Surah An-Nisa Verse 16 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaوَٱلَّذَانِ يَأۡتِيَٰنِهَا مِنكُمۡ فَـَٔاذُوهُمَاۖ فَإِن تَابَا وَأَصۡلَحَا فَأَعۡرِضُواْ عَنۡهُمَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ تَوَّابٗا رَّحِيمًا
Àwọn méjì tí wọ́n ṣe (sìná) nínú yín, kí ẹ (fẹnu) bá wọn wí. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run