Surah Aal-e-Imran Verse 49 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Aal-e-Imranوَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ أَنِّي قَدۡ جِئۡتُكُم بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ أَنِّيٓ أَخۡلُقُ لَكُم مِّنَ ٱلطِّينِ كَهَيۡـَٔةِ ٱلطَّيۡرِ فَأَنفُخُ فِيهِ فَيَكُونُ طَيۡرَۢا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُبۡرِئُ ٱلۡأَكۡمَهَ وَٱلۡأَبۡرَصَ وَأُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُنَبِّئُكُم بِمَا تَأۡكُلُونَ وَمَا تَدَّخِرُونَ فِي بُيُوتِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ
(O si je) Ojise (ti A ran nise) si awon omo ’Isro’il. (O si maa so fun won pe) "Dajudaju emi ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Dajudaju emi yoo mo nnkan fun yin lati inu amo bi irisi eye. Emi yoo fe ategun sinu re. O si maa di eye pelu iyonda Allahu. Emi yoo se iwosan fun afoju ati adete, mo si maa so oku di alaaye pelu iyonda Allahu. Emi yoo maa fun yin ni iro ohun ti e n je ati ohun ti e n fi pamo sinu ile yin. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo