Surah An-Nisa Verse 153 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaيَسۡـَٔلُكَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ أَن تُنَزِّلَ عَلَيۡهِمۡ كِتَٰبٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِۚ فَقَدۡ سَأَلُواْ مُوسَىٰٓ أَكۡبَرَ مِن ذَٰلِكَ فَقَالُوٓاْ أَرِنَا ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّـٰعِقَةُ بِظُلۡمِهِمۡۚ ثُمَّ ٱتَّخَذُواْ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ فَعَفَوۡنَا عَن ذَٰلِكَۚ وَءَاتَيۡنَا مُوسَىٰ سُلۡطَٰنٗا مُّبِينٗا
Àwọn ahlul-kitāb ń bi ọ́ léèrè pé kí o sọ tírà kan kalẹ̀ láti inú sánmọ̀. Wọ́n kúkú bi (Ànábì) Mūsā ní ohun tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Wọ́n wí pé: “Fi Allāhu hàn wá ní gban̄gba.” Nítorí náà, ohùn igbe láti inú sánmọ̀ gbá wọn mú nípasẹ̀ àbòsí ọwọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di n̄ǹkan tí wọ́n jọ́sìn fún lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá wọn. A tún ṣàmójú kúrò níbi ìyẹn. A sì fún (Ànábì) Mūsā ní ẹ̀rí pọ́nńbélé