Surah An-Nisa Verse 146 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaإِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ وَأَصۡلَحُواْ وَٱعۡتَصَمُواْ بِٱللَّهِ وَأَخۡلَصُواْ دِينَهُمۡ لِلَّهِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ مَعَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَسَوۡفَ يُؤۡتِ ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ أَجۡرًا عَظِيمٗا
Àyàfi àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n dúró ṣinṣin ti Allāhu, tí wọ́n sì ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn wọn fún Allāhu. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Láìpẹ́ Allāhu máa fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ẹ̀san ńlá