UAE Prayer Times

  • Dubai
  • Abu Dhabi
  • Sharjah
  • Ajman
  • Fujairah
  • Umm Al Quwain
  • Ras Al Khaimah
  • Quran Translations

Surah Aal-e-Imran - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


الٓمٓ

’Alif lām mīm
Surah Aal-e-Imran, Verse 1


ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُ

Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 2


نَزَّلَ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَأَنزَلَ ٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ

Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo, tí ó ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà ṣíwájú rẹ̀. Ó sì sọ Taorāh àti ’Injīl kalẹ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 3


مِن قَبۡلُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَأَنزَلَ ٱلۡفُرۡقَانَۗ إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ

ní ìṣaájú. Ìmọ̀nà sì ni fún àwọn ènìyàn.1 Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ t’ó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.2 Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà t’ó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san
Surah Aal-e-Imran, Verse 4


إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَخۡفَىٰ عَلَيۡهِ شَيۡءٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ

Dájúdájú Allāhu, kò sí kiní kan t’ó pamọ́ fún Un nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 5


هُوَ ٱلَّذِي يُصَوِّرُكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ كَيۡفَ يَشَآءُۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Òun ni Ẹni tí Ó ń yàwòrán yín sínú àpòlùkẹ́ bí Ó ṣe fẹ́. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára Ọlọ́gbọ́n
Surah Aal-e-Imran, Verse 6


هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۡهُ ءَايَٰتٞ مُّحۡكَمَٰتٌ هُنَّ أُمُّ ٱلۡكِتَٰبِ وَأُخَرُ مُتَشَٰبِهَٰتٞۖ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمۡ زَيۡغٞ فَيَتَّبِعُونَ مَا تَشَٰبَهَ مِنۡهُ ٱبۡتِغَآءَ ٱلۡفِتۡنَةِ وَٱبۡتِغَآءَ تَأۡوِيلِهِۦۖ وَمَا يَعۡلَمُ تَأۡوِيلَهُۥٓ إِلَّا ٱللَّهُۗ وَٱلرَّـٰسِخُونَ فِي ٱلۡعِلۡمِ يَقُولُونَ ءَامَنَّا بِهِۦ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ رَبِّنَاۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ

Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè. kò sí āyah tàbí hadith kan tí ó ní pọ́n-na tí ìtakora wọn wá wọ ipò “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀” (at-ta‘ārudu al-haƙīƙiy). Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’
Surah Aal-e-Imran, Verse 7


رَبَّنَا لَا تُزِغۡ قُلُوبَنَا بَعۡدَ إِذۡ هَدَيۡتَنَا وَهَبۡ لَنَا مِن لَّدُنكَ رَحۡمَةًۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡوَهَّابُ

Olúwa wa, má ṣe yí wa lọ́kàn padà lẹ́yìn tí O ti tọ́ wa sọ́nà. Ta wá lọ́rẹ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, dájúdájú Ìwọ ni Ọlọ́rẹ
Surah Aal-e-Imran, Verse 8


رَبَّنَآ إِنَّكَ جَامِعُ ٱلنَّاسِ لِيَوۡمٖ لَّا رَيۡبَ فِيهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخۡلِفُ ٱلۡمِيعَادَ

Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O máa kó àwọn ènìyàn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kì í yẹ àdéhùn
Surah Aal-e-Imran, Verse 9


إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡـٔٗاۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمۡ وَقُودُ ٱلنَّارِ

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná
Surah Aal-e-Imran, Verse 10


كَدَأۡبِ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡۗ وَٱللَّهُ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ

(Ìṣesí wọn) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Allāhu sì le níbi ìyà
Surah Aal-e-Imran, Verse 11


قُل لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ سَتُغۡلَبُونَ وَتُحۡشَرُونَ إِلَىٰ جَهَنَّمَۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ

Sọ fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Wọ́n máa ṣẹ́gun yín. Wọ́n sì máa ko yín jọ sínú iná Jahanamọ. Ibùgbé náà sì burú
Surah Aal-e-Imran, Verse 12


قَدۡ كَانَ لَكُمۡ ءَايَةٞ فِي فِئَتَيۡنِ ٱلۡتَقَتَاۖ فِئَةٞ تُقَٰتِلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَأُخۡرَىٰ كَافِرَةٞ يَرَوۡنَهُم مِّثۡلَيۡهِمۡ رَأۡيَ ٱلۡعَيۡنِۚ وَٱللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصۡرِهِۦ مَن يَشَآءُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ

Àmì kúkú wà fun yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn). Ìjọ kan ń jà fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Ìkejì sì jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìjọ kejì ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú. Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùrìran
Surah Aal-e-Imran, Verse 13


زُيِّنَ لِلنَّاسِ حُبُّ ٱلشَّهَوَٰتِ مِنَ ٱلنِّسَآءِ وَٱلۡبَنِينَ وَٱلۡقَنَٰطِيرِ ٱلۡمُقَنطَرَةِ مِنَ ٱلذَّهَبِ وَٱلۡفِضَّةِ وَٱلۡخَيۡلِ ٱلۡمُسَوَّمَةِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ وَٱلۡحَرۡثِۗ ذَٰلِكَ مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَٱللَّهُ عِندَهُۥ حُسۡنُ ٱلۡمَـَٔابِ

Wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn ènìyàn; ìfẹ́ ìgbádùn lára àwọn obìnrin, àwọn ọmọkùnrin, àwọn owó wúrà àti fàdákà púpọ̀ àti àwọn ẹṣin tí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́, àwọn ẹran-ọ̀sìn àti (n̄ǹkan) oko. Ìyẹn ni n̄ǹkan ìgbáyé-gbádùn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ rere wà
Surah Aal-e-Imran, Verse 14


۞قُلۡ أَؤُنَبِّئُكُم بِخَيۡرٖ مِّن ذَٰلِكُمۡۖ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ عِندَ رَبِّهِمۡ جَنَّـٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَأَزۡوَٰجٞ مُّطَهَّرَةٞ وَرِضۡوَٰنٞ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ

Sọ pé: “Ṣé kí n̄g sọ n̄ǹkan t’ó dára ju ìyẹn lọ fun yín?” Àwọn t’ó bá bẹ̀rù (Allāhu), àwọn Ọgbà tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn ìyàwó mímọ́ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu (tún ń bẹ fún wọn). Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn
Surah Aal-e-Imran, Verse 15


ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ إِنَّنَآ ءَامَنَّا فَٱغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَا وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ

àwọn t’ó ń sọ pé: "Olúwa wa, dájúdájú àwa gbàgbọ́. Nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá. Kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná
Surah Aal-e-Imran, Verse 16


ٱلصَّـٰبِرِينَ وَٱلصَّـٰدِقِينَ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡمُنفِقِينَ وَٱلۡمُسۡتَغۡفِرِينَ بِٱلۡأَسۡحَارِ

(Ọgbà Ìdẹ̀ra yẹn wà fún) àwọn onísùúrù, àwọn olódodo, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu, àwọn olùnáwó-fẹ́sìn àti àwọn olùtọrọ-àforíjìn ní àsìkò sààrì
Surah Aal-e-Imran, Verse 17


شَهِدَ ٱللَّهُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَأُوْلُواْ ٱلۡعِلۡمِ قَآئِمَۢا بِٱلۡقِسۡطِۚ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Allāhu jẹ́rìí pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Àwọn mọlāika àti onímọ̀ ẹ̀sìn (tún jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.), Allāhu ni Onídéédé. Kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Aal-e-Imran, Verse 18


إِنَّ ٱلدِّينَ عِندَ ٱللَّهِ ٱلۡإِسۡلَٰمُۗ وَمَا ٱخۡتَلَفَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۗ وَمَن يَكۡفُرۡ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَإِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ

Dájúdájú ẹ̀sìn t’ó wà lọ́dọ̀ Allāhu ni ’Islām. Àwọn tí A fún ní Tírà (àwọn yẹhudi àti kristiẹni) kò yapa ẹnu (sí ẹ̀sìn náà) àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ dé bá wọn. (Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀) nípasẹ̀ ọ̀tẹ̀ ààrin wọn (sí àwọn Ànábì). Ẹni t’ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 19


فَإِنۡ حَآجُّوكَ فَقُلۡ أَسۡلَمۡتُ وَجۡهِيَ لِلَّهِ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِۗ وَقُل لِّلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡأُمِّيِّـۧنَ ءَأَسۡلَمۡتُمۡۚ فَإِنۡ أَسۡلَمُواْ فَقَدِ ٱهۡتَدَواْۖ وَّإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا عَلَيۡكَ ٱلۡبَلَٰغُۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ

Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ pé: “Èmi àti ẹni tí ó tẹ̀lé mi juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu.” Kí o sì sọ fún àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) pé: “Ṣé ẹ máa gba ’Islām?” Tí wọ́n bá gba ’Islām, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì kẹ̀yìn (sí ’Islām), iṣẹ́-jíjẹ́ nìkan ni ojúṣe tìrẹ. Allāhu sì ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn
Surah Aal-e-Imran, Verse 20


إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَيَقۡتُلُونَ ٱلَّذِينَ يَأۡمُرُونَ بِٱلۡقِسۡطِ مِنَ ٱلنَّاسِ فَبَشِّرۡهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ

Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́, tí wọ́n tún ń pa àwọn ènìyàn tí ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro
Surah Aal-e-Imran, Verse 21


أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ilé ayé àti ní ọ̀run. Wọn kò sì níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 22


أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يُدۡعَوۡنَ إِلَىٰ كِتَٰبِ ٱللَّهِ لِيَحۡكُمَ بَيۡنَهُمۡ ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ وَهُم مُّعۡرِضُونَ

Ṣé o ò rí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú Tírà, tí À ń pè síbi Tírà Allāhu, kí ó lè ṣe ìdájọ́ láààrin wọn, lẹ́yìn náà tí ìjọ kan nínú wọn ń pẹ̀yìn dà, tí wọ́n sì ń gbúnrí
Surah Aal-e-Imran, Verse 23


ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۖ وَغَرَّهُمۡ فِي دِينِهِم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ

Ìyẹn nítorí pé dájúdájú wọ́n wí pé: “Iná kò lè jó wa tayọ àwọn ọjọ́ t’ó lóǹkà.” Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì tàn wọ́n jẹ nínú ẹ̀sìn wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 24


فَكَيۡفَ إِذَا جَمَعۡنَٰهُمۡ لِيَوۡمٖ لَّا رَيۡبَ فِيهِ وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ

Nítorí náà, báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí A bá kó wọn jọ ní ọjọ́ kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀? Àti pé A máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 25


قُلِ ٱللَّهُمَّ مَٰلِكَ ٱلۡمُلۡكِ تُؤۡتِي ٱلۡمُلۡكَ مَن تَشَآءُ وَتَنزِعُ ٱلۡمُلۡكَ مِمَّن تَشَآءُ وَتُعِزُّ مَن تَشَآءُ وَتُذِلُّ مَن تَشَآءُۖ بِيَدِكَ ٱلۡخَيۡرُۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ

Sọ pé: “Allāhu, Olùkápá ìjọba, Ò ń fi ìjọba fún ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń gba ìjọba lọ́wọ́ ẹni tí O bá fẹ́. Ò ń buyì kún ẹni tí O bá fẹ́. O sì ń tàbùkù ẹni tí O bá fẹ́. Ọwọ́ Rẹ ni oore wà. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbárá lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Aal-e-Imran, Verse 26


تُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَتُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِۖ وَتُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَتُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّۖ وَتَرۡزُقُ مَن تَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ

Ò ń mú òru wọnú ọ̀sán. Ò ń mú ọ̀sán wọnú òru. Ò ń mú alààyè jáde lára òkú. Ò ń mú òkú jáde lára alààyè. O sì ń ṣe arísìkí fún ẹni tí O bá fẹ́ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 27


لَّا يَتَّخِذِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَلَيۡسَ مِنَ ٱللَّهِ فِي شَيۡءٍ إِلَّآ أَن تَتَّقُواْ مِنۡهُمۡ تُقَىٰةٗۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ

Kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Àfi (tí ẹ bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ lórí ahọ́n) láti fi ṣọ́ra fún wọn ní ti wíwá ààbò (fún ìgbàgbọ́ yín). Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fun yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 28


قُلۡ إِن تُخۡفُواْ مَا فِي صُدُورِكُمۡ أَوۡ تُبۡدُوهُ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ

Sọ pé: “Tí ẹ bá fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín pamọ́ tàbí ẹ fi hàn, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ó sì mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Aal-e-Imran, Verse 29


يَوۡمَ تَجِدُ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ مِنۡ خَيۡرٖ مُّحۡضَرٗا وَمَا عَمِلَتۡ مِن سُوٓءٖ تَوَدُّ لَوۡ أَنَّ بَيۡنَهَا وَبَيۡنَهُۥٓ أَمَدَۢا بَعِيدٗاۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَٱللَّهُ رَءُوفُۢ بِٱلۡعِبَادِ

Ní ọjọ́ tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò rí ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ rere níwájú (rẹ̀) àti ohun tí ó ṣe nínú iṣẹ́ ibi, ó máa fẹ́ kí àkókò t’ó jìnnà wà láààrin òun àti iṣẹ́ ibi rẹ̀. Allāhu sì ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fun yín. Allāhu sì ni Aláàánú àwọn olùjọ́sìn
Surah Aal-e-Imran, Verse 30


قُلۡ إِن كُنتُمۡ تُحِبُّونَ ٱللَّهَ فَٱتَّبِعُونِي يُحۡبِبۡكُمُ ٱللَّهُ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡ ذُنُوبَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Sọ pé: “Tí ẹ̀yin bá nífẹ̀ẹ́ Allāhu, ẹ tẹ̀lé mi, Allāhu máa nífẹ̀ẹ́ yín, Ó sì máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Aal-e-Imran, Verse 31


قُلۡ أَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَۖ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Sọ pé: “Ẹ tẹ̀lé (ti) Allāhu àti Òjíṣẹ́. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 32


۞إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰٓ ءَادَمَ وَنُوحٗا وَءَالَ إِبۡرَٰهِيمَ وَءَالَ عِمۡرَٰنَ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ

Dájúdájú Allāhu ṣa Ādam, Nūh, ará ilé ’Ibrọ̄hīm àti ará ilé ‘Imrọ̄n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn)
Surah Aal-e-Imran, Verse 33


ذُرِّيَّةَۢ بَعۡضُهَا مِنۢ بَعۡضٖۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

Wọ́n jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ; apá kan wọn wá láti ara apá kan. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 34


إِذۡ قَالَتِ ٱمۡرَأَتُ عِمۡرَٰنَ رَبِّ إِنِّي نَذَرۡتُ لَكَ مَا فِي بَطۡنِي مُحَرَّرٗا فَتَقَبَّلۡ مِنِّيٓۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ

(Ẹ rántí) nígbà tí aya ‘Imrọ̄n sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi fi ohun tí ń bẹ nínú mi jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọ (pé) mo máa yà á sọ́tọ̀ (fún ẹ̀sìn Rẹ). Nítorí náà, gbà á lọ́wọ́ mi, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 35


فَلَمَّا وَضَعَتۡهَا قَالَتۡ رَبِّ إِنِّي وَضَعۡتُهَآ أُنثَىٰ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا وَضَعَتۡ وَلَيۡسَ ٱلذَّكَرُ كَٱلۡأُنثَىٰۖ وَإِنِّي سَمَّيۡتُهَا مَرۡيَمَ وَإِنِّيٓ أُعِيذُهَا بِكَ وَذُرِّيَّتَهَا مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ ٱلرَّجِيمِ

Nígbà tí ó bí i, ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú mo bí i ní obìnrin - Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ó bí – ọkùnrin kò sì dà bí obìnrin. Dájúdájú èmi sọ ọ́ ní Mọryam. Àti pé dájúdájú mò ń fi Ọ́ wá ààbò fún òun àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ lọ́dọ̀ Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 36


فَتَقَبَّلَهَا رَبُّهَا بِقَبُولٍ حَسَنٖ وَأَنۢبَتَهَا نَبَاتًا حَسَنٗا وَكَفَّلَهَا زَكَرِيَّاۖ كُلَّمَا دَخَلَ عَلَيۡهَا زَكَرِيَّا ٱلۡمِحۡرَابَ وَجَدَ عِندَهَا رِزۡقٗاۖ قَالَ يَٰمَرۡيَمُ أَنَّىٰ لَكِ هَٰذَاۖ قَالَتۡ هُوَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٍ

Olúwa rẹ̀ sì gba àdúà náà ní gbígbà dáadáa. Ó sì mú ọmọ náà dàgbà ní ìdàgbà dáadáa. Ó sì fi Zakariyyā ṣe alágbàtọ́ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí Zakariyyā bá wọlé tọ̀ ọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, ó máa bá èsè (èso) lọ́dọ̀ rẹ̀. (Zakariyyā á) sọ pé: “Mọryam, báwo ni èyí ṣe jẹ́ tìrẹ?” (Mọryam á) sọ pé: "Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 37


هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُۥۖ قَالَ رَبِّ هَبۡ لِي مِن لَّدُنكَ ذُرِّيَّةٗ طَيِّبَةًۖ إِنَّكَ سَمِيعُ ٱلدُّعَآءِ

Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́ àdúà
Surah Aal-e-Imran, Verse 38


فَنَادَتۡهُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَهُوَ قَآئِمٞ يُصَلِّي فِي ٱلۡمِحۡرَابِ أَنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحۡيَىٰ مُصَدِّقَۢا بِكَلِمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَسَيِّدٗا وَحَصُورٗا وَنَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): "Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu. (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò sì níí súnmọ́ obìnrin. (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 39


قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَقَدۡ بَلَغَنِيَ ٱلۡكِبَرُ وَٱمۡرَأَتِي عَاقِرٞۖ قَالَ كَذَٰلِكَ ٱللَّهُ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ

(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 40


قَالَ رَبِّ ٱجۡعَل لِّيٓ ءَايَةٗۖ قَالَ ءَايَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ ٱلنَّاسَ ثَلَٰثَةَ أَيَّامٍ إِلَّا رَمۡزٗاۗ وَٱذۡكُر رَّبَّكَ كَثِيرٗا وَسَبِّحۡ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ

(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé ìwọ kò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àyàfi títọ́ka (sí n̄ǹkan). Rántí Olúwa rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Kí o sì ṣàfọ̀mọ́ (fún Un) ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtù
Surah Aal-e-Imran, Verse 41


وَإِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰكِ وَطَهَّرَكِ وَٱصۡطَفَىٰكِ عَلَىٰ نِسَآءِ ٱلۡعَٰلَمِينَ

(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ)
Surah Aal-e-Imran, Verse 42


يَٰمَرۡيَمُ ٱقۡنُتِي لِرَبِّكِ وَٱسۡجُدِي وَٱرۡكَعِي مَعَ ٱلرَّـٰكِعِينَ

Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́ tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun)
Surah Aal-e-Imran, Verse 43


ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۚ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يُلۡقُونَ أَقۡلَٰمَهُمۡ أَيُّهُمۡ يَكۡفُلُ مَرۡيَمَ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ

Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò. Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfan̄fà (lórí rẹ̀)
Surah Aal-e-Imran, Verse 44


إِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكِ بِكَلِمَةٖ مِّنۡهُ ٱسۡمُهُ ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ وَجِيهٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمِنَ ٱلۡمُقَرَّبِينَ

(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: "Mọryam, dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa dídá ẹ̀dá kan pẹ̀lú) ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Abiyì ni ní ayé àti ní ọ̀run. Ó sì wà lára alásùn-únmọ́ (Allāhu). nínú āyah ti āli ‘Imrọ̄n Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa bí àwọn mọlā’ikah ṣe wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbi ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àwọn mọlāika t’ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà ju ẹyọ kan lọ. Ìdí nìyí tí “mọlā’ikah” fi jẹ́ ọ̀pọ̀ nínú āyah yẹn. Àmọ́ nínú āyah ti Mọryam
Surah Aal-e-Imran, Verse 45


وَيُكَلِّمُ ٱلنَّاسَ فِي ٱلۡمَهۡدِ وَكَهۡلٗا وَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Ó máa bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà t’ó bá dàgbà. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 46


قَالَتۡ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي وَلَدٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞۖ قَالَ كَذَٰلِكِ ٱللَّهُ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ إِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

(Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 47


وَيُعَلِّمُهُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَٱلتَّوۡرَىٰةَ وَٱلۡإِنجِيلَ

(Allāhu) yóò fún un ní ìmọ̀ ìkọ̀wé, ìjìnlẹ̀ òye, Taorāh àti ’Injīl
Surah Aal-e-Imran, Verse 48


وَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ أَنِّي قَدۡ جِئۡتُكُم بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ أَنِّيٓ أَخۡلُقُ لَكُم مِّنَ ٱلطِّينِ كَهَيۡـَٔةِ ٱلطَّيۡرِ فَأَنفُخُ فِيهِ فَيَكُونُ طَيۡرَۢا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُبۡرِئُ ٱلۡأَكۡمَهَ وَٱلۡأَبۡرَصَ وَأُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۖ وَأُنَبِّئُكُم بِمَا تَأۡكُلُونَ وَمَا تَدَّخِرُونَ فِي بُيُوتِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ

(Ó sì jẹ́) Òjíṣẹ́ (tí A rán níṣẹ́) sí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (Ó sì máa sọ fún wọn pé) "Dájúdájú èmi ti mú àmì kan wá fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Dájúdájú èmi yóò mọ n̄ǹkan fun yín láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ. Èmi yóò fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀. Ó sì máa di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti adẹ́tẹ̀, mo sì máa sọ òkú di alààyè pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Èmi yóò máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ sínú ilé yín. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fun yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
Surah Aal-e-Imran, Verse 49


وَمُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيَّ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَلِأُحِلَّ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي حُرِّمَ عَلَيۡكُمۡۚ وَجِئۡتُكُم بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ

Mo sì ń fi ohun t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó ṣíwájú mi nínú Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe ní ẹ̀tọ́ fun yín apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fun yín. Mo ti mú àmì kan wá fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi
Surah Aal-e-Imran, Verse 50


إِنَّ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ

Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà
Surah Aal-e-Imran, Verse 51


۞فَلَمَّآ أَحَسَّ عِيسَىٰ مِنۡهُمُ ٱلۡكُفۡرَ قَالَ مَنۡ أَنصَارِيٓ إِلَى ٱللَّهِۖ قَالَ ٱلۡحَوَارِيُّونَ نَحۡنُ أَنصَارُ ٱللَّهِ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَٱشۡهَدۡ بِأَنَّا مُسۡلِمُونَ

Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: "Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá
Surah Aal-e-Imran, Verse 52


رَبَّنَآ ءَامَنَّا بِمَآ أَنزَلۡتَ وَٱتَّبَعۡنَا ٱلرَّسُولَ فَٱكۡتُبۡنَا مَعَ ٱلشَّـٰهِدِينَ

Olúwa wa, a gbàgbọ́ nínú ohun tí O sọ̀kalẹ̀. A sì tẹ̀lé Òjíṣẹ́. Nítorí náà, kọ wá mọ́ àwọn olùjẹ́rìí
Surah Aal-e-Imran, Verse 53


وَمَكَرُواْ وَمَكَرَ ٱللَّهُۖ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلۡمَٰكِرِينَ

Wọ́n déte, Allāhu sì déte. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn adéte
Surah Aal-e-Imran, Verse 54


إِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَىٰٓ إِنِّي مُتَوَفِّيكَ وَرَافِعُكَ إِلَيَّ وَمُطَهِّرُكَ مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَجَاعِلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوكَ فَوۡقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ ثُمَّ إِلَيَّ مَرۡجِعُكُمۡ فَأَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ فِيمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ

Wafāt/wafāh sì túmọ̀ sí ""ƙọbd"" gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n 3:55 ati sūrah al-Mọ̄’dah ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn t’ó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àti ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti ọ̀wọ́ àwọn t’ó tẹ̀lé e lójú ayé rẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pera wọn bẹ́ẹ̀ nínú sūrah yìí
Surah Aal-e-Imran, Verse 55


فَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَأُعَذِّبُهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò jẹ wọ́n níyà líle ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 56


وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فَيُوَفِّيهِمۡ أُجُورَهُمۡۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní kíkún. Allāhu kò sì fẹ́ràn àwọn alábòsí
Surah Aal-e-Imran, Verse 57


ذَٰلِكَ نَتۡلُوهُ عَلَيۡكَ مِنَ ٱلۡأٓيَٰتِ وَٱلذِّكۡرِ ٱلۡحَكِيمِ

Ìyẹn ni À ń ké fún ọ nínú àwọn āyah àti ìrántí tí ó kún fún ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān)
Surah Aal-e-Imran, Verse 58


إِنَّ مَثَلَ عِيسَىٰ عِندَ ٱللَّهِ كَمَثَلِ ءَادَمَۖ خَلَقَهُۥ مِن تُرَابٖ ثُمَّ قَالَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ

Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀. ẹrú Ọlọ́hun àti Ànábì Ọlọ́hun. Àmọ́ sísọ tí àwọn kristiẹni sọ Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa wọn olùgbàlà wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 59


ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُن مِّنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ

Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, má ṣe wà nínú àwọn oníyèméjì
Surah Aal-e-Imran, Verse 60


فَمَنۡ حَآجَّكَ فِيهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ فَقُلۡ تَعَالَوۡاْ نَدۡعُ أَبۡنَآءَنَا وَأَبۡنَآءَكُمۡ وَنِسَآءَنَا وَنِسَآءَكُمۡ وَأَنفُسَنَا وَأَنفُسَكُمۡ ثُمَّ نَبۡتَهِلۡ فَنَجۡعَل لَّعۡنَتَ ٱللَّهِ عَلَى ٱلۡكَٰذِبِينَ

Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: “Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣe àdúà taratara, kí á sì tọrọ ègún Allāhu lé àwọn òpùrọ́ lórí.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 61


إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡقَصَصُ ٱلۡحَقُّۚ وَمَا مِنۡ إِلَٰهٍ إِلَّا ٱللَّهُۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Dájúdájú èyí, òhun ni ìtàn òdodo. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Aal-e-Imran, Verse 62


فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِٱلۡمُفۡسِدِينَ

Tí wọ́n bá sì pẹ̀yìn dà (níbi òdodo náà), dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 63


قُلۡ يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ تَعَالَوۡاْ إِلَىٰ كَلِمَةٖ سَوَآءِۭ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمۡ أَلَّا نَعۡبُدَ إِلَّا ٱللَّهَ وَلَا نُشۡرِكَ بِهِۦ شَيۡـٔٗا وَلَا يَتَّخِذَ بَعۡضُنَا بَعۡضًا أَرۡبَابٗا مِّن دُونِ ٱللَّهِۚ فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقُولُواْ ٱشۡهَدُواْ بِأَنَّا مُسۡلِمُونَ

Sọ pé: “Ẹ̀yin ahlu-l-kitāb, ẹ wá síbi ọ̀rọ̀ kan t’ó dọ́gba láààrin àwa àti ẹ̀yin, pé a ò níí jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. A ò sì níí fi kiní kan wá akẹgbẹ́ fún Un. Àti pé apá kan wa kò níí sọ apá kan di olúwa lẹ́yìn Allāhu.” Tí wọ́n bá sì gbúnrí, ẹ sọ pé: “Ẹ jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni àwa.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 64


يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لِمَ تُحَآجُّونَ فِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمَآ أُنزِلَتِ ٱلتَّوۡرَىٰةُ وَٱلۡإِنجِيلُ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِهِۦٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ

Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi jiyàn nípa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm? A kò sì sọ at-Taorāh àti al-’Injīl kalẹ̀ bí kò ṣe lẹ́yìn rẹ̀, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni
Surah Aal-e-Imran, Verse 65


هَـٰٓأَنتُمۡ هَـٰٓؤُلَآءِ حَٰجَجۡتُمۡ فِيمَا لَكُم بِهِۦ عِلۡمٞ فَلِمَ تُحَآجُّونَ فِيمَا لَيۡسَ لَكُم بِهِۦ عِلۡمٞۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ

Ẹ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀? Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 66


مَا كَانَ إِبۡرَٰهِيمُ يَهُودِيّٗا وَلَا نَصۡرَانِيّٗا وَلَٰكِن كَانَ حَنِيفٗا مُّسۡلِمٗا وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm kì í ṣe yẹhudi, kì í ṣe kristiẹni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùdúró-déédé, mùsùlùmí. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah Aal-e-Imran, Verse 67


إِنَّ أَوۡلَى ٱلنَّاسِ بِإِبۡرَٰهِيمَ لَلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ وَهَٰذَا ٱلنَّبِيُّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۗ وَٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àwọn ènìyàn t’ó súnmọ́ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jùlọ ni àwọn t’ó tẹ̀lé e àti Ànábì yìí (Ànábì Muhammad s.a.w.) àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Allāhu ni Alátìlẹ́yìn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Aal-e-Imran, Verse 68


وَدَّت طَّآئِفَةٞ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَوۡ يُضِلُّونَكُمۡ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡ وَمَا يَشۡعُرُونَ

Igun kan nínú àwọn ahlul-kitāb fẹ́ láti ṣì yín lọ́nà. Wọn kò lè ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àfi ara wọn, wọn kò sì fura
Surah Aal-e-Imran, Verse 69


يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لِمَ تَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَأَنتُمۡ تَشۡهَدُونَ

Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ẹ sì ń jẹ́rìí (sí òdodo rẹ̀)
Surah Aal-e-Imran, Verse 70


يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لِمَ تَلۡبِسُونَ ٱلۡحَقَّ بِٱلۡبَٰطِلِ وَتَكۡتُمُونَ ٱلۡحَقَّ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ

Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì ń fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo)
Surah Aal-e-Imran, Verse 71


وَقَالَت طَّآئِفَةٞ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ ءَامِنُواْ بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَجۡهَ ٱلنَّهَارِ وَٱكۡفُرُوٓاْ ءَاخِرَهُۥ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ

Igun kan nínú àwọn ahlul-kitāb wí pé: “Ẹ lọ gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kí ẹ sì takò ó níparí rẹ̀, bóyá àwọn mùsùlùmí (kan) máa ṣẹ́rí padà (sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn ’Islām)
Surah Aal-e-Imran, Verse 72


وَلَا تُؤۡمِنُوٓاْ إِلَّا لِمَن تَبِعَ دِينَكُمۡ قُلۡ إِنَّ ٱلۡهُدَىٰ هُدَى ٱللَّهِ أَن يُؤۡتَىٰٓ أَحَدٞ مِّثۡلَ مَآ أُوتِيتُمۡ أَوۡ يُحَآجُّوكُمۡ عِندَ رَبِّكُمۡۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡفَضۡلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ

(Wọ́n tún wí pé:) “Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà (’Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu.” (Wọ́n tún wí pé:) “(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí Wọ́n fun yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín.” Sọ pé: “Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 73


يَخۡتَصُّ بِرَحۡمَتِهِۦ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ

(Allāhu) ń ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu ni Olóore ńlá
Surah Aal-e-Imran, Verse 74


۞وَمِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مَنۡ إِن تَأۡمَنۡهُ بِقِنطَارٖ يُؤَدِّهِۦٓ إِلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّنۡ إِن تَأۡمَنۡهُ بِدِينَارٖ لَّا يُؤَدِّهِۦٓ إِلَيۡكَ إِلَّا مَا دُمۡتَ عَلَيۡهِ قَآئِمٗاۗ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لَيۡسَ عَلَيۡنَا فِي ٱلۡأُمِّيِّـۧنَ سَبِيلٞ وَيَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ

Ó ń bẹ nínú àwọn ahlul-kitāb, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: “Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà.” Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 75


بَلَىٰۚ مَنۡ أَوۡفَىٰ بِعَهۡدِهِۦ وَٱتَّقَىٰ فَإِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُتَّقِينَ

Rárá (A máa bá wọn wí). Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)
Surah Aal-e-Imran, Verse 76


إِنَّ ٱلَّذِينَ يَشۡتَرُونَ بِعَهۡدِ ٱللَّهِ وَأَيۡمَٰنِهِمۡ ثَمَنٗا قَلِيلًا أُوْلَـٰٓئِكَ لَا خَلَٰقَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ ٱللَّهُ وَلَا يَنظُرُ إِلَيۡهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Dájúdájú àwọn t’ó ń ta májẹ̀mu Allāhu àti ìbúra wọn ní owó kékeré, àwọn wọ̀nyẹn, kò níí sí ìpín oore fún wọn ní Ọjọ́ Ìkẹyìn. Allāhu kò níí bá wọn sọ̀rọ̀, kò sì níí ṣíjú wò wọ́n ní Ọjọ́ Àjíǹde. Kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì ń bẹ fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 77


وَإِنَّ مِنۡهُمۡ لَفَرِيقٗا يَلۡوُۥنَ أَلۡسِنَتَهُم بِٱلۡكِتَٰبِ لِتَحۡسَبُوهُ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَمَا هُوَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَيَقُولُونَ هُوَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ وَمَا هُوَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَيَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ

Dájúdájú ìjọ kan ń bẹ nínú wọn t’ó ń fi ahọ́n wọn yí tírà (Allāhu) padà, nítorí kí ẹ lè lérò pé lára tírà ló wà, kò sì sí lára tírà. Wọ́n sì ń wí pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kò sì wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n ń parọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 78


مَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُؤۡتِيَهُ ٱللَّهُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحُكۡمَ وَٱلنُّبُوَّةَ ثُمَّ يَقُولَ لِلنَّاسِ كُونُواْ عِبَادٗا لِّي مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِن كُونُواْ رَبَّـٰنِيِّـۧنَ بِمَا كُنتُمۡ تُعَلِّمُونَ ٱلۡكِتَٰبَ وَبِمَا كُنتُمۡ تَدۡرُسُونَ

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan nígbà tí Allāhu bá fún un ní tírà, ìjìnlẹ̀ òye àti ipò Ànábì, lẹ́yìn náà kí ó máa sọ fún àwọn ènìyàn pé, "ẹ jẹ́ ẹrúsìn fún mi lẹ́yìn Allāhu." Ṣùgbọ́n (ó máa sọ pé) "ẹ jẹ́ olùjọ́sìn fún Olúwa (kí ẹ sì máa fi ẹ̀kọ́ Rẹ̀ kọ́ àwọn ènìyàn) nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tírà àti nítorí pé ẹ jẹ́ ẹni tí ń kọ́ ẹ̀kọ́ (nípa ẹ̀sìn)
Surah Aal-e-Imran, Verse 79


وَلَا يَأۡمُرَكُمۡ أَن تَتَّخِذُواْ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ أَرۡبَابًاۚ أَيَأۡمُرُكُم بِٱلۡكُفۡرِ بَعۡدَ إِذۡ أَنتُم مُّسۡلِمُونَ

(Ànábì kan) kò sì níí pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ sọ àwọn mọlāika àti àwọn Ànábì di olúwa. Ṣé ó máa pa yín ní àṣẹ ṣíṣe àìgbàgbọ́ lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ́ mùsùlùmí ni
Surah Aal-e-Imran, Verse 80


وَإِذۡ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ لَمَآ ءَاتَيۡتُكُم مِّن كِتَٰبٖ وَحِكۡمَةٖ ثُمَّ جَآءَكُمۡ رَسُولٞ مُّصَدِّقٞ لِّمَا مَعَكُمۡ لَتُؤۡمِنُنَّ بِهِۦ وَلَتَنصُرُنَّهُۥۚ قَالَ ءَأَقۡرَرۡتُمۡ وَأَخَذۡتُمۡ عَلَىٰ ذَٰلِكُمۡ إِصۡرِيۖ قَالُوٓاْ أَقۡرَرۡنَاۚ قَالَ فَٱشۡهَدُواْ وَأَنَا۠ مَعَكُم مِّنَ ٱلشَّـٰهِدِينَ

(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì pé: “(Ẹ lo) èyí tí Mo bá fun yín nínú Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad s.a.w.) yóò dé ba yín; ó máa fi èyí t’ó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí t’ó wà pẹ̀lú yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí
Surah Aal-e-Imran, Verse 81


فَمَن تَوَلَّىٰ بَعۡدَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ

Nítorí náà, ẹni tí ó bá kẹ̀yìn sí (Ànábì Muhammad s.a.w.) lẹ́yìn (àdéhùn) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 82


أَفَغَيۡرَ دِينِ ٱللَّهِ يَبۡغُونَ وَلَهُۥٓ أَسۡلَمَ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ طَوۡعٗا وَكَرۡهٗا وَإِلَيۡهِ يُرۡجَعُونَ

Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí
Surah Aal-e-Imran, Verse 83


قُلۡ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا وَمَآ أُنزِلَ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَمَآ أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَٱلنَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمۡ لَا نُفَرِّقُ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّنۡهُمۡ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ

Sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa pẹ̀lú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 84


وَمَن يَبۡتَغِ غَيۡرَ ٱلۡإِسۡلَٰمِ دِينٗا فَلَن يُقۡبَلَ مِنۡهُ وَهُوَ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ

Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá ẹ̀sìn kan ṣe yàtọ̀ sí ’Islām, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò
Surah Aal-e-Imran, Verse 85


كَيۡفَ يَهۡدِي ٱللَّهُ قَوۡمٗا كَفَرُواْ بَعۡدَ إِيمَٰنِهِمۡ وَشَهِدُوٓاْ أَنَّ ٱلرَّسُولَ حَقّٞ وَجَآءَهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Báwo ni Allāhu yó ṣe fi ọ̀nà mọ ìjọ kan t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn? Wọ́n sì jẹ́rìí pé dájúdájú Òjíṣẹ́ náà, òdodo ni. Àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú sì ti dé bá wọn. Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí
Surah Aal-e-Imran, Verse 86


أُوْلَـٰٓئِكَ جَزَآؤُهُمۡ أَنَّ عَلَيۡهِمۡ لَعۡنَةَ ٱللَّهِ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ

Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn ni pé, dájúdájú ègún Allāhu àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) gbogbo àwọn ènìyàn ń bẹ lórí wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 87


خَٰلِدِينَ فِيهَا لَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ

Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí gbé ìyà fúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná)
Surah Aal-e-Imran, Verse 88


إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ وَأَصۡلَحُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ

Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà lẹ́yìn ìyẹn, tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe, nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Aal-e-Imran, Verse 89


إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَعۡدَ إِيمَٰنِهِمۡ ثُمَّ ٱزۡدَادُواْ كُفۡرٗا لَّن تُقۡبَلَ تَوۡبَتُهُمۡ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلضَّآلُّونَ

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ wọn, lẹ́yìn náà, wọ́n lékún ní àìgbàgbọ́, A ò níí gba ìronúpìwàdà wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni olùṣìnà
Surah Aal-e-Imran, Verse 90


إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَمَاتُواْ وَهُمۡ كُفَّارٞ فَلَن يُقۡبَلَ مِنۡ أَحَدِهِم مِّلۡءُ ٱلۡأَرۡضِ ذَهَبٗا وَلَوِ ٱفۡتَدَىٰ بِهِۦٓۗ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 91


لَن تَنَالُواْ ٱلۡبِرَّ حَتَّىٰ تُنفِقُواْ مِمَّا تُحِبُّونَۚ وَمَا تُنفِقُواْ مِن شَيۡءٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٞ

Ọwọ́ yin kò lè ba oore àyàfi tí ẹ bá ń ná nínú ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 92


۞كُلُّ ٱلطَّعَامِ كَانَ حِلّٗا لِّبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ إِلَّا مَا حَرَّمَ إِسۡرَـٰٓءِيلُ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦ مِن قَبۡلِ أَن تُنَزَّلَ ٱلتَّوۡرَىٰةُۚ قُلۡ فَأۡتُواْ بِٱلتَّوۡرَىٰةِ فَٱتۡلُوهَآ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Gbogbo oúnjẹ ló jẹ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àyàfi èyí tí ’Isrọ̄’īl bá ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ṣíwájú kí A tó sọ at-Taorāh kalẹ̀. Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú at-Taorāh wá, kí ẹ sì kà á síta tí ẹ̀yin bá jẹ́ olódodo.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 93


فَمَنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ

Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni alábòsí
Surah Aal-e-Imran, Verse 94


قُلۡ صَدَقَ ٱللَّهُۗ فَٱتَّبِعُواْ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۖ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

Sọ pé: "Allāhu sọ òdodo. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām. Kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah Aal-e-Imran, Verse 95


إِنَّ أَوَّلَ بَيۡتٖ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكٗا وَهُدٗى لِّلۡعَٰلَمِينَ

Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah . (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 96


فِيهِ ءَايَٰتُۢ بَيِّنَٰتٞ مَّقَامُ إِبۡرَٰهِيمَۖ وَمَن دَخَلَهُۥ كَانَ ءَامِنٗاۗ وَلِلَّهِ عَلَى ٱلنَّاسِ حِجُّ ٱلۡبَيۡتِ مَنِ ٱسۡتَطَاعَ إِلَيۡهِ سَبِيلٗاۚ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Àwọn àmì t’ó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́,dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 97


قُلۡ يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لِمَ تَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَٱللَّهُ شَهِيدٌ عَلَىٰ مَا تَعۡمَلُونَ

Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ óò fi ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu? Allāhu sì ni Arínú-róde ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 98


قُلۡ يَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لِمَ تَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ مَنۡ ءَامَنَ تَبۡغُونَهَا عِوَجٗا وَأَنتُمۡ شُهَدَآءُۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ

Sọ pé: "Ẹ̀yin ahlul-kitāb, nítorí kí ni ẹ fi ń ṣẹ́rí ẹni t’ó gbàgbọ́ lódodo kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ẹ sì ń fẹ́ kó wọ́, ẹ sì jẹ́rìí (sí òdodo ’Islām)? Allāhu kì í ṣe Onígbàgbé nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 99


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تُطِيعُواْ فَرِيقٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ يَرُدُّوكُم بَعۡدَ إِيمَٰنِكُمۡ كَٰفِرِينَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé apá kan nínú àwọn tí A fún ní tírà, wọ́n máa da yín padà lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo yín sí ipò aláìgbàgbọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 100


وَكَيۡفَ تَكۡفُرُونَ وَأَنتُمۡ تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ وَفِيكُمۡ رَسُولُهُۥۗ وَمَن يَعۡتَصِم بِٱللَّهِ فَقَدۡ هُدِيَ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ

Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà
Surah Aal-e-Imran, Verse 101


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ حَقَّ تُقَاتِهِۦ وَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنتُم مُّسۡلِمُونَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bẹ̀rù Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ wà ní ipò mùsùlùmí
Surah Aal-e-Imran, Verse 102


وَٱعۡتَصِمُواْ بِحَبۡلِ ٱللَّهِ جَمِيعٗا وَلَا تَفَرَّقُواْۚ وَٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ كُنتُمۡ أَعۡدَآءٗ فَأَلَّفَ بَيۡنَ قُلُوبِكُمۡ فَأَصۡبَحۡتُم بِنِعۡمَتِهِۦٓ إِخۡوَٰنٗا وَكُنتُمۡ عَلَىٰ شَفَا حُفۡرَةٖ مِّنَ ٱلنَّارِ فَأَنقَذَكُم مِّنۡهَاۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ

Ẹ dúró ṣinṣin ti okùn Allāhu (’Islām) ní àpapọ̀, ẹ má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ẹ sì rántí ìkẹ́ Allāhu tí ń bẹ lórí yín (pé) nígbà tí ẹ jẹ́ ọ̀tá (ara yín nígbà àìmọ̀kan), Ó pa ọkàn yín pọ̀ mọ́ra wọn (pẹ̀lú ’Islām), ẹ sì di ọmọ ìyá pẹ̀lú ìkẹ́ Rẹ̀; àti (nígbà tí) ẹ wà létí ọ̀gbun Iná, Ó gbà yín là kúrò nínú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe àlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà (’Islām)
Surah Aal-e-Imran, Verse 103


وَلۡتَكُن مِّنكُمۡ أُمَّةٞ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلۡخَيۡرِ وَيَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِۚ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ

Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun t’ó lóore jùlọ, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè
Surah Aal-e-Imran, Verse 104


وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ تَفَرَّقُواْ وَٱخۡتَلَفُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُۚ وَأُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ

Ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó sọra wọn di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì yapa ẹnu (sí ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn àlàyé t’ó yanjú ti dé bá wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà ńlá ń bẹ fún
Surah Aal-e-Imran, Verse 105


يَوۡمَ تَبۡيَضُّ وُجُوهٞ وَتَسۡوَدُّ وُجُوهٞۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱسۡوَدَّتۡ وُجُوهُهُمۡ أَكَفَرۡتُم بَعۡدَ إِيمَٰنِكُمۡ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ

Ní ọjọ́ tí àwọn ojú kan yóò funfun (ìmọ́lẹ̀). Àwọn ojú kan yó sì dúdú. Ní ti àwọn tí ojú wọn dúdú, (A ó bi wọ́n pé:) "Ṣé ẹ ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín ni?" Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ṣàì gbàgbọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 106


وَأَمَّا ٱلَّذِينَ ٱبۡيَضَّتۡ وُجُوهُهُمۡ فَفِي رَحۡمَةِ ٱللَّهِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ

Ní ti àwọn tí ojú wọn funfun (ìmọ́lẹ̀), nínú ìkẹ́ Allāhu ni wọn yóò wà. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 107


تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ نَتۡلُوهَا عَلَيۡكَ بِٱلۡحَقِّۗ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلۡمٗا لِّلۡعَٰلَمِينَ

Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí kan sí gbogbo ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 108


وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ

Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí
Surah Aal-e-Imran, Verse 109


كُنتُمۡ خَيۡرَ أُمَّةٍ أُخۡرِجَتۡ لِلنَّاسِ تَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَتَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِۗ وَلَوۡ ءَامَنَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۚ مِّنۡهُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ

Ẹ jẹ́ ìjọ t’ó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn , ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 110


لَن يَضُرُّوكُمۡ إِلَّآ أَذٗىۖ وَإِن يُقَٰتِلُوكُمۡ يُوَلُّوكُمُ ٱلۡأَدۡبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ

Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fun yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 111


ضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ أَيۡنَ مَا ثُقِفُوٓاْ إِلَّا بِحَبۡلٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَحَبۡلٖ مِّنَ ٱلنَّاسِ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَسۡكَنَةُۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ

Àbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bá wọn àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba ’Islām) àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu àlà
Surah Aal-e-Imran, Verse 112


۞لَيۡسُواْ سَوَآءٗۗ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ أُمَّةٞ قَآئِمَةٞ يَتۡلُونَ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ وَهُمۡ يَسۡجُدُونَ

(Àwọn ahlul-kitāb) kò rí bákan náà. Ìjọ kan t’ó dúró déédé wà nínú àwọn ahlul-kitāb, tí ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun)
Surah Aal-e-Imran, Verse 113


يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَيَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَيُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ مِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ

Wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 114


وَمَا يَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَلَن يُكۡفَرُوهُۗ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلۡمُتَّقِينَ

Ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí wọ́n pàdánù ẹ̀san rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀)
Surah Aal-e-Imran, Verse 115


إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡـٔٗاۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ

Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 116


مَثَلُ مَا يُنفِقُونَ فِي هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَثَلِ رِيحٖ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتۡ حَرۡثَ قَوۡمٖ ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَأَهۡلَكَتۡهُۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِنۡ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ

Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn t’ó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí
Surah Aal-e-Imran, Verse 117


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ بِطَانَةٗ مِّن دُونِكُمۡ لَا يَأۡلُونَكُمۡ خَبَالٗا وَدُّواْ مَا عَنِتُّمۡ قَدۡ بَدَتِ ٱلۡبَغۡضَآءُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَمَا تُخۡفِي صُدُورُهُمۡ أَكۡبَرُۚ قَدۡ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡقِلُونَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú aláfinúhàn kan yàtọ̀ sí ara yín. Wọn kò níí géwọ́ aburú kúrú fun yín. Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí ó máa kó ìnira ba yín. Ìkórira kúkú ti fojú hàn láti ẹnu wọn. Ohun tí ó sì pamọ́ sínú ọkàn wọn tóbi jùlọ. A ti ṣàlàyé àwọn āyah fun yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onílàákàyè
Surah Aal-e-Imran, Verse 118


هَـٰٓأَنتُمۡ أُوْلَآءِ تُحِبُّونَهُمۡ وَلَا يُحِبُّونَكُمۡ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱلۡكِتَٰبِ كُلِّهِۦ وَإِذَا لَقُوكُمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَوۡاْ عَضُّواْ عَلَيۡكُمُ ٱلۡأَنَامِلَ مِنَ ٱلۡغَيۡظِۚ قُلۡ مُوتُواْ بِغَيۡظِكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn kò sì nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú àwọn tírà, gbogbo rẹ̀ (pátápátá). Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé yín, wọ́n á wí pé: “Àwa gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku àwọn nìkan, wọn yóò máa deyín mọ́ ìka lórí yín ní ti ìbínú. Sọ pé: “Ẹ kú pẹ̀lú ìbínú yín.” Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 119


إِن تَمۡسَسۡكُمۡ حَسَنَةٞ تَسُؤۡهُمۡ وَإِن تُصِبۡكُمۡ سَيِّئَةٞ يَفۡرَحُواْ بِهَاۖ وَإِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ لَا يَضُرُّكُمۡ كَيۡدُهُمۡ شَيۡـًٔاۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعۡمَلُونَ مُحِيطٞ

Tí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ si yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì ṣọ́ra (fún wọn), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 120


وَإِذۡ غَدَوۡتَ مِنۡ أَهۡلِكَ تُبَوِّئُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ مَقَٰعِدَ لِلۡقِتَالِۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

(Rántí) nígbà tí o jí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ara ilé rẹ ní ìdájí kùtùkùtù, tí ò sì ń fi àyè ibùjagun han àwọn onígbàgbọ́ òdodo, Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀
Surah Aal-e-Imran, Verse 121


إِذۡ هَمَّت طَّآئِفَتَانِ مِنكُمۡ أَن تَفۡشَلَا وَٱللَّهُ وَلِيُّهُمَاۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ

(Rántí) nígbà tí ìjọ méjì nínú yín fẹ́ ṣojo. Allāhu sì ni Aláfẹ̀yìntì àwọn méjèèjì. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé
Surah Aal-e-Imran, Verse 122


وَلَقَدۡ نَصَرَكُمُ ٱللَّهُ بِبَدۡرٖ وَأَنتُمۡ أَذِلَّةٞۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ

Allāhu kúkú fun yín ní ìṣẹ́gun ní ogun Badr, nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìlágbára. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un)
Surah Aal-e-Imran, Verse 123


إِذۡ تَقُولُ لِلۡمُؤۡمِنِينَ أَلَن يَكۡفِيَكُمۡ أَن يُمِدَّكُمۡ رَبُّكُم بِثَلَٰثَةِ ءَالَٰفٖ مِّنَ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ مُنزَلِينَ

Rántí nígbà tí ò ń sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo pé: “Ṣé kò níí to yín tí Olúwa yín bá ṣe ìrànlọ́wọ́ fun yín pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú àwọn mọlāika, tí Wọ́n máa sọ̀kalẹ̀?”
Surah Aal-e-Imran, Verse 124


بَلَىٰٓۚ إِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ وَيَأۡتُوكُم مِّن فَوۡرِهِمۡ هَٰذَا يُمۡدِدۡكُمۡ رَبُّكُم بِخَمۡسَةِ ءَالَٰفٖ مِّنَ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ مُسَوِّمِينَ

Rárá (ó máa tó wa.). Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrú, tí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, tí àwọn (ọ̀tá) bá dé ba yín lójijì, Olúwa yín yóò ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún máàrún nínú àwọn mọlāika pẹ̀lú àmì ìdánimọ̀ lára wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 125


وَمَا جَعَلَهُ ٱللَّهُ إِلَّا بُشۡرَىٰ لَكُمۡ وَلِتَطۡمَئِنَّ قُلُوبُكُم بِهِۦۗ وَمَا ٱلنَّصۡرُ إِلَّا مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ

Allāhu kò ṣe é lásán bí kò ṣe kí ó lè jẹ́ ìró ìdùnnú fun yín àtí nítorí kí ọkàn yín lè balẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Kò sí àrànṣe lórí ọ̀tá (láti ibì kan kan) bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Aal-e-Imran, Verse 126


لِيَقۡطَعَ طَرَفٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَوۡ يَكۡبِتَهُمۡ فَيَنقَلِبُواْ خَآئِبِينَ

(Allāhu ṣe àrànṣe náà fun yín) nítorí kí Ó lè gé apá kan dànù nínú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tàbí nítorí kí Ó lè dójú tì wọ́n, tí wọ́n sì máa padà wálé lófo
Surah Aal-e-Imran, Verse 127


لَيۡسَ لَكَ مِنَ ٱلۡأَمۡرِ شَيۡءٌ أَوۡ يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡ أَوۡ يُعَذِّبَهُمۡ فَإِنَّهُمۡ ظَٰلِمُونَ

Kò sí ohun t’ó kàn ọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. Yálà (Allāhu) máa gba ìronúpìwàdà wọn tàbí Ó máa jẹ wọ́n níyà; dájúdájú alábòsí ni wọ́n
Surah Aal-e-Imran, Verse 128


وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ يَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Ó ń foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́, Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Aal-e-Imran, Verse 129


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَأۡكُلُواْ ٱلرِّبَوٰٓاْ أَضۡعَٰفٗا مُّضَٰعَفَةٗۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ

Ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe jẹ èlé, àdìpèlé lórí àdìpèlé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè
Surah Aal-e-Imran, Verse 130


وَٱتَّقُواْ ٱلنَّارَ ٱلَّتِيٓ أُعِدَّتۡ لِلۡكَٰفِرِينَ

Kí ẹ sì ṣọ́ra fún Iná tí Wọ́n ti pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 131


وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ

Kí ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ nítorí kí A lè kẹ yín
Surah Aal-e-Imran, Verse 132


۞وَسَارِعُوٓاْ إِلَىٰ مَغۡفِرَةٖ مِّن رَّبِّكُمۡ وَجَنَّةٍ عَرۡضُهَا ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ أُعِدَّتۡ لِلۡمُتَّقِينَ

Ẹ yára wá àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí ìbú rẹ̀ tó àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Wọ́n pa lésè sílẹ̀ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
Surah Aal-e-Imran, Verse 133


ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ فِي ٱلسَّرَّآءِ وَٱلضَّرَّآءِ وَٱلۡكَٰظِمِينَ ٱلۡغَيۡظَ وَٱلۡعَافِينَ عَنِ ٱلنَّاسِۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Àwọn t’ó ń ná owó wọn nígbà ìdẹ̀ra àti nígbà ìnira, àwọn tí ń gbé ìbínú mì, àwọn alámòjúúkúrò fún àwọn ènìyàn níbi àṣìṣe; Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 134


وَٱلَّذِينَ إِذَا فَعَلُواْ فَٰحِشَةً أَوۡ ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ ذَكَرُواْ ٱللَّهَ فَٱسۡتَغۡفَرُواْ لِذُنُوبِهِمۡ وَمَن يَغۡفِرُ ٱلذُّنُوبَ إِلَّا ٱللَّهُ وَلَمۡ يُصِرُّواْ عَلَىٰ مَا فَعَلُواْ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ

Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni)
Surah Aal-e-Imran, Verse 135


أُوْلَـٰٓئِكَ جَزَآؤُهُم مَّغۡفِرَةٞ مِّن رَّبِّهِمۡ وَجَنَّـٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَنِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ

Àwọn wọ̀nyẹn, ẹ̀san wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn ni àforíjìn àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san olùṣe-iṣẹ́ rere sì dára
Surah Aal-e-Imran, Verse 136


قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِكُمۡ سُنَنٞ فَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ

Àwọn orípa kan kúkú ti lọ ṣíwájú yín. Nítorí náà, ẹ rin ilẹ̀ lọ, kí ẹ wòye sí bí ìgbẹ̀yìn àwọn t’ó pe òdodo nírọ́ ṣe rí
Surah Aal-e-Imran, Verse 137


هَٰذَا بَيَانٞ لِّلنَّاسِ وَهُدٗى وَمَوۡعِظَةٞ لِّلۡمُتَّقِينَ

Èyí ni àlàyé fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti wáàsí sì ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu)
Surah Aal-e-Imran, Verse 138


وَلَا تَهِنُواْ وَلَا تَحۡزَنُواْ وَأَنتُمُ ٱلۡأَعۡلَوۡنَ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ

Ẹ má ṣe kọ́lẹ, ẹ sì má ṣe banújẹ́; ẹ̀yin l’ẹ máa lékè tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
Surah Aal-e-Imran, Verse 139


إِن يَمۡسَسۡكُمۡ قَرۡحٞ فَقَدۡ مَسَّ ٱلۡقَوۡمَ قَرۡحٞ مِّثۡلُهُۥۚ وَتِلۡكَ ٱلۡأَيَّامُ نُدَاوِلُهَا بَيۡنَ ٱلنَّاسِ وَلِيَعۡلَمَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَيَتَّخِذَ مِنكُمۡ شُهَدَآءَۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلظَّـٰلِمِينَ

Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ kèfèrí. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè (tẹ́wọ́) gba àwọn t’ó máa kú fún Un nínú yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí
Surah Aal-e-Imran, Verse 140


وَلِيُمَحِّصَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَيَمۡحَقَ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Àti pé (ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè ṣàfọ̀mọ́ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti nítorí kí Ó lè run àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 141


أَمۡ حَسِبۡتُمۡ أَن تَدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ وَلَمَّا يَعۡلَمِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ جَٰهَدُواْ مِنكُمۡ وَيَعۡلَمَ ٱلصَّـٰبِرِينَ

Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí Allāhu kò tí ì ṣàfi hàn àwọn t’ó máa jagun (ẹ̀sìn) nínú yín, tí kò sì tí ì ṣàfi hàn àwọn onísùúrù
Surah Aal-e-Imran, Verse 142


وَلَقَدۡ كُنتُمۡ تَمَنَّوۡنَ ٱلۡمَوۡتَ مِن قَبۡلِ أَن تَلۡقَوۡهُ فَقَدۡ رَأَيۡتُمُوهُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ

Dájúdájú ẹ ti ń fẹ́ ikú (ogun ẹ̀sìn) ṣíwájú kí ẹ tó pàdé rẹ̀. Ẹ kúkú ti rí i (báyìí), ẹ sì ń wòran
Surah Aal-e-Imran, Verse 143


وَمَا مُحَمَّدٌ إِلَّا رَسُولٞ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِ ٱلرُّسُلُۚ أَفَإِيْن مَّاتَ أَوۡ قُتِلَ ٱنقَلَبۡتُمۡ عَلَىٰٓ أَعۡقَٰبِكُمۡۚ وَمَن يَنقَلِبۡ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِ فَلَن يَضُرَّ ٱللَّهَ شَيۡـٔٗاۚ وَسَيَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلشَّـٰكِرِينَ

Kí ni (Ànábì) Muhammad bí kò ṣe Òjíṣẹ́, tí àwọn Òjíṣẹ́ kan ti lọ ṣíwájú rẹ̀. Ṣé tí ó bá kú tàbí tí wọ́n bá pa á, ẹ máa pẹ̀yìn dà (sẹ́sìn)? Ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìn dà (sẹ́sìn) kò lè kó ìnira kan kan bá Allāhu. Allāhu yó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere. awọ ẹran òkúǹbete tí wọ́n pa lósè kì í ṣe èèwọ̀ fún lílò fún ọ̀ṣọ́ ilé tàbí ọ̀ṣọ́ ara. Irú awọ ẹran òkúǹbete tí wọ́n pa lósè bẹ́ẹ̀ sì di ẹ̀tọ́ láti fi ṣe bàtà bẹ́lítì
Surah Aal-e-Imran, Verse 144


وَمَا كَانَ لِنَفۡسٍ أَن تَمُوتَ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِ كِتَٰبٗا مُّؤَجَّلٗاۗ وَمَن يُرِدۡ ثَوَابَ ٱلدُّنۡيَا نُؤۡتِهِۦ مِنۡهَا وَمَن يُرِدۡ ثَوَابَ ٱلۡأٓخِرَةِ نُؤۡتِهِۦ مِنۡهَاۚ وَسَنَجۡزِي ٱلشَّـٰكِرِينَ

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹ̀mí kan láti kú àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ikú jẹ́) àkọsílẹ̀ onígbèdéke. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ayé, A máa fún un ní ayé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń fẹ́ ẹ̀san (ní) ọ̀run, A máa fún un ní ọ̀run. A ó sì san àwọn olùdúpẹ́ ní ẹ̀san rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 145


وَكَأَيِّن مِّن نَّبِيّٖ قَٰتَلَ مَعَهُۥ رِبِّيُّونَ كَثِيرٞ فَمَا وَهَنُواْ لِمَآ أَصَابَهُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَمَا ضَعُفُواْ وَمَا ٱسۡتَكَانُواْۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلصَّـٰبِرِينَ

Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí wọ́n ti jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ-ẹ̀yìn (wọn). Wọn kò ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú ogun ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò kọ́lẹ, wọn kò sì jura wọn sílẹ̀ fún ọ̀tá ẹ̀sìn. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù
Surah Aal-e-Imran, Verse 146


وَمَا كَانَ قَوۡلَهُمۡ إِلَّآ أَن قَالُواْ رَبَّنَا ٱغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَا وَإِسۡرَافَنَا فِيٓ أَمۡرِنَا وَثَبِّتۡ أَقۡدَامَنَا وَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Kò sì sí ohun kan tí wọ́n sọ tayọ pé wọ́n sọ pé: "Olúwa wa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣejù wa nínú ọ̀rọ̀ wa jìn wá, mú ẹsẹ̀ wa dúró ṣinṣin, kí O sì ṣe àrànṣe fún wa lórí ìjọ aláìgbàgbọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 147


فَـَٔاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ ثَوَابَ ٱلدُّنۡيَا وَحُسۡنَ ثَوَابِ ٱلۡأٓخِرَةِۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Nítorí náà, Allāhu fún wọn ní ẹ̀san ayé àti dáadáa ẹ̀san ọ̀run. Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 148


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تُطِيعُواْ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَرُدُّوكُمۡ عَلَىٰٓ أَعۡقَٰبِكُمۡ فَتَنقَلِبُواْ خَٰسِرِينَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá tẹ̀lé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa yi yín lẹ́sẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Nígbà náà, ẹ máa padà di ẹni òfò (sínú àìgbàgbọ́)
Surah Aal-e-Imran, Verse 149


بَلِ ٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلنَّـٰصِرِينَ

Allāhu sì ni Alárànṣe yín. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn alárànṣe
Surah Aal-e-Imran, Verse 150


سَنُلۡقِي فِي قُلُوبِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلرُّعۡبَ بِمَآ أَشۡرَكُواْ بِٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ سُلۡطَٰنٗاۖ وَمَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُۖ وَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلظَّـٰلِمِينَ

A máa fi ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sínú ọkàn àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé wọ́n bá Allāhu wá akẹgbẹ́, èyí tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún. Iná sì ni ibùgbé wọn; ilé àwọn alábòsí sì burú
Surah Aal-e-Imran, Verse 151


وَلَقَدۡ صَدَقَكُمُ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥٓ إِذۡ تَحُسُّونَهُم بِإِذۡنِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا فَشِلۡتُمۡ وَتَنَٰزَعۡتُمۡ فِي ٱلۡأَمۡرِ وَعَصَيۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ مَآ أَرَىٰكُم مَّا تُحِبُّونَۚ مِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلدُّنۡيَا وَمِنكُم مَّن يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَۚ ثُمَّ صَرَفَكُمۡ عَنۡهُمۡ لِيَبۡتَلِيَكُمۡۖ وَلَقَدۡ عَفَا عَنكُمۡۗ وَٱللَّهُ ذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú Allāhu ti mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fun yín nígbà tí ẹ̀ ń pa wọ́n pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀, títí di ìgbà tí ẹ fi ṣojo, tí ẹ sì ń jiyàn sí ọ̀rọ̀. Ẹ sì yapa (àṣẹ Ànábì) lẹ́yìn tí Allāhu fi ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí hàn yín. - Ó wà nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ayé, ó sì ń bẹ nínú yín ẹni tí ń fẹ́ ọ̀run. - Lẹ́yìn náà, (Allāhu) yí ojú yín kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, kí Ó lè dan yín wò. Ó sì ti ṣàmójú kúrò fun yín; Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Aal-e-Imran, Verse 152


۞إِذۡ تُصۡعِدُونَ وَلَا تَلۡوُۥنَ عَلَىٰٓ أَحَدٖ وَٱلرَّسُولُ يَدۡعُوكُمۡ فِيٓ أُخۡرَىٰكُمۡ فَأَثَٰبَكُمۡ غَمَّۢا بِغَمّٖ لِّكَيۡلَا تَحۡزَنُواْ عَلَىٰ مَا فَاتَكُمۡ وَلَا مَآ أَصَٰبَكُمۡۗ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ̀ ń gùnkè sá lọ, tí ẹ̀yin kò sì bojú wo ẹnì kan kan mọ́ lẹ́yìn, Òjíṣẹ́ sì ń pè yín láti ẹ̀yìn yín. Nítorí náà, (Allāhu) fi ìbànújẹ́ (pípa tí àwọn ọ̀ṣẹbọ pa àwọn kan láààrin yín) san yín ní ẹ̀san ìbànújẹ́ (tí ẹ fi kan Ànábì nípasẹ̀ àìtẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ lójú ogun ’Uhd. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ẹ má baà banújẹ́ lórí ohun tí ó bọ́ fun yín àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 153


ثُمَّ أَنزَلَ عَلَيۡكُم مِّنۢ بَعۡدِ ٱلۡغَمِّ أَمَنَةٗ نُّعَاسٗا يَغۡشَىٰ طَآئِفَةٗ مِّنكُمۡۖ وَطَآئِفَةٞ قَدۡ أَهَمَّتۡهُمۡ أَنفُسُهُمۡ يَظُنُّونَ بِٱللَّهِ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ ظَنَّ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِۖ يَقُولُونَ هَل لَّنَا مِنَ ٱلۡأَمۡرِ مِن شَيۡءٖۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَمۡرَ كُلَّهُۥ لِلَّهِۗ يُخۡفُونَ فِيٓ أَنفُسِهِم مَّا لَا يُبۡدُونَ لَكَۖ يَقُولُونَ لَوۡ كَانَ لَنَا مِنَ ٱلۡأَمۡرِ شَيۡءٞ مَّا قُتِلۡنَا هَٰهُنَاۗ قُل لَّوۡ كُنتُمۡ فِي بُيُوتِكُمۡ لَبَرَزَ ٱلَّذِينَ كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَتۡلُ إِلَىٰ مَضَاجِعِهِمۡۖ وَلِيَبۡتَلِيَ ٱللَّهُ مَا فِي صُدُورِكُمۡ وَلِيُمَحِّصَ مَا فِي قُلُوبِكُمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ

Lẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fun yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó ìrònú bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí." Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.” (Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá
Surah Aal-e-Imran, Verse 154


إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَلَّوۡاْ مِنكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡتَقَى ٱلۡجَمۡعَانِ إِنَّمَا ٱسۡتَزَلَّهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ بِبَعۡضِ مَا كَسَبُواْۖ وَلَقَدۡ عَفَا ٱللَّهُ عَنۡهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٞ

Dájúdájú àwọn t’ó pẹ̀yìn dà nínú yín ní ọjọ́ tí ìjọ méjì pàdé, dájúdájú Èṣù l’ó yẹ̀ wọ́n lẹ́sẹ̀ nítorí apá kan ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì kúkú ti ṣàmójú kúrò fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà
Surah Aal-e-Imran, Verse 155


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَقَالُواْ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ إِذَا ضَرَبُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَوۡ كَانُواْ غُزّٗى لَّوۡ كَانُواْ عِندَنَا مَا مَاتُواْ وَمَا قُتِلُواْ لِيَجۡعَلَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ حَسۡرَةٗ فِي قُلُوبِهِمۡۗ وَٱللَّهُ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ìyá wọn, nígbà tí wọ́n ń rìn kiri ní orí ilẹ̀ tàbí (nígbà) tí wọ́n ń jagun, pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wa ni, wọn ìbá tí kú, àti pé wọn ìbá tí pa wọ́n.” (Wọ́n wí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi ìyẹn ṣe àbámọ̀ sínú ọkàn wọn. Allāhu l’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 156


وَلَئِن قُتِلۡتُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوۡ مُتُّمۡ لَمَغۡفِرَةٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَحۡمَةٌ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ

Dájúdájú tí wọ́n bá pa yín s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ kú (sínú ilé), dájúdájú àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Allāhu lóore ju ohun tí ẹ̀ ń kójọ (nílé ayé)
Surah Aal-e-Imran, Verse 157


وَلَئِن مُّتُّمۡ أَوۡ قُتِلۡتُمۡ لَإِلَى ٱللَّهِ تُحۡشَرُونَ

Dájúdájú tí ẹ bá kú (sínú ilé) tàbí wọ́n pa yín (s’ójú ogun ẹ̀sìn), dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni wọn máa ko yín jọ sí
Surah Aal-e-Imran, Verse 158


فَبِمَا رَحۡمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ لِنتَ لَهُمۡۖ وَلَوۡ كُنتَ فَظًّا غَلِيظَ ٱلۡقَلۡبِ لَٱنفَضُّواْ مِنۡ حَوۡلِكَۖ فَٱعۡفُ عَنۡهُمۡ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ وَشَاوِرۡهُمۡ فِي ٱلۡأَمۡرِۖ فَإِذَا عَزَمۡتَ فَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُتَوَكِّلِينَ

Ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó kúkú rọ̀ ọ́ fún wọn; tí ó bá jẹ́ pé o jẹ́ ẹni burúkú, ọlọ́kàn líle, wọn ìbá ti túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ṣàmójú kúrò fún wọn, bá wọn tọrọ àforíjìn, kí o sì bá wọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀. Tí o bá sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan), kí o gbáralé Allāhu. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbáralé E
Surah Aal-e-Imran, Verse 159


إِن يَنصُرۡكُمُ ٱللَّهُ فَلَا غَالِبَ لَكُمۡۖ وَإِن يَخۡذُلۡكُمۡ فَمَن ذَا ٱلَّذِي يَنصُرُكُم مِّنۢ بَعۡدِهِۦۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ

Tí Allāhu bá ṣe àrànṣe fun yín, kò sí ẹni tí ó máa borí yín. Tí Ó bá sì yẹpẹrẹ yín, ta sì ni ẹni tí ó máa ṣe àrànṣe fun yín lẹ́yìn Rẹ̀? Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé
Surah Aal-e-Imran, Verse 160


وَمَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَن يَغُلَّۚ وَمَن يَغۡلُلۡ يَأۡتِ بِمَا غَلَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá jí ọrọ̀ ogun mú ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 161


أَفَمَنِ ٱتَّبَعَ رِضۡوَٰنَ ٱللَّهِ كَمَنۢ بَآءَ بِسَخَطٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَمَأۡوَىٰهُ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ

Ṣé ẹni tí ó (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu dà bí ẹni tí ó padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, ibùgbé rẹ̀ sì ni iná Jahanamọ? Ìkángun náà sì burú
Surah Aal-e-Imran, Verse 162


هُمۡ دَرَجَٰتٌ عِندَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ

(Èkínní kejì èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò inú Iná ni) wọ́n ní ipò (ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 163


لَقَدۡ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ إِذۡ بَعَثَ فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡ أَنفُسِهِمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمۡ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلُ لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ

Allāhu kúkú ti ṣe oore fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí Ó fi lè gbé Òjíṣẹ́ kan dìde sí wọn láààrin ara wọn. (Òjíṣẹ́ náà) ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà (al-Ƙur’ān) àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
Surah Aal-e-Imran, Verse 164


أَوَلَمَّآ أَصَٰبَتۡكُم مُّصِيبَةٞ قَدۡ أَصَبۡتُم مِّثۡلَيۡهَا قُلۡتُمۡ أَنَّىٰ هَٰذَاۖ قُلۡ هُوَ مِنۡ عِندِ أَنفُسِكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ

Ṣé gbogbo ìgbà tí àdánwò kan bá kàn yín, tí ẹ sì ti fi méjì irú rẹ̀ (kan àwọn kèfèrí), ni ẹ̀yin yóò máa sọ pé: “Ọ̀nà wo ni èyí gbà ṣẹlẹ̀ sí wa?” Sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ ara yín.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Aal-e-Imran, Verse 165


وَمَآ أَصَٰبَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡتَقَى ٱلۡجَمۡعَانِ فَبِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَلِيَعۡلَمَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ tí ikọ̀ ogun méjèèjì pàdé (ṣẹlẹ̀) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Àti pé nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni
Surah Aal-e-Imran, Verse 166


وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ نَافَقُواْۚ وَقِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ قَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوِ ٱدۡفَعُواْۖ قَالُواْ لَوۡ نَعۡلَمُ قِتَالٗا لَّٱتَّبَعۡنَٰكُمۡۗ هُمۡ لِلۡكُفۡرِ يَوۡمَئِذٍ أَقۡرَبُ مِنۡهُمۡ لِلۡإِيمَٰنِۚ يَقُولُونَ بِأَفۡوَٰهِهِم مَّا لَيۡسَ فِي قُلُوبِهِمۡۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يَكۡتُمُونَ

(Ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn t’ó ṣọ̀bẹ-ṣèlu (nínú àwọn mùsùlùmí). (Àwọn onígbàgbọ́ òdodo) sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí á lọ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ wá dáàbò bo ẹ̀mí ara yín.” Wọ́n wí pé: “Àwa ìbá mọ ogun-ún jà àwa ìbá tẹ̀lé yín.” Wọ́n súnmọ́ àìgbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn ju ìgbàgbọ́ lọ. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 167


ٱلَّذِينَ قَالُواْ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ وَقَعَدُواْ لَوۡ أَطَاعُونَا مَا قُتِلُواْۗ قُلۡ فَٱدۡرَءُواْ عَنۡ أَنفُسِكُمُ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Àwọn t’ó sọ nípa àwọn ọmọ ìyá wọn (t’ó kú s’ójú ogun ẹ̀sìn) pé – tí àwọn sì jòkóò kalẹ̀ sílé (ní tiwọn), "Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n tẹ̀lé tiwa ni, wọn ìbá tí pa wọ́n." Sọ pé: “Ẹ yẹkú dànù fún ẹ̀mí yín tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 168


وَلَا تَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ قُتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَمۡوَٰتَۢاۚ بَلۡ أَحۡيَآءٌ عِندَ رَبِّهِمۡ يُرۡزَقُونَ

Ẹ má ṣe lérò pé òkú (ìyà) ni àwọn tí wọ́n pa s’ójú ogun ẹ̀sìn Allāhu, àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 169


فَرِحِينَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ وَيَسۡتَبۡشِرُونَ بِٱلَّذِينَ لَمۡ يَلۡحَقُواْ بِهِم مِّنۡ خَلۡفِهِمۡ أَلَّا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ

Wọ́n ń dunnú nítorí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀. Wọ́n sì ń yọ̀ fún àwọn tí kò tí ì pàdé wọn nínú àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ pé: “Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 170


۞يَسۡتَبۡشِرُونَ بِنِعۡمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَضۡلٖ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ

Wọ́n ń bá wọn yọ̀ fún ìkẹ́ àti oore-àjùlọ (tí ń dúró dè wọ́n) lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn onígbàgbọ́ òdodo ráre
Surah Aal-e-Imran, Verse 171


ٱلَّذِينَ ٱسۡتَجَابُواْ لِلَّهِ وَٱلرَّسُولِ مِنۢ بَعۡدِ مَآ أَصَابَهُمُ ٱلۡقَرۡحُۚ لِلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ مِنۡهُمۡ وَٱتَّقَوۡاْ أَجۡرٌ عَظِيمٌ

(Àwọn ni) àwọn t’ó jẹ́pè Allāhu àti Òjíṣẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti f’ara gbọgbẹ́. Ẹ̀san ńlá wà fún àwọn t’ó ṣe rere, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu) nínú wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 172


ٱلَّذِينَ قَالَ لَهُمُ ٱلنَّاسُ إِنَّ ٱلنَّاسَ قَدۡ جَمَعُواْ لَكُمۡ فَٱخۡشَوۡهُمۡ فَزَادَهُمۡ إِيمَٰنٗا وَقَالُواْ حَسۡبُنَا ٱللَّهُ وَنِعۡمَ ٱلۡوَكِيلُ

(Àwọn ni) àwọn tí àwọn ènìyàn wí fún pé: “Wọ́n mà ti kóra jọ dè yín, nítorí náà ẹ bẹ̀rù wọn.” (Èyí) lékún ìgbàgbọ́ òdodo wọn. Wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó fún wa. Ó sì dára ni Alámòójútó.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 173


فَٱنقَلَبُواْ بِنِعۡمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَضۡلٖ لَّمۡ يَمۡسَسۡهُمۡ سُوٓءٞ وَٱتَّبَعُواْ رِضۡوَٰنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ ذُو فَضۡلٍ عَظِيمٍ

Nítorí náà, wọ́n padà délé pẹ̀lú ìkẹ́ àti oore-àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Aburú kan kò sì kàn wọ́n. Àti pé wọ́n (ṣiṣẹ́) tọ ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Olóore ńlá
Surah Aal-e-Imran, Verse 174


إِنَّمَا ذَٰلِكُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ يُخَوِّفُ أَوۡلِيَآءَهُۥ فَلَا تَخَافُوهُمۡ وَخَافُونِ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ

Dájúdájú ìyẹn ni Èṣù, tí ń fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ dẹ́rù bà yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn. Kí ẹ sì bẹ̀rù Mi tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo
Surah Aal-e-Imran, Verse 175


وَلَا يَحۡزُنكَ ٱلَّذِينَ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡكُفۡرِۚ إِنَّهُمۡ لَن يَضُرُّواْ ٱللَّهَ شَيۡـٔٗاۚ يُرِيدُ ٱللَّهُ أَلَّا يَجۡعَلَ لَهُمۡ حَظّٗا فِي ٱلۡأٓخِرَةِۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٌ

Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń sáré kó sínú àìgbàgbọ́ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Dájúdájú wọn kò lè kó ìnira kan bá Allāhu. Allāhu kò fẹ́ kí ìpín kan nínú oore wà fún wọn ní ọ̀run (ni); ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 176


إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلۡكُفۡرَ بِٱلۡإِيمَٰنِ لَن يَضُرُّواْ ٱللَّهَ شَيۡـٔٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Dájúdájú àwọn t’ó fi ìgbàgbọ́ òdodo ra àìgbàgbọ́, wọn kò lè kó ìnira kan bá Allāhu. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 177


وَلَا يَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّمَا نُمۡلِي لَهُمۡ خَيۡرٞ لِّأَنفُسِهِمۡۚ إِنَّمَا نُمۡلِي لَهُمۡ لِيَزۡدَادُوٓاْ إِثۡمٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ

Kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé bí A ṣe ń lọ́ra fún wọn jẹ́ oore fún wọn. A kàn ń lọ́ra fún wọn nítorí kí wọ́n lè lékún nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 178


مَّا كَانَ ٱللَّهُ لِيَذَرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ عَلَىٰ مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ حَتَّىٰ يَمِيزَ ٱلۡخَبِيثَ مِنَ ٱلطَّيِّبِۗ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُطۡلِعَكُمۡ عَلَى ٱلۡغَيۡبِ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَجۡتَبِي مِن رُّسُلِهِۦ مَن يَشَآءُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۚ وَإِن تُؤۡمِنُواْ وَتَتَّقُواْ فَلَكُمۡ أَجۡرٌ عَظِيمٞ

Allāhu kò níí gbé àwọn onígbàgbọ́ òdodo jù sílẹ̀ lórí ohun tí ẹ wà lórí rẹ̀ (níbi àìmọ onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ṣọ̀bẹ-ṣèlu) títí Ó máa fi ya ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára ẹni dáadáa. Allāhu kò sì níí fi ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ mọ̀ yín, ṣùgbọ́n Allāhu yóò ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Tí ẹ bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ẹ̀san ńlá yó sì wà fun yín
Surah Aal-e-Imran, Verse 179


وَلَا يَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ يَبۡخَلُونَ بِمَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ هُوَ خَيۡرٗا لَّهُمۖ بَلۡ هُوَ شَرّٞ لَّهُمۡۖ سَيُطَوَّقُونَ مَا بَخِلُواْ بِهِۦ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ وَلِلَّهِ مِيرَٰثُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ

Kí àwọn t’ó ń ṣahun pẹ̀lú ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀ má ṣe lérò pé oore ni fún wọn. Rárá, aburú ni fún wọn. A ó fí ohun tí wọ́n fi ṣahun dì wọ́n lọ́rùn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 180


لَّقَدۡ سَمِعَ ٱللَّهُ قَوۡلَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ فَقِيرٞ وَنَحۡنُ أَغۡنِيَآءُۘ سَنَكۡتُبُ مَا قَالُواْ وَقَتۡلَهُمُ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَنَقُولُ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ

Allāhu kúkú ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú aláìní ni Allāhu, àwa sì ni ọlọ́rọ̀.” A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n wí àti pípa tí wọ́n pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. A sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
Surah Aal-e-Imran, Verse 181


ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيكُمۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيۡسَ بِظَلَّامٖ لِّلۡعَبِيدِ

Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ yín tì síwájú. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe àbòsí fún àwọn ẹrú (Rẹ̀)
Surah Aal-e-Imran, Verse 182


ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ عَهِدَ إِلَيۡنَآ أَلَّا نُؤۡمِنَ لِرَسُولٍ حَتَّىٰ يَأۡتِيَنَا بِقُرۡبَانٖ تَأۡكُلُهُ ٱلنَّارُۗ قُلۡ قَدۡ جَآءَكُمۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِي بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَبِٱلَّذِي قُلۡتُمۡ فَلِمَ قَتَلۡتُمُوهُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ

Àwọn t’ó wí pé: "Dájúdájú Allāhu ṣàdéhùn fún wa pé a ò gbọdọ̀ gba Òjíṣẹ́ kan gbọ́ títí ó máa fí mú sàráà kan wá fún wa tí iná (àtọ̀runwá) yóò fi lánu." Sọ pé: "Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín ṣíwájú mi pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí to yanjú àti èyí tí ẹ wí (yìí), nítorí kí ni ẹ fi pa wọ́n tí ẹ bá jẹ́ olódodo
Surah Aal-e-Imran, Verse 183


فَإِن كَذَّبُوكَ فَقَدۡ كُذِّبَ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَ جَآءُو بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُنِيرِ

Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ ní òpùrọ́. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ìpín-ìpín Tírà àti Tírà t’ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn
Surah Aal-e-Imran, Verse 184


كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۗ وَإِنَّمَا تُوَفَّوۡنَ أُجُورَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ فَمَن زُحۡزِحَ عَنِ ٱلنَّارِ وَأُدۡخِلَ ٱلۡجَنَّةَ فَقَدۡ فَازَۗ وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا مَتَٰعُ ٱلۡغُرُورِ

Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn
Surah Aal-e-Imran, Verse 185


۞لَتُبۡلَوُنَّ فِيٓ أَمۡوَٰلِكُمۡ وَأَنفُسِكُمۡ وَلَتَسۡمَعُنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَمِنَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُوٓاْ أَذٗى كَثِيرٗاۚ وَإِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ذَٰلِكَ مِنۡ عَزۡمِ ٱلۡأُمُورِ

Dájúdájú A ó máa dan yín wò nínú dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìpalára láti ọ̀dọ̀ àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan
Surah Aal-e-Imran, Verse 186


وَإِذۡ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ لَتُبَيِّنُنَّهُۥ لِلنَّاسِ وَلَا تَكۡتُمُونَهُۥ فَنَبَذُوهُ وَرَآءَ ظُهُورِهِمۡ وَٱشۡتَرَوۡاْ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلٗاۖ فَبِئۡسَ مَا يَشۡتَرُونَ

(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn àwọn tí A fún ní tírà pé ẹ gbọ́dọ̀ ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn, ẹ ò sì gbọdọ̀ fi pamọ́. Wọ́n sì jù ú sẹ́yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n sì tà á ní owó kékeré. Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń tà mà sì burú (níyà)
Surah Aal-e-Imran, Verse 187


لَا تَحۡسَبَنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡرَحُونَ بِمَآ أَتَواْ وَّيُحِبُّونَ أَن يُحۡمَدُواْ بِمَا لَمۡ يَفۡعَلُواْ فَلَا تَحۡسَبَنَّهُم بِمَفَازَةٖ مِّنَ ٱلۡعَذَابِۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ

Ẹ má ṣe lérò pé àwọn t’ó ń dunnú sí ohun tí wọ́n ṣe (ní àìdáa máa là nínú ìyà). Wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí kí àwọn (ènìyàn) máa yìn wọ́n fún ohun tí wọn kò ṣe (níṣẹ́ rere). Nítorí náà, ẹ má ṣe rò wọ́n ro ìgbàlà níbi Ìyà. Ìyà ẹlẹ́ta eléro sì wà fún wọn
Surah Aal-e-Imran, Verse 188


وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ

Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Aal-e-Imran, Verse 189


إِنَّ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán; (àmì wà nínú wọn) fún àwọn onílàákàyè
Surah Aal-e-Imran, Verse 190


ٱلَّذِينَ يَذۡكُرُونَ ٱللَّهَ قِيَٰمٗا وَقُعُودٗا وَعَلَىٰ جُنُوبِهِمۡ وَيَتَفَكَّرُونَ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ رَبَّنَا مَا خَلَقۡتَ هَٰذَا بَٰطِلٗا سُبۡحَٰنَكَ فَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ

Àwọn t’ó ń rántí Allāhu ní ìnàró, ìjókòó àti ní ìdùbúlẹ̀; tí wọ́n ń ronú sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (wọ́n sì ń sọ pé:) "Olúwa wa, Ìwọ kò ṣẹ̀dàá èyí pẹ̀lú irọ́. Mímọ́ ni fún Ọ. Nítorí náà, ṣọ́ wa níbi ìyà Iná
Surah Aal-e-Imran, Verse 191


رَبَّنَآ إِنَّكَ مَن تُدۡخِلِ ٱلنَّارَ فَقَدۡ أَخۡزَيۡتَهُۥۖ وَمَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٖ

Olúwa wa, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí O bá mú wọ inú Iná, O ti dójú tì í. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún àwọn alábòsí
Surah Aal-e-Imran, Verse 192


رَّبَّنَآ إِنَّنَا سَمِعۡنَا مُنَادِيٗا يُنَادِي لِلۡإِيمَٰنِ أَنۡ ءَامِنُواْ بِرَبِّكُمۡ فَـَٔامَنَّاۚ رَبَّنَا فَٱغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَا وَكَفِّرۡ عَنَّا سَيِّـَٔاتِنَا وَتَوَفَّنَا مَعَ ٱلۡأَبۡرَارِ

Olúwa wa, dájúdájú àwa gbọ́ olùpèpè kan t’ó ń pe (ìpè) sí ibi ìgbàgbọ́ pé: "Ẹ gba Olúwa yín gbọ́.” A sì gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, kí O sì pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́, kí O sì pa wá pẹ̀lú àwọn ẹni rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 193


رَبَّنَا وَءَاتِنَا مَا وَعَدتَّنَا عَلَىٰ رُسُلِكَ وَلَا تُخۡزِنَا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ إِنَّكَ لَا تُخۡلِفُ ٱلۡمِيعَادَ

Olúwa wa, fún wa ní ohun tí O ṣàdéhùn rẹ̀ fún wa lórí (ahọ́n) àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ. Má sì ṣe dójú tì wá ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Ìwọ kì í yapa àdéhùn
Surah Aal-e-Imran, Verse 194


فَٱسۡتَجَابَ لَهُمۡ رَبُّهُمۡ أَنِّي لَآ أُضِيعُ عَمَلَ عَٰمِلٖ مِّنكُم مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰۖ بَعۡضُكُم مِّنۢ بَعۡضٖۖ فَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ وَأُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَأُوذُواْ فِي سَبِيلِي وَقَٰتَلُواْ وَقُتِلُواْ لَأُكَفِّرَنَّ عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡ وَلَأُدۡخِلَنَّهُمۡ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ ثَوَابٗا مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ عِندَهُۥ حُسۡنُ ٱلثَّوَابِ

Olúwa wọn sì jẹ́pè wọn pé: “Dájúdájú Èmi kò níí fi iṣẹ́ oníṣẹ́ kan nínú yín ráre; ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ara kan náà ni yín (níbi ẹ̀san). Nítorí náà, àwọn t’ó gbé (ìlú wọn) jù sílẹ̀, tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn, tí wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n nítorí ẹ̀sìn Mi, wọ́n jagun ẹ̀sìn, wọ́n sì pa wọ́n. Dájúdájú Èmi yóò bá wọn pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Èmi yó sì mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni ẹ̀san dáadáa wà
Surah Aal-e-Imran, Verse 195


لَا يَغُرَّنَّكَ تَقَلُّبُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ

Má ṣe gba ẹ̀tàn pẹ̀lú ìgbòkè-gbodò àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìlú
Surah Aal-e-Imran, Verse 196


مَتَٰعٞ قَلِيلٞ ثُمَّ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ

Ìgbádùn díẹ̀ (lè wà fún wọn), lẹ́yìn náà iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ibùgbé náà sì burú
Surah Aal-e-Imran, Verse 197


لَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ لَهُمۡ جَنَّـٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا نُزُلٗا مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۗ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لِّلۡأَبۡرَارِ

Ṣùgbọ́n àwọn t’ó bẹ̀rù Olúwa wọn, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ fún wọn. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ibùdésí kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu sì lóore jùlọ fún àwọn ẹni rere
Surah Aal-e-Imran, Verse 198


وَإِنَّ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَمَن يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُمۡ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِمۡ خَٰشِعِينَ لِلَّهِ لَا يَشۡتَرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ ثَمَنٗا قَلِيلًاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ

Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn ahlul-kitāb ẹni t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fun yín àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún wọn; wọ́n ń páyà Allāhu, wọn kì í ta àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu ní owó kékeré. Àwọn wọ̀nyẹn ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́
Surah Aal-e-Imran, Verse 199


يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱصۡبِرُواْ وَصَابِرُواْ وَرَابِطُواْ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ṣe sùúrù, ẹ pàrọwà sùúrù, ẹ ṣọ́ bodè ìlú yín (láti lè dènà àwọn ọmọ-ogun ọ̀tá ẹ̀sìn). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè
Surah Aal-e-Imran, Verse 200


Author: Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni


<< Surah 2
>> Surah 4

Yoruba Translations by other Authors


Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Yoruba Translation By Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Popular Areas
Apartments for rent in Dubai Apartments for rent Abu Dhabi Villas for rent in Dubai House for rent Abu Dhabi Apartments for sale in Dubai Apartments for sale in Abu Dhabi Flat for rent Sharjah
Popular Searches
Studios for rent in UAE Apartments for rent in UAE Villas for rent in UAE Apartments for sale in UAE Villas for sale in UAE Land for sale in UAE Dubai Real Estate
Trending Areas
Apartments for rent in Dubai Marina Apartments for sale in Dubai Marina Villa for rent in Sharjah Villa for sale in Dubai Flat for rent in Ajman Studio for rent in Abu Dhabi Villa for rent in Ajman
Trending Searches
Villa for rent in Abu Dhabi Shop for rent in Dubai Villas for sale in Ajman Studio for rent in Sharjah 1 Bedroom Apartment for rent in Dubai Property for rent in Abu Dhabi Commercial properties for sale
© Copyright Dubai Prayer Time. All Rights Reserved
Designed by Prayer Time In Dubai