Surah An-Nisa Verse 176 - Yoruba Translation by Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Surah An-Nisaيَسۡتَفۡتُونَكَ قُلِ ٱللَّهُ يُفۡتِيكُمۡ فِي ٱلۡكَلَٰلَةِۚ إِنِ ٱمۡرُؤٌاْ هَلَكَ لَيۡسَ لَهُۥ وَلَدٞ وَلَهُۥٓ أُخۡتٞ فَلَهَا نِصۡفُ مَا تَرَكَۚ وَهُوَ يَرِثُهَآ إِن لَّمۡ يَكُن لَّهَا وَلَدٞۚ فَإِن كَانَتَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُمَا ٱلثُّلُثَانِ مِمَّا تَرَكَۚ وَإِن كَانُوٓاْ إِخۡوَةٗ رِّجَالٗا وَنِسَآءٗ فَلِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۗ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ أَن تَضِلُّواْۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمُۢ
Won n bi o leere ibeere, so pe: “Allahu n fun yin ni idajo nipa eni ti ko ni obi, ko si ni omo. Ti eniyan kan ba ku, ti ko ni omo laye, ti o si ni arabinrin kan, idaji ni tire ninu ohun ti o fi sile. (Arakunrin) l’o maa je gbogbo ogun arabinrin re, ti ko ba ni omo laye. Ti arabinrin ba si je meji, ida meji ninu ida meta ni tiwon ninu ohun ti o fi sile. Ti won ba si je arakunrin (pupo) lokunrin ati lobinrin, ti okunrin kan ni ipin obinrin meji. Allahu n se alaye fun yin ki e ma baa sina. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan