Surah An-Nisa Verse 155 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaفَبِمَا نَقۡضِهِم مِّيثَٰقَهُمۡ وَكُفۡرِهِم بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَقَتۡلِهِمُ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖ وَقَوۡلِهِمۡ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَلۡ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَيۡهَا بِكُفۡرِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُونَ إِلَّا قَلِيلٗا
Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn, ṣíṣàìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu, pípa tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́ àti wíwí tí wọ́n ń wí pé: “Ọkàn wa ti di.” – rárá, Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. – Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn)