Surah An-Nisa Verse 113 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكَ وَرَحۡمَتُهُۥ لَهَمَّت طَّآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ أَن يُضِلُّوكَ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡۖ وَمَا يَضُرُّونَكَ مِن شَيۡءٖۚ وَأَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمۡ تَكُن تَعۡلَمُۚ وَكَانَ فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكَ عَظِيمٗا
Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti fẹ́ ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́; oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun t’ó tóbi