú. A sì (fẹ́) kí wọ́n jogún (ilẹ̀)
Surah Al-Qasas, Verse 5


وَنُمَكِّنَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنُرِيَ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا مِنۡهُم مَّا كَانُواْ يَحۡذَرُونَ

A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn
Surah Al-Qasas, Verse 6


وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ أُمِّ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَرۡضِعِيهِۖ فَإِذَا خِفۡتِ عَلَيۡهِ فَأَلۡقِيهِ فِي ٱلۡيَمِّ وَلَا تَخَافِي وَلَا تَحۡزَنِيٓۖ إِنَّا رَآدُّوهُ إِلَيۡكِ وَجَاعِلُوهُ مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú agbami odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́
Surah Al-Qasas, Verse 7


فَٱلۡتَقَطَهُۥٓ ءَالُ فِرۡعَوۡنَ لِيَكُونَ لَهُمۡ عَدُوّٗا وَحَزَنًاۗ إِنَّ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَجُنُودَهُمَا كَانُواْ خَٰطِـِٔينَ

Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe
Surah Al-Qasas, Verse 8


وَقَالَتِ ٱمۡرَأَتُ فِرۡعَوۡنَ قُرَّتُ عَيۡنٖ لِّي وَلَكَۖ لَا تَقۡتُلُوهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ

Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura
Surah Al-Qasas, Verse 9


وَأَصۡبَحَ فُؤَادُ أُمِّ مُوسَىٰ فَٰرِغًاۖ إِن كَادَتۡ لَتُبۡدِي بِهِۦ لَوۡلَآ أَن رَّبَطۡنَا عَلَىٰ قَلۡبِهَا لِتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Al-Qasas, Verse 10


وَقَالَتۡ لِأُخۡتِهِۦ قُصِّيهِۖ فَبَصُرَتۡ بِهِۦ عَن جُنُبٖ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ

Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọpa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi t’ó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i)
Surah Al-Qasas, Verse 11


۞وَحَرَّمۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَرَاضِعَ مِن قَبۡلُ فَقَالَتۡ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰٓ أَهۡلِ بَيۡتٖ يَكۡفُلُونَهُۥ لَكُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ نَٰصِحُونَ

A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) Arábìnrin rẹ̀ sì wí pé: “Ṣé kí n̄g fi ará ilé kan hàn yín, tí ó máa gbà á tọ́ fun yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.”
Surah Al-Qasas, Verse 12


فَرَدَدۡنَٰهُ إِلَىٰٓ أُمِّهِۦ كَيۡ تَقَرَّ عَيۡنُهَا وَلَا تَحۡزَنَ وَلِتَعۡلَمَ أَنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀
Surah Al-Qasas, Verse 13


وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥ وَٱسۡتَوَىٰٓ ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Nígbà t’ó dàgbà, t’ó di géńdé, A fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san
Surah Al-Qasas, Verse 14


وَدَخَلَ ٱلۡمَدِينَةَ عَلَىٰ حِينِ غَفۡلَةٖ مِّنۡ أَهۡلِهَا فَوَجَدَ فِيهَا رَجُلَيۡنِ يَقۡتَتِلَانِ هَٰذَا مِن شِيعَتِهِۦ وَهَٰذَا مِنۡ عَدُوِّهِۦۖ فَٱسۡتَغَٰثَهُ ٱلَّذِي مِن شِيعَتِهِۦ عَلَى ٱلَّذِي مِنۡ عَدُوِّهِۦ فَوَكَزَهُۥ مُوسَىٰ فَقَضَىٰ عَلَيۡهِۖ قَالَ هَٰذَا مِنۡ عَمَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِۖ إِنَّهُۥ عَدُوّٞ مُّضِلّٞ مُّبِينٞ

Ó wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀). Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ Èṣù. Dájúdájú (èṣù) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”
Surah Al-Qasas, Verse 15


قَالَ رَبِّ إِنِّي ظَلَمۡتُ نَفۡسِي فَٱغۡفِرۡ لِي فَغَفَرَ لَهُۥٓۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Nítorí náà, foríjìn mí.” Ó sì foríjìn ín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Al-Qasas, Verse 16


قَالَ رَبِّ بِمَآ أَنۡعَمۡتَ عَلَيَّ فَلَنۡ أَكُونَ ظَهِيرٗا لِّلۡمُجۡرِمِينَ

Ó sọ pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe ìkẹ́ fún mi, èmi kò níí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Surah Al-Qasas, Verse 17


فَأَصۡبَحَ فِي ٱلۡمَدِينَةِ خَآئِفٗا يَتَرَقَّبُ فَإِذَا ٱلَّذِي ٱسۡتَنصَرَهُۥ بِٱلۡأَمۡسِ يَسۡتَصۡرِخُهُۥۚ قَالَ لَهُۥ مُوسَىٰٓ إِنَّكَ لَغَوِيّٞ مُّبِينٞ

Nítorí náà, ó di ẹni t’ó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”
Surah Al-Qasas, Verse 18


فَلَمَّآ أَنۡ أَرَادَ أَن يَبۡطِشَ بِٱلَّذِي هُوَ عَدُوّٞ لَّهُمَا قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ أَتُرِيدُ أَن تَقۡتُلَنِي كَمَا قَتَلۡتَ نَفۡسَۢا بِٱلۡأَمۡسِۖ إِن تُرِيدُ إِلَّآ أَن تَكُونَ جَبَّارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا تُرِيدُ أَن تَكُونَ مِنَ ٱلۡمُصۡلِحِينَ

Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: “Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe.”
Surah Al-Qasas, Verse 19


وَجَآءَ رَجُلٞ مِّنۡ أَقۡصَا ٱلۡمَدِينَةِ يَسۡعَىٰ قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ إِنَّ ٱلۡمَلَأَ يَأۡتَمِرُونَ بِكَ لِيَقۡتُلُوكَ فَٱخۡرُجۡ إِنِّي لَكَ مِنَ ٱلنَّـٰصِحِينَ

Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Mūsā, dájúdájú àwọn ìjòyè ń dá ìmọ̀ràn lórí rẹ láti pa ọ́. Nítorí náà, jáde (kúrò nínú ìlú), dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn rere fún ọ.”
Surah Al-Qasas, Verse 20


فَخَرَجَ مِنۡهَا خَآئِفٗا يَتَرَقَّبُۖ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Ó sì jáde kúrò nínú (ìlú) pẹ̀lú ìpáyà, tí ó ń retí (ẹ̀hónú wọn), ó sì sọ pé: “Olúwa mi, là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
Surah Al-Qasas, Verse 21


وَلَمَّا تَوَجَّهَ تِلۡقَآءَ مَدۡيَنَ قَالَ عَسَىٰ رَبِّيٓ أَن يَهۡدِيَنِي سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ

Nígbà tí ó sì dojú kọ ọ̀kánkán ìlú Mọdyan, ó sọ pé: “Ó súnmọ́ kí Olúwa mi fọ̀nà tààrà (sí ìlú Mọdyan) mọ̀ mí.”
Surah Al-Qasas, Verse 22


وَلَمَّا وَرَدَ مَآءَ مَدۡيَنَ وَجَدَ عَلَيۡهِ أُمَّةٗ مِّنَ ٱلنَّاسِ يَسۡقُونَ وَوَجَدَ مِن دُونِهِمُ ٱمۡرَأَتَيۡنِ تَذُودَانِۖ قَالَ مَا خَطۡبُكُمَاۖ قَالَتَا لَا نَسۡقِي حَتَّىٰ يُصۡدِرَ ٱلرِّعَآءُۖ وَأَبُونَا شَيۡخٞ كَبِيرٞ

Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: “Kí l’ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?” Wọ́n sọ pé: “A ò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlagbà arúgbó sì ni bàbá wa.”
Surah Al-Qasas, Verse 23


فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰٓ إِلَى ٱلظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَآ أَنزَلۡتَ إِلَيَّ مِنۡ خَيۡرٖ فَقِيرٞ

Ó sì bá wọn fún (ẹran-ọ̀sìn) wọn ní omi mu. Lẹ́yìn náà, ó padà síbi ibòji, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi bùkátà sí ohun tí O bá sọ̀kalẹ̀ fún mi nínú oore.”
Surah Al-Qasas, Verse 24


فَجَآءَتۡهُ إِحۡدَىٰهُمَا تَمۡشِي عَلَى ٱسۡتِحۡيَآءٖ قَالَتۡ إِنَّ أَبِي يَدۡعُوكَ لِيَجۡزِيَكَ أَجۡرَ مَا سَقَيۡتَ لَنَاۚ فَلَمَّا جَآءَهُۥ وَقَصَّ عَلَيۡهِ ٱلۡقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفۡۖ نَجَوۡتَ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì wá bá a, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìtìjú, ó sọ pé: “Dájúdájú bàbá mi ń pè ọ́ nítorí kí ó lè san ọ́ ní ẹ̀san omi tí o fún (àwọn ẹran-ọ̀sìn) wa mu.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ ìtàn (ara rẹ̀) fún un. (Bàbá náà) sọ pé: “Má bẹ̀rù. O ti là lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
Surah Al-Qasas, Verse 25


قَالَتۡ إِحۡدَىٰهُمَا يَـٰٓأَبَتِ ٱسۡتَـٔۡجِرۡهُۖ إِنَّ خَيۡرَ مَنِ ٱسۡتَـٔۡجَرۡتَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡأَمِينُ

Ọ̀kan nínú (àwọn ọmọbìnrin) méjèèjì sọ pé: “Bàbá mi o, gbà á síṣẹ́. Dájúdájú ẹni t’ó dára jùlọ tí o lè gbà síṣẹ́ ni alágbára, olùfọkàntán.”
Surah Al-Qasas, Verse 26


قَالَ إِنِّيٓ أُرِيدُ أَنۡ أُنكِحَكَ إِحۡدَى ٱبۡنَتَيَّ هَٰتَيۡنِ عَلَىٰٓ أَن تَأۡجُرَنِي ثَمَٰنِيَ حِجَجٖۖ فَإِنۡ أَتۡمَمۡتَ عَشۡرٗا فَمِنۡ عِندِكَۖ وَمَآ أُرِيدُ أَنۡ أَشُقَّ عَلَيۡكَۚ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Ó sọ pé: “Dájúdájú mo fẹ́ fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì wọ̀nyí fún ọ ní aya lórí (àdéhùn) pé o máa bá mi ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣe é pé ọdún mẹ́wàá, láti ọ̀dọ̀ rẹ nìyẹn. Èmi kò sì fẹ́ kó ìnira bá ọ. Tí Allāhu bá fẹ́, o máa rí i pé mo wà nínú àwọn ẹni rere.”
Surah Al-Qasas, Verse 27


قَالَ ذَٰلِكَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَۖ أَيَّمَا ٱلۡأَجَلَيۡنِ قَضَيۡتُ فَلَا عُدۡوَٰنَ عَلَيَّۖ وَٱللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٞ

(Mūsā) sọ pé: “(Àdéhùn) yìí wà láààrin èmi àti ìwọ. Èyíkéyìí tí mo bá mú ṣẹ nínú àdéhùn méjèèjì náà, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣàbòsí sí mi. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
Surah Al-Qasas, Verse 28


۞فَلَمَّا قَضَىٰ مُوسَى ٱلۡأَجَلَ وَسَارَ بِأَهۡلِهِۦٓ ءَانَسَ مِن جَانِبِ ٱلطُّورِ نَارٗاۖ قَالَ لِأَهۡلِهِ ٱمۡكُثُوٓاْ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا لَّعَلِّيٓ ءَاتِيكُم مِّنۡهَا بِخَبَرٍ أَوۡ جَذۡوَةٖ مِّنَ ٱلنَّارِ لَعَلَّكُمۡ تَصۡطَلُونَ

Nígbà tí Mūsā parí àkókò náà, ó mú ará ilé rẹ̀ rin (ìrìn-àjò). Ó sì rí iná kan ní ẹ̀bá àpáta. Ó sọ fún ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró (síbí ná). Èmi rí iná kan. Ó ṣe é ṣe kí n̄g mú ìró kan wá ba yín láti ibẹ̀ tàbí (kí n̄g mú) ògúnná kan wá nítorí kí ẹ lè rí ohun yẹ́ná.”
Surah Al-Qasas, Verse 29


فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِيَ مِن شَٰطِيِٕ ٱلۡوَادِ ٱلۡأَيۡمَنِ فِي ٱلۡبُقۡعَةِ ٱلۡمُبَٰرَكَةِ مِنَ ٱلشَّجَرَةِ أَن يَٰمُوسَىٰٓ إِنِّيٓ أَنَا ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é láti ẹ̀gbẹ́ àfonífojì ní ọwọ́ ọ̀tún (rẹ̀) ní àyè ìbùkún láti ibi igi náà. (A sọ pé): “Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
Surah Al-Qasas, Verse 30


وَأَنۡ أَلۡقِ عَصَاكَۚ فَلَمَّا رَءَاهَا تَهۡتَزُّ كَأَنَّهَا جَآنّٞ وَلَّىٰ مُدۡبِرٗا وَلَمۡ يُعَقِّبۡۚ يَٰمُوسَىٰٓ أَقۡبِلۡ وَلَا تَخَفۡۖ إِنَّكَ مِنَ ٱلۡأٓمِنِينَ

Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” (Ó sì jù ú sílẹ̀). Nígbà tí ó rí i t’ó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìn dà, ó ń sá lọ́, kò sì padà. (Allāhu sọ pé): “Mūsā, máa bọ̀ padà, má sì ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn olùfàyàbalẹ̀
Surah Al-Qasas, Verse 31


ٱسۡلُكۡ يَدَكَ فِي جَيۡبِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٖ وَٱضۡمُمۡ إِلَيۡكَ جَنَاحَكَ مِنَ ٱلرَّهۡبِۖ فَذَٰنِكَ بُرۡهَٰنَانِ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦٓۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ

Ti ọwọ́ rẹ bọ (abíyá láti ibi) ọrùn ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra sí (abíyá rẹ) níbi ẹ̀rù. Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Surah Al-Qasas, Verse 32


قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلۡتُ مِنۡهُمۡ نَفۡسٗا فَأَخَافُ أَن يَقۡتُلُونِ

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pa ẹnì kan nínú wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí
Surah Al-Qasas, Verse 33


وَأَخِي هَٰرُونُ هُوَ أَفۡصَحُ مِنِّي لِسَانٗا فَأَرۡسِلۡهُ مَعِيَ رِدۡءٗا يُصَدِّقُنِيٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ

Àti pé arákùnrin mi, Hārūn, ó dá láhọ́n jù mí lọ. Nítorí náà, rán an níṣẹ́ pẹ̀lú mi, kí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí yóò máa jẹ́rìí sí òdodo ọ̀rọ̀ mi. Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.”
Surah Al-Qasas, Verse 34


قَالَ سَنَشُدُّ عَضُدَكَ بِأَخِيكَ وَنَجۡعَلُ لَكُمَا سُلۡطَٰنٗا فَلَا يَصِلُونَ إِلَيۡكُمَا بِـَٔايَٰتِنَآۚ أَنتُمَا وَمَنِ ٱتَّبَعَكُمَا ٱلۡغَٰلِبُونَ

(Allāhu) sọ pé: “A máa fi arákùnrin rẹ kún ọ lọ́wọ́. A ó sì fún ẹ̀yin méjèèjì ní agbára, wọn kò sì níí lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀yin méjèèjì. Pẹ̀lú àwọn àmì Wa, ẹ̀yin méjèèjì àti àwọn t’ó bá tẹ̀lé ẹ̀yin méjèèjì l’ó máa borí.”
Surah Al-Qasas, Verse 35


فَلَمَّا جَآءَهُم مُّوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا بَيِّنَٰتٖ قَالُواْ مَا هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّفۡتَرٗى وَمَا سَمِعۡنَا بِهَٰذَا فِيٓ ءَابَآئِنَا ٱلۡأَوَّلِينَ

Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé bá wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àdáhun. A kò sì gbọ́ èyí (rí) láààrin àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Surah Al-Qasas, Verse 36


وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّيٓ أَعۡلَمُ بِمَن جَآءَ بِٱلۡهُدَىٰ مِنۡ عِندِهِۦ وَمَن تَكُونُ لَهُۥ عَٰقِبَةُ ٱلدَّارِۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ

(Ànábì) Mūsā sì sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ẹni tí àtubọ̀tán ilé (ìkẹ́) máa jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
Surah Al-Qasas, Verse 37


وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ مَا عَلِمۡتُ لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرِي فَأَوۡقِدۡ لِي يَٰهَٰمَٰنُ عَلَى ٱلطِّينِ فَٱجۡعَل لِّي صَرۡحٗا لَّعَلِّيٓ أَطَّلِعُ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ

Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi! Nítorí náà, Hāmọ̄n, dá iná fún mi, kí o fi mọ amọ̀, kí o sì kọ́ ilé gíga kan fún mi nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā. (Nítorí pé) dájúdájú mò ń rò ó sí ara àwọn òpùrọ́.”
Surah Al-Qasas, Verse 38


وَٱسۡتَكۡبَرَ هُوَ وَجُنُودُهُۥ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ إِلَيۡنَا لَا يُرۡجَعُونَ

Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì rò pé dájúdájú A ò níí dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Wa
Surah Al-Qasas, Verse 39


فَأَخَذۡنَٰهُ وَجُنُودَهُۥ فَنَبَذۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Nítorí náà, A gbá òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú; A jù wọ́n sínú agbami odò. Wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ti rí
Surah Al-Qasas, Verse 40


وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَئِمَّةٗ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلنَّارِۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا يُنصَرُونَ

A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń pèpè sínú Iná. Tí ó bá sì di Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́
Surah Al-Qasas, Verse 41


وَأَتۡبَعۡنَٰهُمۡ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ هُم مِّنَ ٱلۡمَقۡبُوحِينَ

Àti pé A fi ègún tọpa wọn ní ilé ayé yìí. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yó sì wà nínú àwọn ẹni ìparun
Surah Al-Qasas, Verse 42


وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِ مَآ أَهۡلَكۡنَا ٱلۡقُرُونَ ٱلۡأُولَىٰ بَصَآئِرَ لِلنَّاسِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لَّعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ

Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà lẹ́yìn ìgbà tí A ti pa àwọn ìjọ àkọ́kọ́ rẹ́. (Tírà náà jẹ́) àríwòye fún àwọn ènìyàn, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí
Surah Al-Qasas, Verse 43


وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ ٱلۡغَرۡبِيِّ إِذۡ قَضَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَى ٱلۡأَمۡرَ وَمَا كُنتَ مِنَ ٱلشَّـٰهِدِينَ

Ìwọ kò sí ní ẹ̀bá ìwọ̀-òòrùn nígbà tí A fi ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā. Àti pé ìwọ kò sí nínú àwọn t’ó wà níbẹ̀
Surah Al-Qasas, Verse 44


وَلَٰكِنَّآ أَنشَأۡنَا قُرُونٗا فَتَطَاوَلَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡعُمُرُۚ وَمَا كُنتَ ثَاوِيٗا فِيٓ أَهۡلِ مَدۡيَنَ تَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَا وَلَٰكِنَّا كُنَّا مُرۡسِلِينَ

Ṣùgbọ́n A ṣẹ̀dá àwọn ìran kan tí ẹ̀mí wọn gùn. O ò kúkú gbé láààrin ará ìlú Mọdyan, tí ò ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, ṣùgbọ́n Àwa l’à ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́
Surah Al-Qasas, Verse 45


وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ ٱلطُّورِ إِذۡ نَادَيۡنَا وَلَٰكِن رَّحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٖ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ

(Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí. 16:36 àti sūrah Fātir 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀ Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan t’ó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé
Surah Al-Qasas, Verse 46


وَلَوۡلَآ أَن تُصِيبَهُم مُّصِيبَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ فَيَقُولُواْ رَبَّنَا لَوۡلَآ أَرۡسَلۡتَ إِلَيۡنَا رَسُولٗا فَنَتَّبِعَ ءَايَٰتِكَ وَنَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
Surah Al-Qasas, Verse 47


فَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ مِنۡ عِندِنَا قَالُواْ لَوۡلَآ أُوتِيَ مِثۡلَ مَآ أُوتِيَ مُوسَىٰٓۚ أَوَلَمۡ يَكۡفُرُواْ بِمَآ أُوتِيَ مُوسَىٰ مِن قَبۡلُۖ قَالُواْ سِحۡرَانِ تَظَٰهَرَا وَقَالُوٓاْ إِنَّا بِكُلّٖ كَٰفِرُونَ

Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?" Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: “Òpìdán méjì t’ó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n).” Wọ́n sì tún wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn).”
Surah Al-Qasas, Verse 48


قُلۡ فَأۡتُواْ بِكِتَٰبٖ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ هُوَ أَهۡدَىٰ مِنۡهُمَآ أَتَّبِعۡهُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, t’ó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Surah Al-Qasas, Verse 49


فَإِن لَّمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَكَ فَٱعۡلَمۡ أَنَّمَا يَتَّبِعُونَ أَهۡوَآءَهُمۡۚ وَمَنۡ أَضَلُّ مِمَّنِ ٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ بِغَيۡرِ هُدٗى مِّنَ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Tí wọn kò bá jẹ́pè rẹ, mọ̀ pé wọ́n kàn ń tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni. Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni t’ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, láì sí ìmọ̀nà (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu! Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí
Surah Al-Qasas, Verse 50


۞وَلَقَدۡ وَصَّلۡنَا لَهُمُ ٱلۡقَوۡلَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ

Àti pé dájúdájú A ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí
Surah Al-Qasas, Verse 51


ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِهِۦ هُم بِهِۦ يُؤۡمِنُونَ

Àwọn tí A fún ní Tírà ṣíwájú rẹ̀, wọ́n gba al-Ƙur’ān gbọ́
Surah Al-Qasas, Verse 52


وَإِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِهِۦٓ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّنَآ إِنَّا كُنَّا مِن قَبۡلِهِۦ مُسۡلِمِينَ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.”
Surah Al-Qasas, Verse 53


أُوْلَـٰٓئِكَ يُؤۡتَوۡنَ أَجۡرَهُم مَّرَّتَيۡنِ بِمَا صَبَرُواْ وَيَدۡرَءُونَ بِٱلۡحَسَنَةِ ٱلسَّيِّئَةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn
Surah Al-Qasas, Verse 54


وَإِذَا سَمِعُواْ ٱللَّغۡوَ أَعۡرَضُواْ عَنۡهُ وَقَالُواْ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ لَا نَبۡتَغِي ٱلۡجَٰهِلِينَ

Àti pé nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ burúkú, wọ́n á ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì sọ pé: “Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kí àlàáfíà máa ba yín. A kò wá àwọn aláìmọ̀kan (ní alábàáṣepọ̀).”
Surah Al-Qasas, Verse 55


إِنَّكَ لَا تَهۡدِي مَنۡ أَحۡبَبۡتَ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يَشَآءُۚ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ

Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà
Surah Al-Qasas, Verse 56


وَقَالُوٓاْ إِن نَّتَّبِعِ ٱلۡهُدَىٰ مَعَكَ نُتَخَطَّفۡ مِنۡ أَرۡضِنَآۚ أَوَلَمۡ نُمَكِّن لَّهُمۡ حَرَمًا ءَامِنٗا يُجۡبَىٰٓ إِلَيۡهِ ثَمَرَٰتُ كُلِّ شَيۡءٖ رِّزۡقٗا مِّن لَّدُنَّا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ

Wọ́n wí pé: “Tí a bá (fi lè) tẹ̀lé ìmọ̀nà pẹ̀lú rẹ, àwọn ọ̀ṣẹbọ yóò kó wa kúrò lórí ilẹ̀ wa.” Ṣé A ò fún wọn ní ibùgbé (tí ó jẹ́) àyè ọ̀wọ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì ń kó àwọn èso gbogbo ìlú wá síbẹ̀, tí ó jẹ́ èsè láti ọ̀dọ̀ Wa? Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀
Surah Al-Qasas, Verse 57


وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةِۭ بَطِرَتۡ مَعِيشَتَهَاۖ فَتِلۡكَ مَسَٰكِنُهُمۡ لَمۡ تُسۡكَن مِّنۢ بَعۡدِهِمۡ إِلَّا قَلِيلٗاۖ وَكُنَّا نَحۡنُ ٱلۡوَٰرِثِينَ

Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún
Surah Al-Qasas, Verse 58


وَمَا كَانَ رَبُّكَ مُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ حَتَّىٰ يَبۡعَثَ فِيٓ أُمِّهَا رَسُولٗا يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَاۚ وَمَا كُنَّا مُهۡلِكِي ٱلۡقُرَىٰٓ إِلَّا وَأَهۡلُهَا ظَٰلِمُونَ

Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí
Surah Al-Qasas, Verse 59


وَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَيۡءٖ فَمَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتُهَاۚ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ

Kò sí ohun tí A fun yín bí kò ṣe nítorí ìgbádùn ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni
Surah Al-Qasas, Verse 60


أَفَمَن وَعَدۡنَٰهُ وَعۡدًا حَسَنٗا فَهُوَ لَٰقِيهِ كَمَن مَّتَّعۡنَٰهُ مَتَٰعَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا ثُمَّ هُوَ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ

Ǹjẹ́ ẹni tí A bá ṣàdéhùn ní àdéhùn t’ó dára, tí ó sì máa pàdé rẹ̀, dà bí ẹni tí A fún ní ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé bí, lẹ́yìn náà ní Ọjọ́ Àjíǹde tí ó máa wà nínú àwọn tí wọn yóò mú wá (fún ìyà Iná)
Surah Al-Qasas, Verse 61


وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ

(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
Surah Al-Qasas, Verse 62


قَالَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ رَبَّنَا هَـٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ أَغۡوَيۡنَآ أَغۡوَيۡنَٰهُمۡ كَمَا غَوَيۡنَاۖ تَبَرَّأۡنَآ إِلَيۡكَۖ مَا كَانُوٓاْ إِيَّانَا يَعۡبُدُونَ

Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí tí a kó ṣìnà, a kó wọn ṣìnà gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe ṣìnà. A yọwọ́ yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀ wọn) níwájú Rẹ (báyìí); kì í ṣe àwa ni wọ́n ń jọ́sìn fún.”
Surah Al-Qasas, Verse 63


وَقِيلَ ٱدۡعُواْ شُرَكَآءَكُمۡ فَدَعَوۡهُمۡ فَلَمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَهُمۡ وَرَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۚ لَوۡ أَنَّهُمۡ كَانُواْ يَهۡتَدُونَ

A sọ (fún wọn) pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín.” Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n)
Surah Al-Qasas, Verse 64


وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ مَاذَآ أَجَبۡتُمُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni ẹ fọ̀ ní èsì fún àwọn Òjíṣẹ́?”
Surah Al-Qasas, Verse 65


فَعَمِيَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَنۢبَآءُ يَوۡمَئِذٖ فَهُمۡ لَا يَتَسَآءَلُونَ

Èsì ọ̀rọ̀ yó sì fọ́jú pọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ yẹn; wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè
Surah Al-Qasas, Verse 66


فَأَمَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَعَسَىٰٓ أَن يَكُونَ مِنَ ٱلۡمُفۡلِحِينَ

Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ó súnmọ́ pé ó máa wà nínú àwọn olùjèrè
Surah Al-Qasas, Verse 67


وَرَبُّكَ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُ وَيَخۡتَارُۗ مَا كَانَ لَهُمُ ٱلۡخِيَرَةُۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ

Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà. Ṣíṣa ẹ̀ṣà kò tọ́ sí wọn. Mímọ́ ni fún Allāhu. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I
Surah Al-Qasas, Verse 68


وَرَبُّكَ يَعۡلَمُ مَا تُكِنُّ صُدُورُهُمۡ وَمَا يُعۡلِنُونَ

Olúwa rẹ sì mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀
Surah Al-Qasas, Verse 69


وَهُوَ ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ لَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلۡأُولَىٰ وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَلَهُ ٱلۡحُكۡمُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ

Òun sì ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. TiRẹ̀ ni ọpẹ́ ní ilé ayé yìí àti ní ọ̀run. TiRẹ̀ sì ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Al-Qasas, Verse 70


قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن جَعَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمُ ٱلَّيۡلَ سَرۡمَدًا إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِضِيَآءٍۚ أَفَلَا تَسۡمَعُونَ

Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ òru di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní ìmọ́lẹ̀? Ṣé ẹ ò gbọ́rọ̀ ni?”
Surah Al-Qasas, Verse 71


قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن جَعَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمُ ٱلنَّهَارَ سَرۡمَدًا إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِلَيۡلٖ تَسۡكُنُونَ فِيهِۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ

Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ ọ̀sán di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní alẹ́ tí ẹ óò máa sinmi nínú rẹ̀? Ṣé ẹ ò ríran ni?”
Surah Al-Qasas, Verse 72


وَمِن رَّحۡمَتِهِۦ جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ

Nínú ìkẹ́ Rẹ̀ (ni pé) Ó ṣe òru àti ọ̀sán fun yín; nítorí kí ẹ lè sinmi nínú (òru) àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀ (ní ọ̀sán) àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́
Surah Al-Qasas, Verse 73


وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ فَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ

(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
Surah Al-Qasas, Verse 74


وَنَزَعۡنَا مِن كُلِّ أُمَّةٖ شَهِيدٗا فَقُلۡنَا هَاتُواْ بُرۡهَٰنَكُمۡ فَعَلِمُوٓاْ أَنَّ ٱلۡحَقَّ لِلَّهِ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ

A sì máa mú ẹlẹ́rìí kan jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. A máa sọ pé: “Ẹ mú ìdí ọ̀rọ̀ yín wá.” Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ń jẹ́ ti Allāhu. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ yó sì dòfo mọ́ wọn lọ́wọ́
Surah Al-Qasas, Verse 75


۞إِنَّ قَٰرُونَ كَانَ مِن قَوۡمِ مُوسَىٰ فَبَغَىٰ عَلَيۡهِمۡۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡكُنُوزِ مَآ إِنَّ مَفَاتِحَهُۥ لَتَنُوٓأُ بِٱلۡعُصۡبَةِ أُوْلِي ٱلۡقُوَّةِ إِذۡ قَالَ لَهُۥ قَوۡمُهُۥ لَا تَفۡرَحۡۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡفَرِحِينَ

Dájúdájú Ƙọ̄rūn wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ṣùgbọ́n ó ṣègbéraga sí wọn. A sì fún un ní àwọn àpótí-ọrọ̀ èyí tí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ wúwo láti gbé fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn alágbára. (Rántí) nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ fún un pé: "Má ṣe yọ ayọ̀ àyọ̀jù. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn aláyọ̀jù
Surah Al-Qasas, Verse 76


وَٱبۡتَغِ فِيمَآ ءَاتَىٰكَ ٱللَّهُ ٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَۖ وَلَا تَنسَ نَصِيبَكَ مِنَ ٱلدُّنۡيَاۖ وَأَحۡسِن كَمَآ أَحۡسَنَ ٱللَّهُ إِلَيۡكَۖ وَلَا تَبۡغِ ٱلۡفَسَادَ فِي ٱلۡأَرۡضِۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُفۡسِدِينَ

Fi n̄ǹkan tí Allāhu fún ọ wá ilé Ìkẹ́yìn. Má ṣe gbàgbé ìpín rẹ ní ilé ayé. Ṣe dáadáa gẹ́gẹ́ bí Allāhu ti ṣe dáadáa fún ọ. Má sì ṣe wá ìbàjẹ́ ṣe lórí ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn òbìlẹ̀jẹ́
Surah Al-Qasas, Verse 77


قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمٍ عِندِيٓۚ أَوَلَمۡ يَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ قَدۡ أَهۡلَكَ مِن قَبۡلِهِۦ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مَنۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُ قُوَّةٗ وَأَكۡثَرُ جَمۡعٗاۚ وَلَا يُسۡـَٔلُ عَن ذُنُوبِهِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ

Ó wí pé: "Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni." Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀)
Surah Al-Qasas, Verse 78


فَخَرَجَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ فِي زِينَتِهِۦۖ قَالَ ٱلَّذِينَ يُرِيدُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا يَٰلَيۡتَ لَنَا مِثۡلَ مَآ أُوتِيَ قَٰرُونُ إِنَّهُۥ لَذُو حَظٍّ عَظِيمٖ

Ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn t’ó ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí sì wí pé: “Háà! Kí á sì ní irú ohun tí wọ́n fún Ƙọ̄rūn. Dájúdájú ó ní ìpín ńlá nínú oore.”
Surah Al-Qasas, Verse 79


وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ وَيۡلَكُمۡ ثَوَابُ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لِّمَنۡ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗاۚ وَلَا يُلَقَّىٰهَآ إِلَّا ٱلصَّـٰبِرُونَ

Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ sọ pé: “Ègbé ni fun yín! Ẹ̀san Allāhu lóore jùlọ fún ẹni t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì sí ẹni tí ó máa rí (ẹ̀san náà) gbà àfi àwọn onísùúrù.”
Surah Al-Qasas, Verse 80


فَخَسَفۡنَا بِهِۦ وَبِدَارِهِ ٱلۡأَرۡضَ فَمَا كَانَ لَهُۥ مِن فِئَةٖ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُنتَصِرِينَ

Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn t’ó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́
Surah Al-Qasas, Verse 81


وَأَصۡبَحَ ٱلَّذِينَ تَمَنَّوۡاْ مَكَانَهُۥ بِٱلۡأَمۡسِ يَقُولُونَ وَيۡكَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ وَيَقۡدِرُۖ لَوۡلَآ أَن مَّنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡنَا لَخَسَفَ بِنَاۖ وَيۡكَأَنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡكَٰفِرُونَ

Àwọn t’ó ń rankàn ipò rẹ̀ ní àná sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ṣé ẹ rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu kẹ́ wa ni, ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ gbé àwa náà mì ni. Ṣé ẹ rí i pé àwọn aláìmoore kò níí jèrè.”
Surah Al-Qasas, Verse 82


تِلۡكَ ٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ نَجۡعَلُهَا لِلَّذِينَ لَا يُرِيدُونَ عُلُوّٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فَسَادٗاۚ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلۡمُتَّقِينَ

Ilé Ìkẹ́yìn yẹn, A máa fi fún àwọn tí kò fẹ́ máa ṣe ìgbéraga àti ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
Surah Al-Qasas, Verse 83


مَن جَآءَ بِٱلۡحَسَنَةِ فَلَهُۥ خَيۡرٞ مِّنۡهَاۖ وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَلَا يُجۡزَى ٱلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ إِلَّا مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú iṣẹ́ rere wá, tirẹ̀ ni rere t’ó lóore jùlọ sí èyí t’ó mú wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wá, A ò sì níí san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san kan àfi ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Al-Qasas, Verse 84


إِنَّ ٱلَّذِي فَرَضَ عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ لَرَآدُّكَ إِلَىٰ مَعَادٖۚ قُل رَّبِّيٓ أَعۡلَمُ مَن جَآءَ بِٱلۡهُدَىٰ وَمَنۡ هُوَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ

Dájúdájú Ẹni tí Ó ṣe al-Ƙur’ān ní ọ̀ran-anyàn fún ọ, Ó sì máa dá ọ padà sí èbúté kan. Sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá àti ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
Surah Al-Qasas, Verse 85


وَمَا كُنتَ تَرۡجُوٓاْ أَن يُلۡقَىٰٓ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبُ إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۖ فَلَا تَكُونَنَّ ظَهِيرٗا لِّلۡكَٰفِرِينَ

Ìwọ kò sì retí pé A óò sọ tírà al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ (tẹ́lẹ̀), àmọ́ ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ jẹ́ alátìlẹ́yìn fún àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Al-Qasas, Verse 86


وَلَا يَصُدُّنَّكَ عَنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بَعۡدَ إِذۡ أُنزِلَتۡ إِلَيۡكَۖ وَٱدۡعُ إِلَىٰ رَبِّكَۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

Má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́ ọ lórí kúrò níbi àwọn āyah Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí A ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ. Pèpè sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah Al-Qasas, Verse 87


وَلَا تَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۘ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ كُلُّ شَيۡءٍ هَالِكٌ إِلَّا وَجۡهَهُۥۚ لَهُ ٱلۡحُكۡمُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ

Má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Gbogbo n̄ǹkan l’ó máa parun àfi Ojú Rẹ̀ (àfi Òun). TiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Al-Qasas, Verse 88


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 27
>> Surah 29

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai