Surah An-Nisa Verse 171 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaيَـٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا تَغۡلُواْ فِي دِينِكُمۡ وَلَا تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّۚ إِنَّمَا ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ رَسُولُ ٱللَّهِ وَكَلِمَتُهُۥٓ أَلۡقَىٰهَآ إِلَىٰ مَرۡيَمَ وَرُوحٞ مِّنۡهُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۖ وَلَا تَقُولُواْ ثَلَٰثَةٌۚ ٱنتَهُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ إِنَّمَا ٱللَّهُ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓ أَن يَكُونَ لَهُۥ وَلَدٞۘ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fun yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo (tí ìjọ́sìn tọ́ sí). Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó