Surah An-Nisa Verse 119 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَلَأُضِلَّنَّهُمۡ وَلَأُمَنِّيَنَّهُمۡ وَلَأٓمُرَنَّهُمۡ فَلَيُبَتِّكُنَّ ءَاذَانَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ وَلَأٓمُرَنَّهُمۡ فَلَيُغَيِّرُنَّ خَلۡقَ ٱللَّهِۚ وَمَن يَتَّخِذِ ٱلشَّيۡطَٰنَ وَلِيّٗا مِّن دُونِ ٱللَّهِ فَقَدۡ خَسِرَ خُسۡرَانٗا مُّبِينٗا
Dájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Mo máa fi èròkerò sínú ọkàn wọn. Mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀dá Allāhu padà." Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú Èṣù ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé