Surah Ya-Seen - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
يسٓ
Ya sin
Surah Ya-Seen, Verse 1
وَٱلۡقُرۡءَانِ ٱلۡحَكِيمِ
(Allahu) bura pelu Al-Ƙur’an tira ogbon
Surah Ya-Seen, Verse 2
إِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dajudaju iwo wa ninu awon Ojise
Surah Ya-Seen, Verse 3
عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
wa lori ona taara (’Islam)
Surah Ya-Seen, Verse 4
تَنزِيلَ ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ
(Al-Ƙur’an je) imisi t’o sokale lati odo Alagbara, Asake-orun
Surah Ya-Seen, Verse 5
لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أُنذِرَ ءَابَآؤُهُمۡ فَهُمۡ غَٰفِلُونَ
nitori ki o le sekilo fun awon eniyan kan, (awon) ti won ko se ikilo fun awon baba won ri. Nitori naa, afonufora si ni won (nipa imona)
Surah Ya-Seen, Verse 6
لَقَدۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَىٰٓ أَكۡثَرِهِمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Dajudaju oro naa ti ko le opolopo won lori; won ko si nii gbagbo
Surah Ya-Seen, Verse 7
إِنَّا جَعَلۡنَا فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ أَغۡلَٰلٗا فَهِيَ إِلَى ٱلۡأَذۡقَانِ فَهُم مُّقۡمَحُونَ
Dajudaju Awa ti ko ewon si won lorun. O si ga de agbon (won). Won si ga won lorun soke
Surah Ya-Seen, Verse 8
وَجَعَلۡنَا مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ سَدّٗا وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ سَدّٗا فَأَغۡشَيۡنَٰهُمۡ فَهُمۡ لَا يُبۡصِرُونَ
Ati pe Awa fi gaga kan siwaju won, gaga kan seyin won; A bo won loju, won ko si riran
Surah Ya-Seen, Verse 9
وَسَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Bakan naa ni fun won, yala o kilo fun won tabi o o kilo fun won; won ko nii gbagbo
Surah Ya-Seen, Verse 10
إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلذِّكۡرَ وَخَشِيَ ٱلرَّحۡمَٰنَ بِٱلۡغَيۡبِۖ فَبَشِّرۡهُ بِمَغۡفِرَةٖ وَأَجۡرٖ كَرِيمٍ
Eni ti ikilo re (maa wulo fun) ni eni ti o tele Isiti (al-Ƙur’an), ti o si paya Ajoke-aye ni ikoko. Nitori naa, fun un ni iro idunnu nipa aforijin ati esan alapon-onle
Surah Ya-Seen, Verse 11
إِنَّا نَحۡنُ نُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَنَكۡتُبُ مَا قَدَّمُواْ وَءَاثَٰرَهُمۡۚ وَكُلَّ شَيۡءٍ أَحۡصَيۡنَٰهُ فِيٓ إِمَامٖ مُّبِينٖ
Dajudaju Awa, Awa l’A n so awon oku di alaye. A si n se akosile ohun ti won ti siwaju ati oripa (ise owo) won. Gbogbo nnkan ni A se akosile re sinu tira kan t’o yanju
Surah Ya-Seen, Verse 12
وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلًا أَصۡحَٰبَ ٱلۡقَرۡيَةِ إِذۡ جَآءَهَا ٱلۡمُرۡسَلُونَ
Fi apejuwe kan lele fun won nipa awon ara ilu kan nigba ti awon Ojise wa ba won
Surah Ya-Seen, Verse 13
إِذۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهِمُ ٱثۡنَيۡنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزۡنَا بِثَالِثٖ فَقَالُوٓاْ إِنَّآ إِلَيۡكُم مُّرۡسَلُونَ
(Ranti) nigba ti A ran Ojise meji nise si won. Won pe awon mejeeji ni opuro. A si fi eni keta ro awon mejeeji lagbara. Won si so pe: “Dajudaju awa ni Ojise ti Won ran nise si yin.”
Surah Ya-Seen, Verse 14
قَالُواْ مَآ أَنتُمۡ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا وَمَآ أَنزَلَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مِن شَيۡءٍ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا تَكۡذِبُونَ
Won wi pe: “Eyin ko je kini kan bi ko se abara bi iru tiwa. Ajoke-aye ko si so nnkan kan kale. Eyin ko si je kini kan bi ko se opuro.”
Surah Ya-Seen, Verse 15
قَالُواْ رَبُّنَا يَعۡلَمُ إِنَّآ إِلَيۡكُمۡ لَمُرۡسَلُونَ
Won so pe: "Oluwa wa mo pe dajudaju awa ni Ojise ti Won ran nise si yin
Surah Ya-Seen, Verse 16
وَمَا عَلَيۡنَآ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Ko si si ojuse kan fun wa bi ko se ise-jije ponnbele.”
Surah Ya-Seen, Verse 17
قَالُوٓاْ إِنَّا تَطَيَّرۡنَا بِكُمۡۖ لَئِن لَّمۡ تَنتَهُواْ لَنَرۡجُمَنَّكُمۡ وَلَيَمَسَّنَّكُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٞ
Won wi pe: “Dajudaju awa ri ami aburu lara yin. Ti e o ba jawo (nibi ipepe yin), dajudaju a maa so yin loko pa. Iya eleta-elero yo si je yin lati odo wa.”
Surah Ya-Seen, Verse 18
قَالُواْ طَـٰٓئِرُكُم مَّعَكُمۡ أَئِن ذُكِّرۡتُمۚ بَلۡ أَنتُمۡ قَوۡمٞ مُّسۡرِفُونَ
Won so pe: "Ami aburu yin n be pelu yin. Se nitori pe won se isiti fun yin (l’e fi ri ami aburu lara wa)? Ko ri bee! Ijo alakoyo ni yin ni
Surah Ya-Seen, Verse 19
وَجَآءَ مِنۡ أَقۡصَا ٱلۡمَدِينَةِ رَجُلٞ يَسۡعَىٰ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُواْ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Okunrin kan sare de lati opin ilu naa, o wi pe: “Eyin eniyan mi, e tele awon Ojise naa
Surah Ya-Seen, Verse 20
ٱتَّبِعُواْ مَن لَّا يَسۡـَٔلُكُمۡ أَجۡرٗا وَهُم مُّهۡتَدُونَ
E tele eni ti ko beere owo-oya kan ni owo yin. Olumona si ni won
Surah Ya-Seen, Verse 21
وَمَالِيَ لَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Ki ni o maa mu mi ti emi ko fi nii josin fun Eni ti O pile eda mi? Odo Re si ni won yoo da yin pada si
Surah Ya-Seen, Verse 22
ءَأَتَّخِذُ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةً إِن يُرِدۡنِ ٱلرَّحۡمَٰنُ بِضُرّٖ لَّا تُغۡنِ عَنِّي شَفَٰعَتُهُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَا يُنقِذُونِ
Se ki ng so awon kan di olohun leyin Allahu ni? Ti Ajoke-aye ba fe fi inira kan mi, isipe won ko le ro mi loro kini kan, won ko si le gba mi la
Surah Ya-Seen, Verse 23
إِنِّيٓ إِذٗا لَّفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
(Bi emi ko ba josin fun Allahu) nigba naa dajudaju mo ti wa ninu isina ponnbele
Surah Ya-Seen, Verse 24
إِنِّيٓ ءَامَنتُ بِرَبِّكُمۡ فَٱسۡمَعُونِ
Dajudaju emi gbagbo ninu Oluwa Eledaa yin. Nitori naa, e gbo mi.”
Surah Ya-Seen, Verse 25
قِيلَ ٱدۡخُلِ ٱلۡجَنَّةَۖ قَالَ يَٰلَيۡتَ قَوۡمِي يَعۡلَمُونَ
Won so pe: “Wo inu Ogba Idera.” O so pe: “Awon eniyan mi iba ni imo
Surah Ya-Seen, Verse 26
بِمَا غَفَرَ لِي رَبِّي وَجَعَلَنِي مِنَ ٱلۡمُكۡرَمِينَ
nipa bi Oluwa mi se forijin mi ati (bi) O se fi mi si ara awon alapon-onle (won iba ronu piwada).”
Surah Ya-Seen, Verse 27
۞وَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَىٰ قَوۡمِهِۦ مِنۢ بَعۡدِهِۦ مِن جُندٖ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا كُنَّا مُنزِلِينَ
A ko so omo ogun kan kale le awon eniyan re lori lati sanmo leyin re. A o si so (molaika kan) kale (fun iparun won)
Surah Ya-Seen, Verse 28
إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ خَٰمِدُونَ
(Iparun won) ko je kini kan bi ko se igbe eyo kan; nigba naa ni won di oku kale
Surah Ya-Seen, Verse 29
يَٰحَسۡرَةً عَلَى ٱلۡعِبَادِۚ مَا يَأۡتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Abamo ma ni fun awon erusin naa; ojise kan ko nii wa ba won ayafi ki won maa fi se yeye
Surah Ya-Seen, Verse 30
أَلَمۡ يَرَوۡاْ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ أَنَّهُمۡ إِلَيۡهِمۡ لَا يَرۡجِعُونَ
Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? (Se won ko ri i pe) dajudaju won ko pada si odo won mo (nile aye) ni
Surah Ya-Seen, Verse 31
وَإِن كُلّٞ لَّمَّا جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ
Dajudaju gbogbo won patapata si ni won maa ko wa si odo Wa
Surah Ya-Seen, Verse 32
وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلۡأَرۡضُ ٱلۡمَيۡتَةُ أَحۡيَيۡنَٰهَا وَأَخۡرَجۡنَا مِنۡهَا حَبّٗا فَمِنۡهُ يَأۡكُلُونَ
Ami ni oku ile je fun won. A so o di aye. A si mu eso jade lati inu re. Won si n je ninu re
Surah Ya-Seen, Verse 33
وَجَعَلۡنَا فِيهَا جَنَّـٰتٖ مِّن نَّخِيلٖ وَأَعۡنَٰبٖ وَفَجَّرۡنَا فِيهَا مِنَ ٱلۡعُيُونِ
A tun se awon ogba dabinu ati ajara sinu ile. A si mu awon odo iseleru se yo lati inu re
Surah Ya-Seen, Verse 34
لِيَأۡكُلُواْ مِن ثَمَرِهِۦ وَمَا عَمِلَتۡهُ أَيۡدِيهِمۡۚ أَفَلَا يَشۡكُرُونَ
nitori ki won le je ninu eso re ati eyi ti won fi owo ara won se! Se won ko nii dupe ni? “nitori ki won le je ninu eso re ki i si se ise owo won. Se won ko nii dupe ni?” Itumo keji duro le ise Allahu lori iseda nnkan oko. Iyen ni pe
Surah Ya-Seen, Verse 35
سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ وَمِنۡ أَنفُسِهِمۡ وَمِمَّا لَا يَعۡلَمُونَ
Mimo ni fun Eni ti O seda gbogbo nnkan ni orisirisi ninu ohun ti ile n hu jade ati ninu emi ara won ati ninu ohun ti won ko mo. tabi oro imo ero kan tabi imo irori kan tabi eyikeyii imo kan lodi si ayah kan ninu al-Ƙur’an tabi hadith Anabi wa Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) t’o fese rinle o ti sina ni isina ponnbele. “zaoj” ni eyo. “Zaoj” si n tumo si ako tabi abo nigba ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) ba n soro nipa iseda eniyan tabi omo bibi gege bi o se wa ninu surah an-Najm; 53:45 ati surah al-Ƙiyamoh; 75:39. amo ti ikini keji yato sira won ni ona kookan gege bi ako ati abo nnkan didun ati nnkan kikoro a le ri eso mimu tabi eso jije kan ti o maa je orisirisi. Itumo olorisirisi tun lo labe ayah ti a n tose re lowo yii. Nitori naa zaoj ko pon dandan ki o ni itumo ako ati abo nikan. Orisirisi ni “zaoj”; ako je orisi kan
Surah Ya-Seen, Verse 36
وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلَّيۡلُ نَسۡلَخُ مِنۡهُ ٱلنَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظۡلِمُونَ
Oru je ami kan fun won, ti A n yo osan jade lati inu re. Nigba naa (ti A ba yo o tan) won yoo tun wa ninu okunkun (ale miiran). ojo keje ni ojo iparan suna omo naa. Bawo ni a o se ka ojo meje naa? Teletele awon kan lero pe koda ki ojo ibimo ku iseju kan ti a o fi bo sinu ojo titun. Bi apeere ti obinrin kan ba bimo ni osan Alaadi
Surah Ya-Seen, Verse 37
وَٱلشَّمۡسُ تَجۡرِي لِمُسۡتَقَرّٖ لَّهَاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ
Ati pe oorun yoo maa rin lo si aye re. Iyen ni eto (ti) Alagbara, Onimo
Surah Ya-Seen, Verse 38
وَٱلۡقَمَرَ قَدَّرۡنَٰهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَٱلۡعُرۡجُونِ ٱلۡقَدِيمِ
Osupa naa, A ti se odiwon awon ibuso fun un (ti o ti ma maa tobi si i) titi o maa fi pada da bii ogomo ope t’o ti pe
Surah Ya-Seen, Verse 39
لَا ٱلشَّمۡسُ يَنۢبَغِي لَهَآ أَن تُدۡرِكَ ٱلۡقَمَرَ وَلَا ٱلَّيۡلُ سَابِقُ ٱلنَّهَارِۚ وَكُلّٞ فِي فَلَكٖ يَسۡبَحُونَ
Ko ye fun oorun lati lo asiko osupa. Ko si ye fun ale lati lo asiko osan. Ikookan wa ni opopona roboto t’o n to
Surah Ya-Seen, Verse 40
وَءَايَةٞ لَّهُمۡ أَنَّا حَمَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ
O tun je ami fun won pe dajudaju Awa gbe awon aromodomo won gun oko oju-omi t’o kun keke
Surah Ya-Seen, Verse 41
وَخَلَقۡنَا لَهُم مِّن مِّثۡلِهِۦ مَا يَرۡكَبُونَ
A tun seda (omiran) fun won ninu iru re ti won yoo maa gun
Surah Ya-Seen, Verse 42
وَإِن نَّشَأۡ نُغۡرِقۡهُمۡ فَلَا صَرِيخَ لَهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنقَذُونَ
Ti A ba fe Awa iba te won ri sinu omi. Ko nii si oluranlowo kan fun won. Won ko si nii gba won la
Surah Ya-Seen, Verse 43
إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ
Afi (ki A fi) ike kan lati odo Wa (yo won jade, ki A si tun fun won ni) igbadun aye titi di igba die
Surah Ya-Seen, Verse 44
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُواْ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيكُمۡ وَمَا خَلۡفَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ
(Won maa gbunri) nigba ti A ba so fun won pe: "E sora fun ohun t’o wa niwaju yin ati ohun t’o wa leyin yin nitori ki A le ke yin
Surah Ya-Seen, Verse 45
وَمَا تَأۡتِيهِم مِّنۡ ءَايَةٖ مِّنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِمۡ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ
Ati pe ayah kan ninu awon ayah Oluwa won ko nii wa ba won afi ki won maa gbunri kuro nibe
Surah Ya-Seen, Verse 46
وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ أَنفِقُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنُطۡعِمُ مَن لَّوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ أَطۡعَمَهُۥٓ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Nigba ti A ba si so fun won pe: "E na ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun yin.", awon t’o sai gbagbo yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Se ki a bo eni ti (o je pe) Allahu iba fe iba bo o (amo ko bo o. Awa naa ko si nii ba A bo o)?” Ki ni eyin bi ko se pe (e wa) ninu isina ponnbele
Surah Ya-Seen, Verse 47
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Won si n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo
Surah Ya-Seen, Verse 48
مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ تَأۡخُذُهُمۡ وَهُمۡ يَخِصِّمُونَ
Won ko reti kini kan bi ko se igbe eyo kan soso ti o maa gba won mu nigba ti won ba n se ariyanjiyan lowo
Surah Ya-Seen, Verse 49
فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ تَوۡصِيَةٗ وَلَآ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ يَرۡجِعُونَ
Nigba naa, won ko nii le so asoole kan. Won ko si nii le pada si odo ara ile won
Surah Ya-Seen, Verse 50
وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يَنسِلُونَ
Won a si fon fere oniwo fun ajinde, nigba naa ni won yoo maa sare jade lati inu saree wa si odo Oluwa won
Surah Ya-Seen, Verse 51
قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا مَنۢ بَعَثَنَا مِن مَّرۡقَدِنَاۜۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَصَدَقَ ٱلۡمُرۡسَلُونَ
Won a wi pe: "Egbe wa o! Ta ni o ta wa ji lati oju oorun wa?" Eyi ni nnkan ti Ajoke-aye se ni adehun. Awon Ojise si ti so ododo (nipa re)
Surah Ya-Seen, Verse 52
إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ
Ko je kini kan tayo igbe eyo kan soso. Nigba naa ni (awon molaika) yoo ko gbogbo won jo si odo Wa
Surah Ya-Seen, Verse 53
فَٱلۡيَوۡمَ لَا تُظۡلَمُ نَفۡسٞ شَيۡـٔٗا وَلَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Nitori naa, ni oni won ko nii se abosi kini kan fun emi kan. A o si nii san yin ni esan afi ohun ti e n se nise
Surah Ya-Seen, Verse 54
إِنَّ أَصۡحَٰبَ ٱلۡجَنَّةِ ٱلۡيَوۡمَ فِي شُغُلٖ فَٰكِهُونَ
Dajudaju ni oni awon ero inu Ogba Idera yoo kun fun igbadun
Surah Ya-Seen, Verse 55
هُمۡ وَأَزۡوَٰجُهُمۡ فِي ظِلَٰلٍ عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ مُتَّكِـُٔونَ
Awon ati awon iyawo won yoo wa labe awon iboji, won yo si rogboku sori awon ibusun
Surah Ya-Seen, Verse 56
لَهُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٞ وَلَهُم مَّا يَدَّعُونَ
Eso wa ninu re fun won. Ohun ti won yoo maa beere fun tun wa fun won pelu
Surah Ya-Seen, Verse 57
سَلَٰمٞ قَوۡلٗا مِّن رَّبّٖ رَّحِيمٖ
Alaafia ni oro ti o maa wa lati odo Oluwa, Asake-orun
Surah Ya-Seen, Verse 58
وَٱمۡتَٰزُواْ ٱلۡيَوۡمَ أَيُّهَا ٱلۡمُجۡرِمُونَ
Eyin elese, e bo si oto ni oni
Surah Ya-Seen, Verse 59
۞أَلَمۡ أَعۡهَدۡ إِلَيۡكُمۡ يَٰبَنِيٓ ءَادَمَ أَن لَّا تَعۡبُدُواْ ٱلشَّيۡطَٰنَۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
Eyin omo (Anabi) Adam, se Emi ko ti pa yin ni ase pe ki e ma se josin fun Esu? Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin
Surah Ya-Seen, Verse 60
وَأَنِ ٱعۡبُدُونِيۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Ati pe ki e josin fun Mi. Eyi ni ona taara
Surah Ya-Seen, Verse 61
وَلَقَدۡ أَضَلَّ مِنكُمۡ جِبِلّٗا كَثِيرًاۖ أَفَلَمۡ تَكُونُواْ تَعۡقِلُونَ
Ati pe (Esu) kuku ti si opolopo eda lona ninu yin. Se e o nii se laakaye ni
Surah Ya-Seen, Verse 62
هَٰذِهِۦ جَهَنَّمُ ٱلَّتِي كُنتُمۡ تُوعَدُونَ
Eyi ni ina Jahanamo ti A n se ni adehun fun yin
Surah Ya-Seen, Verse 63
ٱصۡلَوۡهَا ٱلۡيَوۡمَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ
E wo inu re ni oni nitori pe eyin je alaigbagbo
Surah Ya-Seen, Verse 64
ٱلۡيَوۡمَ نَخۡتِمُ عَلَىٰٓ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَتُكَلِّمُنَآ أَيۡدِيهِمۡ وَتَشۡهَدُ أَرۡجُلُهُم بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Ni oni, A maa di enu won pa. Awon owo won yo si maa ba Wa soro. Awon ese won yo si maa jerii si ohun ti won n se nise
Surah Ya-Seen, Verse 65
وَلَوۡ نَشَآءُ لَطَمَسۡنَا عَلَىٰٓ أَعۡيُنِهِمۡ فَٱسۡتَبَقُواْ ٱلصِّرَٰطَ فَأَنَّىٰ يُبۡصِرُونَ
Ti o ba je pe A ba fe, Awa iba fo won loju, won iba si yara wa soju ona, bawo ni won se maa riran na
Surah Ya-Seen, Verse 66
وَلَوۡ نَشَآءُ لَمَسَخۡنَٰهُمۡ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمۡ فَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ مُضِيّٗا وَلَا يَرۡجِعُونَ
Ti o ba je pe A ba fe, Awa iba yi won pada si eda miiran ninu ibugbe won. Won ko si nii lagbara lati lo siwaju. Won ko si nii pada seyin
Surah Ya-Seen, Verse 67
وَمَن نُّعَمِّرۡهُ نُنَكِّسۡهُ فِي ٱلۡخَلۡقِۚ أَفَلَا يَعۡقِلُونَ
Enikeni ti A ba fun ni emi gigun lo, A oo so eda re di ole, se won ko nii se laakaye ni
Surah Ya-Seen, Verse 68
وَمَا عَلَّمۡنَٰهُ ٱلشِّعۡرَ وَمَا يَنۢبَغِي لَهُۥٓۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ وَقُرۡءَانٞ مُّبِينٞ
A o ko Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) ni ewi. Ko si ro o lorun (lati kewi). Ki ni ohun (ti A fi ranse si i) bi ko se iranti ati al-Ƙur’an ponnbele
Surah Ya-Seen, Verse 69
لِّيُنذِرَ مَن كَانَ حَيّٗا وَيَحِقَّ ٱلۡقَوۡلُ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
nitori ki o le sekilo fun eni ti o je alaaye ati nitori ki oro naa le ko lori awon alaigbagbo
Surah Ya-Seen, Verse 70
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا خَلَقۡنَا لَهُم مِّمَّا عَمِلَتۡ أَيۡدِينَآ أَنۡعَٰمٗا فَهُمۡ لَهَا مَٰلِكُونَ
Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A seda ninu ohun ti A fi owo Wa se (ti o je) awon eran-osin fun won? Won si ni ikapa lori won
Surah Ya-Seen, Verse 71
وَذَلَّلۡنَٰهَا لَهُمۡ فَمِنۡهَا رَكُوبُهُمۡ وَمِنۡهَا يَأۡكُلُونَ
A te won lori ba fun won; won n gun ninu won, won si n je ninu won
Surah Ya-Seen, Verse 72
وَلَهُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَمَشَارِبُۚ أَفَلَا يَشۡكُرُونَ
Awon anfaani ati ohun mimu tun wa fun won ninu re. Se won ko nii dupe ni
Surah Ya-Seen, Verse 73
وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ ءَالِهَةٗ لَّعَلَّهُمۡ يُنصَرُونَ
Won so awon kan di olohun leyin Allahu nitori ki won le saranse fun won
Surah Ya-Seen, Verse 74
لَا يَسۡتَطِيعُونَ نَصۡرَهُمۡ وَهُمۡ لَهُمۡ جُندٞ مُّحۡضَرُونَ
Won ko si le se aranse fun won; sebi awon orisa ni omo ogun ti A maa ko wo inu Ina fun awon aborisa (lati fi je won niya)
Surah Ya-Seen, Verse 75
فَلَا يَحۡزُنكَ قَوۡلُهُمۡۘ إِنَّا نَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَ
Nitori naa, ma se je ki oro won ba o ninu je. Dajudaju Awa mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n safi han re
Surah Ya-Seen, Verse 76
أَوَلَمۡ يَرَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن نُّطۡفَةٖ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٞ مُّبِينٞ
Se eniyan ko ri i pe dajudaju Awa l’A seda re lati inu ato? (Sebi leyin) igba naa l’o di alatako ponnbele
Surah Ya-Seen, Verse 77
وَضَرَبَ لَنَا مَثَلٗا وَنَسِيَ خَلۡقَهُۥۖ قَالَ مَن يُحۡيِ ٱلۡعِظَٰمَ وَهِيَ رَمِيمٞ
Ati pe o fi akawe lele nipa Wa. O si gbagbe iseda re. O wi pe: "Ta ni O maa so egungun di alaaye nigba ti o ti kefun
Surah Ya-Seen, Verse 78
قُلۡ يُحۡيِيهَا ٱلَّذِيٓ أَنشَأَهَآ أَوَّلَ مَرَّةٖۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلۡقٍ عَلِيمٌ
So pe: "Eni ti O seda re nigba akoko l’O maa so o di alaaye. Oun si ni Onimo nipa gbogbo eda
Surah Ya-Seen, Verse 79
ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلشَّجَرِ ٱلۡأَخۡضَرِ نَارٗا فَإِذَآ أَنتُم مِّنۡهُ تُوقِدُونَ
(Oun ni) Eni ti O mu ina jade fun yin lati ara igi tutu. E si n fi ko ina
Surah Ya-Seen, Verse 80
أَوَلَيۡسَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يَخۡلُقَ مِثۡلَهُمۚ بَلَىٰ وَهُوَ ٱلۡخَلَّـٰقُ ٱلۡعَلِيمُ
Nje Eni ti O seda awon sanmo ati ile ko ni agbara lati da iru won (miiran) bi? Rara (O ni agbara). Oun si ni Eledaa, Onimo
Surah Ya-Seen, Verse 81
إِنَّمَآ أَمۡرُهُۥٓ إِذَآ أَرَادَ شَيۡـًٔا أَن يَقُولَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Ase Re nigba ti O ba gbero kini kan ni pe, O maa so fun un pe "Je bee." O si maa je bee
Surah Ya-Seen, Verse 82
فَسُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي بِيَدِهِۦ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيۡءٖ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Nitori naa, mimo ni fun Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
Surah Ya-Seen, Verse 83