Surah Ar-Room - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
الٓمٓ
’Alif lām mīm
Surah Ar-Room, Verse 1
غُلِبَتِ ٱلرُّومُ
Wọ́n ṣẹ́gun Rōmu
Surah Ar-Room, Verse 2
فِيٓ أَدۡنَى ٱلۡأَرۡضِ وَهُم مِّنۢ بَعۡدِ غَلَبِهِمۡ سَيَغۡلِبُونَ
ní àwọn ilẹ̀ t’ó wà nítòsí (erékùsù Lárúbáwá). Lẹ́yìn ìṣẹ́gun wọn, àwọn náà máa ṣẹ́gun wọn
Surah Ar-Room, Verse 3
فِي بِضۡعِ سِنِينَۗ لِلَّهِ ٱلۡأَمۡرُ مِن قَبۡلُ وَمِنۢ بَعۡدُۚ وَيَوۡمَئِذٖ يَفۡرَحُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ
ní ọdún mẹ́wàá (sí ìgbà náà). Ti Allāhu ni àṣẹ ní ìṣaájú àti ní ìkẹ́yìn. Ní ọjọ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ òdodo máa dunnú
Surah Ar-Room, Verse 4
بِنَصۡرِ ٱللَّهِۚ يَنصُرُ مَن يَشَآءُۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ
sí àrànṣe Allāhu. Ó ń ṣàrànṣe fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run
Surah Ar-Room, Verse 5
وَعۡدَ ٱللَّهِۖ لَا يُخۡلِفُ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
(Èyí jẹ́) àdéhùn Allāhu. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀
Surah Ar-Room, Verse 6
يَعۡلَمُونَ ظَٰهِرٗا مِّنَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُمۡ عَنِ ٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ غَٰفِلُونَ
Wọ́n nímọ̀ nípa gban̄gba nínú ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Afọ́nú-fọ́ra sì ni wọ́n nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn
Surah Ar-Room, Verse 7
أَوَلَمۡ يَتَفَكَّرُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۗ مَّا خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلٖ مُّسَمّٗىۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ بِلِقَآيِٕ رَبِّهِمۡ لَكَٰفِرُونَ
Ṣé wọn kò ronú nípa ọ̀rọ̀ ara wọn ni? Allāhu kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn
Surah Ar-Room, Verse 8
أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗ وَأَثَارُواْ ٱلۡأَرۡضَ وَعَمَرُوهَآ أَكۡثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n fi ilẹ̀ dáko. Wọ́n sì lo ilẹ̀ fún ohun tí ó pọ̀ ju bí (àwọn ará Mọkkah) ṣe lò ó. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn sì mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Nítorí náà, Allāhu kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí
Surah Ar-Room, Verse 9
ثُمَّ كَانَ عَٰقِبَةَ ٱلَّذِينَ أَسَـٰٓـُٔواْ ٱلسُّوٓأَىٰٓ أَن كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَكَانُواْ بِهَا يَسۡتَهۡزِءُونَ
Lẹ́yìn náà, aburú jẹ́ àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣaburú nítorí pé wọ́n pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́
Surah Ar-Room, Verse 10
ٱللَّهُ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Allāhu ń pilẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sípò alààyè). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí
Surah Ar-Room, Verse 11
وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُبۡلِسُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ
Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yó sọ̀rètí nù
Surah Ar-Room, Verse 12
وَلَمۡ يَكُن لَّهُم مِّن شُرَكَآئِهِمۡ شُفَعَـٰٓؤُاْ وَكَانُواْ بِشُرَكَآئِهِمۡ كَٰفِرِينَ
Àti pé kò níí sí àwọn olùṣìpẹ̀ fún wọn nínú àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì máa jẹ́ alátakò òrìṣà wọn
Surah Ar-Room, Verse 13
وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يَوۡمَئِذٖ يَتَفَرَّقُونَ
Ní ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ yẹn ni wọn yóò pínyà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Surah Ar-Room, Verse 14
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فَهُمۡ فِي رَوۡضَةٖ يُحۡبَرُونَ
Ní ti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, wọn yóò wà ní àyè t’ó rẹwà jùlọ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí wọn yó sì máa dunnú
Surah Ar-Room, Verse 15
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَلِقَآيِٕ ٱلۡأٓخِرَةِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ فِي ٱلۡعَذَابِ مُحۡضَرُونَ
Ní ti àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pé àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò kó wá sínú Iná
Surah Ar-Room, Verse 16
فَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ حِينَ تُمۡسُونَ وَحِينَ تُصۡبِحُونَ
Nítorí náà, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu nígbà tí ẹ bá wà ní alẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní òwúrọ̀
Surah Ar-Room, Verse 17
وَلَهُ ٱلۡحَمۡدُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَعَشِيّٗا وَحِينَ تُظۡهِرُونَ
TiRẹ̀ sì ni ọpẹ́ nínú àwọn sánmọ̀ àti lórí ilẹ̀ ní àṣálẹ́ àti nígbà tí ẹ bá wà ní ọ̀sán
Surah Ar-Room, Verse 18
يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَيُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّ وَيُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ وَكَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ
(Allāhu) ń yọ alààyè jáde láti ara òkú. Ó ń yọ òkú jáde láti ara alààyè. Ó ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Báyẹn ni A óò ṣe mu ẹ̀yin náà jáde
Surah Ar-Room, Verse 19
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنۡ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ إِذَآ أَنتُم بَشَرٞ تَنتَشِرُونَ
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá yín láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà náà ẹ̀yin di abara tí ẹ̀ ń fọ́nká (lórí ilẹ̀ ayé)
Surah Ar-Room, Verse 20
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَنۡ خَلَقَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا لِّتَسۡكُنُوٓاْ إِلَيۡهَا وَجَعَلَ بَيۡنَكُم مَّوَدَّةٗ وَرَحۡمَةًۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀ pé, Ó ṣẹ̀dá àwọn aya fun yín láti ara yín nítorí kí ẹ lè rí ìfàyàbalẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì fi ìfẹ́ àti ìkẹ́ sí ààrin yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó láròjinlẹ̀
Surah Ar-Room, Verse 21
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ خَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفُ أَلۡسِنَتِكُمۡ وَأَلۡوَٰنِكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡعَٰلِمِينَ
Ó wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn èdè yín àti àwọn àwọ̀ ara yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onímọ̀
Surah Ar-Room, Verse 22
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ مَنَامُكُم بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱبۡتِغَآؤُكُم مِّن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni oorun yín ní alẹ́ àti ní ọ̀sán àti wíwá tí ẹ̀ ń wá nínú oore Rẹ̀ (fún ìjẹ-ìmu). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń gbọ́rọ̀
Surah Ar-Room, Verse 23
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ يُرِيكُمُ ٱلۡبَرۡقَ خَوۡفٗا وَطَمَعٗا وَيُنَزِّلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَيُحۡيِۦ بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni fífi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ti ẹ̀rù àti ìrètí. Ó sì ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Ó ń fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè
Surah Ar-Room, Verse 24
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَن تَقُومَ ٱلسَّمَآءُ وَٱلۡأَرۡضُ بِأَمۡرِهِۦۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمۡ دَعۡوَةٗ مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ إِذَآ أَنتُمۡ تَخۡرُجُونَ
Àti pé nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé sánmọ̀ àti ilẹ̀ dúró pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá pè yín ní ìpè kan nígbà náà ni ẹ̀yin yóò máa jáde láti inú ilẹ̀
Surah Ar-Room, Verse 25
وَلَهُۥ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ كُلّٞ لَّهُۥ قَٰنِتُونَ
TiRẹ̀ ni àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀
Surah Ar-Room, Verse 26
وَهُوَ ٱلَّذِي يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ وَهُوَ أَهۡوَنُ عَلَيۡهِۚ وَلَهُ ٱلۡمَثَلُ ٱلۡأَعۡلَىٰ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Òun ni Ẹni tí Ó ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá dídá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sípò alààyè fún àjíǹde). Ó sì rọrùn jùlọ fún Un (láti ṣe bẹ́ẹ̀). TiRẹ̀ ni ìròyìn t’ó ga jùlọ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n
Surah Ar-Room, Verse 27
ضَرَبَ لَكُم مَّثَلٗا مِّنۡ أَنفُسِكُمۡۖ هَل لَّكُم مِّن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن شُرَكَآءَ فِي مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ فَأَنتُمۡ فِيهِ سَوَآءٞ تَخَافُونَهُمۡ كَخِيفَتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
(Allāhu) ṣàkàwé kan fun yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fun yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gbadọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń páyà ẹ̀yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ t’ó ń ṣe làákàyè
Surah Ar-Room, Verse 28
بَلِ ٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ أَهۡوَآءَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٖۖ فَمَن يَهۡدِي مَنۡ أَضَلَّ ٱللَّهُۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ
Ńṣe ni àwọn t’ó ṣàbòsí tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn láì sí ìmọ̀ kan (fún wọn). Ta sì ni ó lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà? Kò sì níí sí àwọn alárànṣe fún wọn
Surah Ar-Room, Verse 29
فَأَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗاۚ فِطۡرَتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي فَطَرَ ٱلنَّاسَ عَلَيۡهَاۚ لَا تَبۡدِيلَ لِخَلۡقِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sì sí ìyípadà fún ẹ̀dá Allāhu. Ìyẹn ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀
Surah Ar-Room, Verse 30
۞مُنِيبِينَ إِلَيۡهِ وَٱتَّقُوهُ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَلَا تَكُونُواْ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
(Ẹ jẹ́) olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípa ìronúpìwàdà). Ẹ páyà Rẹ̀. Ẹ kírun. Ẹ má ṣe wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ
Surah Ar-Room, Verse 31
مِنَ ٱلَّذِينَ فَرَّقُواْ دِينَهُمۡ وَكَانُواْ شِيَعٗاۖ كُلُّ حِزۡبِۭ بِمَا لَدَيۡهِمۡ فَرِحُونَ
(Ẹ má ṣe wà) nínú àwọn t’ó dá ẹ̀sìn wọn sí kélekèle, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun tí ó wà lọ́dọ̀ wọn
Surah Ar-Room, Verse 32
وَإِذَا مَسَّ ٱلنَّاسَ ضُرّٞ دَعَوۡاْ رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَآ أَذَاقَهُم مِّنۡهُ رَحۡمَةً إِذَا فَرِيقٞ مِّنۡهُم بِرَبِّهِمۡ يُشۡرِكُونَ
Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, wọn yóò pe Olúwa wọn, tí wọn yóò máa ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí (Allāhu) bá fún wọn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, nígbà náà ni igun kan nínú wọn yóò máa ṣẹbọ sí Olúwa wọn
Surah Ar-Room, Verse 33
لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡۚ فَتَمَتَّعُواْ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí ohun tí (Allāhu) fún wọn. Ẹ máa jayé lọ. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀
Surah Ar-Room, Verse 34
أَمۡ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ سُلۡطَٰنٗا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُواْ بِهِۦ يُشۡرِكُونَ
Tàbí A sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún wọn, t’ó ń sọ̀rọ̀ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń sọ di akẹgbẹ́ Rẹ̀
Surah Ar-Room, Verse 35
وَإِذَآ أَذَقۡنَا ٱلنَّاسَ رَحۡمَةٗ فَرِحُواْ بِهَاۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ إِذَا هُمۡ يَقۡنَطُونَ
Nígbà tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò, wọn yóò dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn wọ́n nípa ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú, nígbà náà ni wọn yóò sọ̀rètí nù
Surah Ar-Room, Verse 36
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́, (Ó sì ń) díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́)? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́
Surah Ar-Room, Verse 37
فَـَٔاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجۡهَ ٱللَّهِۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ
Nítorí náà, fún ẹbí ni ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò tí agara dá (ní n̄ǹkan). Ìyẹn lóore jùlọ fún àwọn t’ó ń fẹ́ Ojú rere Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè
Surah Ar-Room, Verse 38
وَمَآ ءَاتَيۡتُم مِّن رِّبٗا لِّيَرۡبُوَاْ فِيٓ أَمۡوَٰلِ ٱلنَّاسِ فَلَا يَرۡبُواْ عِندَ ٱللَّهِۖ وَمَآ ءَاتَيۡتُم مِّن زَكَوٰةٖ تُرِيدُونَ وَجۡهَ ٱللَّهِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُضۡعِفُونَ
Ohunkóhun tí ẹ bá fún (àwọn ènìyàn) ní ẹ̀bùn, nítorí kí ó lè di èlé láti ara dúkìá àwọn ènìyàn, kò lè lékún ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì (fún àwọn ènìyàn) ní Zakāh, tí ẹ̀ ń fẹ́ ojú rere Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní àdìpèlé ẹ̀san
Surah Ar-Room, Verse 39
ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ ثُمَّ رَزَقَكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡۖ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَفۡعَلُ مِن ذَٰلِكُم مِّن شَيۡءٖۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín, lẹ́yìn náà, Ó fun yín ní arísìkí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà, O máa sọ yín di alààyè. Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè ṣe n̄ǹkan kan nínú ìyẹn? Mímọ́ ni fún Un. Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I
Surah Ar-Room, Verse 40
ظَهَرَ ٱلۡفَسَادُ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ بِمَا كَسَبَتۡ أَيۡدِي ٱلنَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعۡضَ ٱلَّذِي عَمِلُواْ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Ìbàjẹ́ hàn lórí ilẹ̀ àti lójú omi nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ àwọn ènìyàn ṣe níṣẹ́ (aburú) nítorí kí (Allāhu) lè fi (ìyà) apá kan èyí tí wọ́n ṣe níṣẹ́ (aburú) tọ́ wọn lẹ́nu wò nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (níbi aburú)
Surah Ar-Room, Verse 41
قُلۡ سِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلُۚ كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّشۡرِكِينَ
Sọ pé: “Ẹ rìn lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí àtubọ̀tán àwọn t’ó ṣíwájú ṣe rí! Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n jẹ́ ọ̀ṣẹbọ.”
Surah Ar-Room, Verse 42
فَأَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ ٱلۡقَيِّمِ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۖ يَوۡمَئِذٖ يَصَّدَّعُونَ
Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀rinlẹ̀ ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé, tí kò sí n̄ǹkan tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́dọ̀ Allāhu. Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ènìyàn yóò pínyà sí (èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti èrò Iná)
Surah Ar-Room, Verse 43
مَن كَفَرَ فَعَلَيۡهِ كُفۡرُهُۥۖ وَمَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِأَنفُسِهِمۡ يَمۡهَدُونَ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, orí ara rẹ̀ ni (ìyà) àìgbàgbọ́ rẹ̀ wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń tẹ́ ìtẹ́ (Ọgbà Ìdẹ̀ra) sílẹ̀ fún
Surah Ar-Room, Verse 44
لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡكَٰفِرِينَ
nítorí kí (Allāhu) lè san ẹ̀san rere nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìgbàgbọ́
Surah Ar-Room, Verse 45
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦٓ أَن يُرۡسِلَ ٱلرِّيَاحَ مُبَشِّرَٰتٖ وَلِيُذِيقَكُم مِّن رَّحۡمَتِهِۦ وَلِتَجۡرِيَ ٱلۡفُلۡكُ بِأَمۡرِهِۦ وَلِتَبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِهِۦ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni pé, Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró ìdùnnú. Àti pé nítorí kí (Allāhu) lè fun yín tọ́ wò nínú ìkẹ́ Rẹ̀; àti nítorí kí ọkọ̀ ojú-omi lè rìn lójú-omi pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀; àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́
Surah Ar-Room, Verse 46
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوۡمِهِمۡ فَجَآءُوهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَٱنتَقَمۡنَا مِنَ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيۡنَا نَصۡرُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. A sì gbẹ̀san lára àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀. Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo
Surah Ar-Room, Verse 47
ٱللَّهُ ٱلَّذِي يُرۡسِلُ ٱلرِّيَٰحَ فَتُثِيرُ سَحَابٗا فَيَبۡسُطُهُۥ فِي ٱلسَّمَآءِ كَيۡفَ يَشَآءُ وَيَجۡعَلُهُۥ كِسَفٗا فَتَرَى ٱلۡوَدۡقَ يَخۡرُجُ مِنۡ خِلَٰلِهِۦۖ فَإِذَآ أَصَابَ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦٓ إِذَا هُمۡ يَسۡتَبۡشِرُونَ
Allāhu ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn atẹ́gùn ránṣẹ́. (Atẹ́gùn náà) sì máa tu ẹ̀ṣújò sókè. (Allāhu) yó sì tẹ́ (ẹ̀ṣújò) sílẹ̀ s’ójú sánmọ̀ bí Ó bá ṣe fẹ́. Ó sì máa dá a kélekèle (sí ojú sánmọ̀). O sì máa rí òjò tí ó ma máa jáde láààrin rẹ̀. Nígbà tí Ó bá sì rọ (òjò náà) fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, nígbà náà wọn yó sì máa dunnú
Surah Ar-Room, Verse 48
وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلِ أَن يُنَزَّلَ عَلَيۡهِم مِّن قَبۡلِهِۦ لَمُبۡلِسِينَ
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí Ó tó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún wọn, wọ́n ti sọ̀rètí nù ṣíwájú rẹ̀
Surah Ar-Room, Verse 49
فَٱنظُرۡ إِلَىٰٓ ءَاثَٰرِ رَحۡمَتِ ٱللَّهِ كَيۡفَ يُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَآۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Nítorí náà, wòye sí àwọn orípa ìkẹ́ Allāhu, (wo) bí (Allāhu) ṣe ń ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. Dájúdájú (Allāhu) yìí ni Ó kúkú máa sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan
Surah Ar-Room, Verse 50
وَلَئِنۡ أَرۡسَلۡنَا رِيحٗا فَرَأَوۡهُ مُصۡفَرّٗا لَّظَلُّواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ يَكۡفُرُونَ
Dájúdájú tí A bá rán atẹ́gùn kan (sí wọn), kí wọ́n sì rí (n̄ǹkan ọ̀gbìn wọn) ní pípọ́n (jíjóná), dájúdájú wọn yó sì máa ṣàì moore lọ lẹ́yìn rẹ̀
Surah Ar-Room, Verse 51
فَإِنَّكَ لَا تُسۡمِعُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَلَا تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوۡاْ مُدۡبِرِينَ
Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ
Surah Ar-Room, Verse 52
وَمَآ أَنتَ بِهَٰدِ ٱلۡعُمۡيِ عَن ضَلَٰلَتِهِمۡۖ إِن تُسۡمِعُ إِلَّا مَن يُؤۡمِنُ بِـَٔايَٰتِنَا فَهُم مُّسۡلِمُونَ
Ìwọ kọ́ l’o máa fi ọ̀nà mọ àwọn afọ́jú níbi ìṣìnà wọn. Kò sí ẹni tí o máa mú gbọ́ ọ̀rọ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àwọn āyah Wa gbọ́. Àwọn sì ni (mùsùlùmí) olùjupá-jusẹ̀-sílẹ̀ fún Allāhu. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó ń ṣiṣẹ́ ìyanu. Kò sì sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun kan tí Allāhu kò fún ní iṣẹ́ ìyanu kan tàbí òmíràn ṣe ní ìbámu sí ìgbà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni èyíkéyìí iṣẹ́ ìyanu tí ó bá tọwọ́ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan wáyé kò sọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ náà di olúwa àti olùgbàlà. Allāhu nìkan ṣoṣo ní Olúwa àti Olùgbàlà ayé àti ọ̀run. Nítorí náà fún àlékún lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tí Allāhu bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ àwọn kristiẹni gẹ́gẹ́ bí ìṣesí wọn bí ó ṣe ń wù ú tó àti bí ó ṣe ń jẹ̀rankàn tó ni pé kí gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ gbàgbọ́ nínú Allāhu. Àmọ́ wọn kò gbàgbọ́
Surah Ar-Room, Verse 53
۞ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن ضَعۡفٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعۡدِ ضَعۡفٖ قُوَّةٗ ثُمَّ جَعَلَ مِنۢ بَعۡدِ قُوَّةٖ ضَعۡفٗا وَشَيۡبَةٗۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡقَدِيرُ
Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti (ara n̄ǹkan) lílẹ, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn lílẹ Ó fun (yín ní) agbára, lẹ́yìn náà, lẹ́yìn agbára, Ó tún fi lílẹ àti ogbó (si yín lára). Ó ń dá ohunkóhun tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Onímọ̀, Alágbára
Surah Ar-Room, Verse 54
وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ يُقۡسِمُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ مَا لَبِثُواْ غَيۡرَ سَاعَةٖۚ كَذَٰلِكَ كَانُواْ يُؤۡفَكُونَ
Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá ṣẹlẹ̀ (ìyẹn, ọjọ́ Àjíǹde), àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò máa búra pé àwọn kò gbé (ilé ayé) ju àkókò kan lọ.” Báyẹn ni wọ́n ṣe máa ń f’irọ́ tanra wọn jẹ
Surah Ar-Room, Verse 55
وَقَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ وَٱلۡإِيمَٰنَ لَقَدۡ لَبِثۡتُمۡ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡبَعۡثِۖ فَهَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡبَعۡثِ وَلَٰكِنَّكُمۡ كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ òdodo yóò sọ pé: “Dájúdájú nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu, ẹ ti gbé ilé ayé títí Ọjọ́ Àjíǹde (fi tó). Nítorí náà, èyí ni Ọjọ́ Àjíǹde, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mọ̀.”
Surah Ar-Room, Verse 56
فَيَوۡمَئِذٖ لَّا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَعۡذِرَتُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُسۡتَعۡتَبُونَ
Nítorí náà ní ọjọ́ yẹn, àwọn t’ó ṣàbòsí, àwáwí wọn kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu
Surah Ar-Room, Verse 57
وَلَقَدۡ ضَرَبۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَلَئِن جِئۡتَهُم بِـَٔايَةٖ لَّيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا مُبۡطِلُونَ
A kúkú ti fi oríṣiríṣi àkàwé lélẹ̀ nínú al-Ƙur’ān yìí fún àwọn ènìyàn. Dájúdájú tí o bá mú āyah kan wá fún wọn, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Ẹ̀yin (mùsùlùmí) kò jẹ́ kiní kan tayọ òpùrọ́.”
Surah Ar-Room, Verse 58
كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ
Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí dí ọkàn àwọn tí kò nímọ̀
Surah Ar-Room, Verse 59
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ وَلَا يَسۡتَخِفَّنَّكَ ٱلَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí kò mọ àmọ̀dájú (nípa Ọjọ́ ẹ̀san) sọ ọ́ dòpè
Surah Ar-Room, Verse 60