Surah Al-Ahzab Verse 37 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah Al-Ahzabوَإِذۡ تَقُولُ لِلَّذِيٓ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَأَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِ أَمۡسِكۡ عَلَيۡكَ زَوۡجَكَ وَٱتَّقِ ٱللَّهَ وَتُخۡفِي فِي نَفۡسِكَ مَا ٱللَّهُ مُبۡدِيهِ وَتَخۡشَى ٱلنَّاسَ وَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخۡشَىٰهُۖ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيۡدٞ مِّنۡهَا وَطَرٗا زَوَّجۡنَٰكَهَا لِكَيۡ لَا يَكُونَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ حَرَجٞ فِيٓ أَزۡوَٰجِ أَدۡعِيَآئِهِمۡ إِذَا قَضَوۡاْ مِنۡهُنَّ وَطَرٗاۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولٗا
(Ranti) nigba ti o n so fun eni ti Allahu sedera fun, ti iwo naa sedera fun1 pe: “Mu iyawo re dani, ki o si beru Allahu.” O si n fi pamo sinu emi re ohun ti Allahu yo safi han re. Ati pe o n paya awon eniyan. Allahu l’O si letoo julo pe ki o paya Re. Nigba ti Zaed ti pari bukata re lodo re (ti o si ti ko o sile), A ti se e ni iyawo fun o nitori ki o ma baa je laifi fun awon onigbagbo ododo lati fe iyawo omo-olomo ti won n pe ni omo won nigba ti won ba ti pari bukata won lodo won (ti won si ti ko won sile). Ase Allahu si gbodo se